فَلَمَّآ أَسۡلَمَا وَتَلَّهُۥ لِلۡجَبِينِ 103
Nigbati o tẹri rẹ ba fun Allah, ti o si jupa jusẹ fun Un, o fi Ibrahim ọmọ rẹ lelẹ ni ẹgbẹ iwaju rẹ lati mu ohun ti wọn pa lasẹ didu rẹ sẹ.
وَنَٰدَيۡنَٰهُ أَن يَٰٓإِبۡرَٰهِيمُ 104
A si pe Ibrahim, ohun ni mimu asẹ Allah pẹlu didu ọmọ rẹ: a ni irẹ Ibrahim.
قَدۡ صَدَّقۡتَ ٱلرُّءۡيَآۚ إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ 105
Ala ti o ri ti di ododo ni ojuran rẹ pẹlu ipinnu rẹ lori didu ọmọ rẹ, a wa - gẹgẹ bi a se san ọ lẹsan pẹlu lila ọ kuro nibi idanwo ti o tobi naa - a o maa sẹsan fun awọn oluse daadaa, a o si maa la wọn kuro nibi adanwo ati awọn ilekoko.
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلۡبَلَٰٓؤُاْ ٱلۡمُبِينُ 106
Dajudaju eleyi ni idanwo ti o fi oju han, bẹẹni Ibrahim si ti yege nibẹ.
وَفَدَيۡنَٰهُ بِذِبۡحٍ عَظِيمٖ 107
A si jiirọ fun Ismail pẹlu agbo ti o tobi dipo rẹ, o si pa a di i.
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ 108
A si sẹ ẹyin ti o dara ku fun Ibrahim ninu awọn ijọ ti o tẹle e.
سَلَٰمٌ عَلَىٰٓ إِبۡرَٰهِيمَ 109
Ikinni lati ọdọ Allah fun un ati adura ọla kuro nibi gbogbo inira ati aleebu.
كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ 110
Gẹgẹ bi a se sẹsan fun Ibrahim lori itẹle rẹ ni a o maa sẹsan fun awọn oluse daadaa.
إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 111
Dajudaju Ibrahim wa ninu awọn ẹru wa ti o jẹ olugbagbọ ododo, awọn ti o nmu ohun ti ijẹ ẹru fun Allah ko sinu sẹ.
وَبَشَّرۡنَٰهُ بِإِسۡحَٰقَ نَبِيّٗا مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ 112
A si fi ọmọkunrin miran fun un niro idunnu, ti yoo di anọbi ati ẹru rere oun ni Ishaaq; ni ẹsan lori titẹle ti Allah ọmọ rẹ kan soso.
وَبَٰرَكۡنَا عَلَيۡهِ وَعَلَىٰٓ إِسۡحَٰقَۚ وَمِن ذُرِّيَّتِهِمَا مُحۡسِنٞ وَظَالِمٞ لِّنَفۡسِهِۦ مُبِينٞ 113
A si sọ alubarika lati ọdọ wa kalẹ fun un ati fun ọmọ rẹ Ishaaq, a si jẹ ki idẹkun wa pọ fun wọn ninu rẹ ni pipọ ọmọ awọn mejeeji, o wa ninu arọmọdọmọ awọn mejeeji oluse daadaa nibi titẹle asẹ Ọlọhun Ọba rẹ, o si tun wa ninu wọn alabosi fun ẹmin ara rẹ pẹlu sise keferi ati dida awọn ẹsẹ ni abosi ti o fi oju han.
وَلَقَدۡ مَنَنَّا عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ 114
Paapaa a ti se idẹkun fun Musa ati ọmọ iya rẹ aharuna nibi jijẹ anọbi.
وَنَجَّيۡنَٰهُمَا وَقَوۡمَهُمَا مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ 115
A la awọn mejeeji ati awọn ijọ wọn tii se arọmọdọmọ Israheel nibi imusin fir'aona fun wọn ati itẹri.
