وَلَقَدۡ نَعۡلَمُ أَنَّهُمۡ يَقُولُونَ إِنَّمَا يُعَلِّمُهُۥ بَشَرٞۗ لِّسَانُ ٱلَّذِي يُلۡحِدُونَ إِلَيۡهِ أَعۡجَمِيّٞ وَهَٰذَا لِسَانٌ عَرَبِيّٞ مُّبِينٌ 103
Awa mọ wipe dajudaju awọn ẹlẹbọ nsọpe: dajudaju Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun eniyan kan ni nkọ ni Alukuraani, opurọ ni wọn si nibi nkan ti wọn npe ara wọn, ede ti wọn nlero wipe ẹniti o nkọ ọ mọ jẹ ede ajoji, bẹẹni Alukuraani yii si sọkalẹ pẹlu ahọn larubawa ti o han de, ti o ni agbekalẹ ti o dara, bawo ni wọn se wa nlero wipe o gba a kọ lati ibi ede ajoji?!
إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِ لَا يَهۡدِيهِمُ ٱللَّهُ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٌ 104
Dajudaju awọn ti ko nigbagbọ ninu aayah Allah wipe ọdọ Ọba mimọ ni o ti wa Ọlọhun Allah ko nii fi wọn se kongẹ imọna niwọnba igbati wọn ba taku lori eleyi, iya itara si nbẹ fun wọn nitori keferi si Allah ati pipe aayah Rẹ nirọ ti wọn wa nibẹ.
إِنَّمَا يَفۡتَرِي ٱلۡكَذِبَ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡكَٰذِبُونَ 105
Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun kii se opurọ lori ohun ti o mu wa lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ, dajudaju awọn ti wọn ko gba aayah ỌLọhun nlododo ni wọn hun ahunjọ irọ; nitoripe wọn ko paya iya, wọn ko si rankan ẹsan, awọn ti a fi keferi royin yii ni opurọ; nitoripe irọ jẹ isesi wọn eyiti wọn barẹ.
مَن كَفَرَ بِٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ إِيمَٰنِهِۦٓ إِلَّا مَنۡ أُكۡرِهَ وَقَلۡبُهُۥ مُطۡمَئِنُّۢ بِٱلۡإِيمَٰنِ وَلَٰكِن مَّن شَرَحَ بِٱلۡكُفۡرِ صَدۡرٗا فَعَلَيۡهِمۡ غَضَبٞ مِّنَ ٱللَّهِ وَلَهُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ 106
Ẹnikẹni ti o ba se keferi si Allah lẹyin igbagbọ rẹ, ko le jẹ ẹnikẹni ayaafi ẹniti wọn jẹ nipa lori sise keferi, ti o nsọ gbolohun keferi lori ahọn rẹ, ti ọkan rẹ si balẹ lori igbagbọ, ti o si ni amọdaju lori ododo rẹ, sugbọn ẹniti igbaaya rẹ ba fẹ si keferi, ti o si saa lẹsa lori igbagbọ, ti o nsọ ọ jade niti titẹle, ti jẹ olugunri kuro ninu Islam ibinu Allah si nbẹ le wọn lori, bẹẹ ni iya ti o tobi nbẹ fun wọn.
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمُ ٱسۡتَحَبُّواْ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا عَلَى ٱلۡأٓخِرَةِ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡكَٰفِرِينَ 107
Igunri kuro ninu Islam yii jẹ nitori gbigbe ọla fun ohun ti wọn ri ninu oore ile aye lati ibi ẹbun sise keferi wọn si ọrun, bẹẹ ni dajudaju Allah ko nii fi ijọ keferi se kongẹ igbagbọ, bikosepe Yoo dagunla si wọn.
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ طَبَعَ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ وَسَمۡعِهِمۡ وَأَبۡصَٰرِهِمۡۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡغَٰفِلُونَ 108
Awọn ti a fi igunri kuro ninu Islam royin lẹyin igbagbọ ni awọn ti Allah ti fi edidi di ọkan wọn, wọn ko le gbọ agbọye isiti, bẹẹ ni o wa ni igbọran wọn, wọn ko le gbọ ni gbigbọ ti yoo se wọn ni anfaani, bẹẹ ni o wa lori iriran wọn, wọn ko le ri awọn amin ti o tọka si igbagbọ, awọn wọnyi ni olufọnu nipa awọn okunfa oriire ati oriibu, ati ohun ti Allah pese fun wọn ninu iya.
لَا جَرَمَ أَنَّهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ 109
Niti ododo awọn ni ẹni ofo ni ọjọ igbende, awọn ti wọn ti sofo ẹmin wọn nitori keferi wọn lẹyin igbagbọ wọn eyiti o jasi wipe ti wọn ba dii mu, wọn ko ba wọ Alujannah.
ثُمَّ إِنَّ رَبَّكَ لِلَّذِينَ هَاجَرُواْ مِنۢ بَعۡدِ مَا فُتِنُواْ ثُمَّ جَٰهَدُواْ وَصَبَرُوٓاْ إِنَّ رَبَّكَ مِنۢ بَعۡدِهَا لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ 110
Lẹyin igba naa dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - ire ojise - oluforijinni olukẹ awọn ọlẹ ninu awọn olugbagbọ ododo ti o se irin ajo lati Mẹkkah lọsi Mẹdinah lẹyin igbati awọn ẹlẹbọ ti fi iya jẹ wọn, ti wọn si dan wo nibi ẹsin wọn debi pe wọn sọ gbolohun keferi bẹẹ ni ọkan wọn si balẹ lori igbagbọ, lẹyin naa ni wọn wa gbiyanju si oju ọna ti Allah ki gbolohun Allah le jẹ ohun ti o ga julọ, ki gbolohun awọn keferi si jẹ eyiti o rẹlẹ, wọn si se suuru lori wahala, dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ lẹyin idaamu yii eyiti wọn ri ati ijiya eyiti wọn fi jẹ wọn titi ti wọn fi sọ gbolohun keferi; oluforijinni fun wọn ati olukẹ si wọn nitoripe wọn ko sọ gbollohun keferi ayaafi tori ijẹni nipa.
Sisẹdẹ fun ẹniti wọn jẹ nipa lati pe gbolohun keferi ni ojukoroju, ti ọkan rẹ si balẹ lori igbagbọ.
Awọn olugunri kuro ninu ẹsin ni ẹtọ si ibinu Allah ati iya Rẹ; nitoripe wọn nifẹ si isẹmin aye lori ọrun, wọn waa se imọna Allah ni eewọ fun wọn, Ọlọhun Allah si fi edidi di ọkan wọn ati igbọran wọn ati ọkan wọn, wọn si fi wọn sinu afọnufọra nipa ohun ti wọn gbero si wọn ninu iya ti o le koko ni ọjọ igbende.
Ọlọhun Allah kọ akọsilẹ aforijin fun awọn ti wọn nigbagbọ, ti wọn si se irin ajo lẹyin igbati wọn ti daamu wọn, ti wọn si tun se suuru lori igbiyanju.