ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ خَٰلِقُ كُلِّ شَيۡءٖ فَٱعۡبُدُوهُۚ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ وَكِيلٞ 102
Ẹni yii - ẹyin eniyan - ti a fi gbogbo iroyin naa yin ni Ọlọhun Ọba yin, ko si ọlọhun ọba miran yatọ siI, ko si si ẹni ijọsin tọsi yatọ si I, Oun ni O mu gbogbo nkan bẹ, ki ẹ maa sin ni Oun nikan soso, Oun ni ijọsin tọsi, O si jẹ olusọ fun gbogbo nkan.
لَّا تُدۡرِكُهُ ٱلۡأَبۡصَٰرُ وَهُوَ يُدۡرِكُ ٱلۡأَبۡصَٰرَۖ وَهُوَ ٱللَّطِيفُ ٱلۡخَبِيرُ 103
Gbogbo oju ko lee ri I, Oun ti mimọ nbẹ fun si nri gbogbo oju, O si nimọ pẹlu rẹ, Oun ni alaanu si awọn ẹru Rẹ rere, Oun ni yoo fun wọn niro.
قَدۡ جَآءَكُم بَصَآئِرُ مِن رَّبِّكُمۡۖ فَمَنۡ أَبۡصَرَ فَلِنَفۡسِهِۦۖ وَمَنۡ عَمِيَ فَعَلَيۡهَاۚ وَمَآ أَنَا۠ عَلَيۡكُم بِحَفِيظٖ 104
Paapaa o ti wa ba yin - ẹyin eniyan - awijare ti o fi oju han, ati ẹri ti gbọngbọn lati ọdọ Ọlọhun Ọba yin, ẹniti o ba se laakaye, ti o si tẹriba, anfaani rẹ yoo sẹri si ọdọ rẹ, ẹniti o ba diju fun un, ti ko si se laakaye pẹlu rẹ, ti ko si tẹriba fun un, ninra bẹ yoo sẹri si ọdọ rẹ, emi kii se olusọ leyin lori, ti yoo maa sọ isẹ yin, mo jẹ ojisẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba mi, Oun si ni olusọ leyin lori.
وَكَذَٰلِكَ نُصَرِّفُ ٱلۡأٓيَٰتِ وَلِيَقُولُواْ دَرَسۡتَ وَلِنُبَيِّنَهُۥ لِقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ 105
Gẹgẹ bi a se mu oniranran ẹri ati awijare wa lori agbara Ọlọhun Ọba Allah, bẹẹ naa ni a o se mi oniranran amin wa lori adehun daadaa ati adehun iya ati isiti, awọn ọlọsẹbọ yoo ma sọrọ: eleyi kii se imisi, o kọ ni ọdọ awọn onitira siwaju rẹ. Ati ki a le ba salaye ododo fun awọn eniyan pẹlu mimu awọn amin yi wa fun awọn olugbagbọ ododo ninu awọn ọmọlẹyin Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, awọn ni wọn gba ododo, ti wọn si ntẹle.
ٱتَّبِعۡ مَآ أُوحِيَ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ وَأَعۡرِضۡ عَنِ ٱلۡمُشۡرِكِينَ 106
Tẹle - ire ojise - ohun ti Ọlọhun Ọba rẹ fi ransẹ si ọ ninu ododo, Oun ni ẹniti mimọ nbẹ fun, ti ko si ẹniti ijọsin tọsi yatọ siI, mase daamu ọkan rẹ nitori awọn keferi ati orikunkun wọn, ọrọ wọn di ọwọ Ọlọhun Ọba Allah.
وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَآ أَشۡرَكُواْۗ وَمَا جَعَلۡنَٰكَ عَلَيۡهِمۡ حَفِيظٗاۖ وَمَآ أَنتَ عَلَيۡهِم بِوَكِيلٖ 107
Ti Ọlọhun Ọba Allah ba fẹ ki wọn ma se ẹbọ kankan pẹlu Rẹ, wọn ko nii se ẹbọ kankan pẹlu Rẹ, a o se ọ ni - ire ojise - olusẹ ti yoo maa kiyesi awọn isẹ wọn, iwọ kii se ẹniti yoo maa gbe wọn yẹwo, ojisẹ ni o jẹ, ohun ti o jẹ ọranyan fun ọ ni mimju de ogongo.