وَنَصَرۡنَٰهُمۡ فَكَانُواْ هُمُ ٱلۡغَٰلِبِينَ 116
A si ran wọn se lori firiaon ati awọn ọmọ ogun rẹ, isẹgun wa jẹ ti wọn lori ọta wọn.
وَءَاتَيۡنَٰهُمَا ٱلۡكِتَٰبَ ٱلۡمُسۡتَبِينَ 117
A si fun Musa ati ọmọ iya haruna ni taoreeta ni iwe kan ti o fi oju han ti ko si iruju nibẹ lati ọdọ Allah.
وَهَدَيۡنَٰهُمَا ٱلصِّرَٰطَ ٱلۡمُسۡتَقِيمَ 118
A si tọ awọn mejeeji si ọna ti o duro tọ eyiti ko si iwọgun nibẹ ohun ni oju ọna ẹsin Islam ti o nmuni de ibi iyọnu asẹda ti mimọ nbẹ fun.
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِمَا فِي ٱلۡأٓخِرِينَ 119
A si sẹ ẹyin ti o dara ku fun awọn mejeeji ati iranti ti o dun ni nu awọn ijọ ti o tẹle e.
سَلَٰمٌ عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ 120
Ikinilati ọdọ Allah ti o dara ati ẹyin le wọn lori ati adura alaafia kuro nibi gbogbo ohun ti ọkan kọ.
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ 121
Awa gẹgẹbi a se san Musa ati haruna lẹsan ti o dara yii, bẹẹni a o maa sẹsan fun gbogbo oluse daadaa nibi titẹle asẹ Ọlọhun Ọba wọn.
إِنَّهُمَا مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 122
Dajudaju Musa ati haruna wa ninu awọn ẹru wa olugbagbọ ododo si Allah oluse ohun ti O se lofin fun wọn.
وَإِنَّ إِلۡيَاسَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 123
Ati wipe dajudaju Iliyasu wa ninu awọn ojisẹ lọdọ Ọlọhun Ọba rẹ, Allah se idẹkun le lori pẹlu ijẹ anọbi ati isẹ riran.
إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِۦٓ أَلَا تَتَّقُونَ 124
Nigbati o sọ fun awọn ijọ rẹ, awọn ti wọn ransẹ si ninu awọn ọmọ isirẹli: ẹyin ijọ mi, se ẹ ko ni paya Allah ni; pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ninu rẹ si ni imulọkan soso ati jinna si awọn nkan ti o kọ ninu rẹ si ẹbọ?!
أَتَدۡعُونَ بَعۡلٗا وَتَذَرُونَ أَحۡسَنَ ٱلۡخَٰلِقِينَ 125
Se ẹ o ma sin ohun ti o yatọ si Allah tii se oosa yin baalu, ti ẹ o si gbe ijọsin Allah ti O dara ju ninu olusẹda lọ ni?!
ٱللَّهَ رَبَّكُمۡ وَرَبَّ ءَابَآئِكُمُ ٱلۡأَوَّلِينَ 126
Allah si ni olutẹju yin eyiti O da yin, O si da awọn baba yin siwaju, Oun si ni ẹniti ijọsin tọ si, kii se ẹlomiran ninu awọn oosa ti ko le se anfaani, bẹẹni ko le mu inira ba yin.
Gbolohun rẹ: (فَلَمَّآ أَسۡلَمَا) (nigbati awọn mejeeji jupa jusẹ silẹ) jẹ itọka lori wipe Ibrahim ati ismail awọn ti ọla nbẹ fun wọn wa ninu ijupa jusẹ ti o de ogongo fun asẹ Allah ti O ga.
Ninu awọn erongba ofin ẹsin ni titu awọn ẹru lọrun silẹ kuro nibi ijẹru abara.
Ẹyin ti o dara ati iranti ti o dun wa ninu idẹkun kiakia ni ile aye.