وَلَا تَسُبُّواْ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ فَيَسُبُّواْ ٱللَّهَ عَدۡوَۢا بِغَيۡرِ عِلۡمٖۗ كَذَٰلِكَ زَيَّنَّا لِكُلِّ أُمَّةٍ عَمَلَهُمۡ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّهِم مَّرۡجِعُهُمۡ فَيُنَبِّئُهُم بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 108
Ẹ mase bu - ẹyin olugbagbọ ododo - awọn ẹbọ eyiti awọn ọlọsẹbọ nsin pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, koda bi o jẹ ohun ti o yẹpẹrẹ, ti o si lẹtọ si eebu; ki awọn ọlọsẹbọ naa ma baa maa bu Ọlọhun Ọba Allah niti ifesi pada ati aini imọ nipa Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun, gẹgẹ bi ọna anu ti awọn eniyan yii wa se jẹ nkan ọsọ fun wọn, bẹẹ naa ni a se se isẹ ijọ kọọkan lọsọ fun un, rere ni o jẹ ni tabi aburu, ti wọn sinse ohun ti a se lọsọ fun wọn, lẹyin eyi ọdọ Ọlọhun Ọba wọn ni ibusẹri si wọn ni ọjọ igbende, yoo fun wọn niro lori ohun ti wọn se ni ile aye, yoo si san wọn lẹsan lori.
وَأَقۡسَمُواْ بِٱللَّهِ جَهۡدَ أَيۡمَٰنِهِمۡ لَئِن جَآءَتۡهُمۡ ءَايَةٞ لَّيُؤۡمِنُنَّ بِهَاۚ قُلۡ إِنَّمَا ٱلۡأٓيَٰتُ عِندَ ٱللَّهِۖ وَمَا يُشۡعِرُكُمۡ أَنَّهَآ إِذَا جَآءَتۡ لَا يُؤۡمِنُونَ 109
Awọn ọsẹbọ bura pẹlu Ọlọhun Ọba Allah ni ibura ti o le pẹlu ohun ti lagbara: ti Muhammad ba mu eyikeyi amin kan wa, ninu awọn amin ti wọn hun, wọn yoo gbaa gbọ, sọ fun wọn - ire ojise - wipe awọn amin naa kii se lati ọdọ mi ni mo ti nsọọ kalẹ, ati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ni, O nsọ kalẹ nigbati O ba fẹ, ki ni o fi mọ yin - ẹyin olugbagbọ ododo - wipe awọn amin yi wa ni ibamun si ohun ti ẹ hun jọ, ti ẹ ko fi gbaa gbọ, bikose wipe wọn sẹku lori orikunkun wọn ati iyan jija wọn; nitori wipe wọn ko fẹ imọna.
وَنُقَلِّبُ أَفِۡٔدَتَهُمۡ وَأَبۡصَٰرَهُمۡ كَمَا لَمۡ يُؤۡمِنُواْ بِهِۦٓ أَوَّلَ مَرَّةٖ وَنَذَرُهُمۡ فِي طُغۡيَٰنِهِمۡ يَعۡمَهُونَ 110
A o yi ọkan wọn pada ati irina wọn pẹlu gaga kan ti yoo wa laarin rẹ ati imọna sibi ododo, gẹgẹ bi wọn se fi gaga si aarin wọn ati igbagbọ si Alukuraani ni igba akọkọ nitori ori kunkun wọn, a o fi wọn silẹ nibi ọna anu wọn, ati igbẹru gbọnri wọn si Ọlọhun Ọba wọn, wọn yoo maa daamu ni itẹsẹ-bọsẹ.
Fiffọ Ọlọhun Ọba Allah ti o ga mọ kanga kuro nibi abosi, ti adisọkan (ijẹni nipa) ma nfi rinlẹ, ati sise alaye wipe sise keferi ẹda ati sise ẹbọ wọn alamọri kan ti wọn da silẹ lati ọwọ ara wọn ni.
Ko si ninu ikapani eyikeyi Anọbi lati mu amin kan wa lati ọdọ ara rẹ, tabi ni igba kii gba ti o ba wu u, bikose wipe eleyi jẹ ohun ti Ọlọhun Ọba Allah yoo da pada si lọdọ, oun nikan ni Ọba Alagbara lori rẹ, Oun nikan ni Ọjọgbọn ti o ma npebubu iran amin ati asiko ifihan rẹ.
Kikọ funi kuro nibi mima bu awọn ọlọhun ọlọsẹbọ niti isọra nibi aburu nla eyi tii se ikọja ẹnu aala si bibu ỌlọhunỌba Allah ti o da gbogbo agbanla aye.
Ọlọhun Ọba Allah le fi gaga si aarin ẹru ati ọnaamọ, ti yoo si yi oju rẹ ati ọkan rẹ si aitẹle tiRẹ, ki o le jẹ ijiya fun lori yiyan keferi laayo.