وَإِذَا كُنتَ فِيهِمۡ فَأَقَمۡتَ لَهُمُ ٱلصَّلَوٰةَ فَلۡتَقُمۡ طَآئِفَةٞ مِّنۡهُم مَّعَكَ وَلۡيَأۡخُذُوٓاْ أَسۡلِحَتَهُمۡۖ فَإِذَا سَجَدُواْ فَلۡيَكُونُواْ مِن وَرَآئِكُمۡ وَلۡتَأۡتِ طَآئِفَةٌ أُخۡرَىٰ لَمۡ يُصَلُّواْ فَلۡيُصَلُّواْ مَعَكَ وَلۡيَأۡخُذُواْ حِذۡرَهُمۡ وَأَسۡلِحَتَهُمۡۗ وَدَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَوۡ تَغۡفُلُونَ عَنۡ أَسۡلِحَتِكُمۡ وَأَمۡتِعَتِكُمۡ فَيَمِيلُونَ عَلَيۡكُم مَّيۡلَةٗ وَٰحِدَةٗۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ إِن كَانَ بِكُمۡ أَذٗى مِّن مَّطَرٍ أَوۡ كُنتُم مَّرۡضَىٰٓ أَن تَضَعُوٓاْ أَسۡلِحَتَكُمۡۖ وَخُذُواْ حِذۡرَكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ أَعَدَّ لِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٗا مُّهِينٗا 102
Ti o ba wa - ire ojise - ninu awọ ọmọ ogun nigbati wọn nba ọta ja, ti o si gbero lati kirun fun wọn, pin awọn ọmọ ogun si ijọ meji: ki awọn ijọ kan maa kirun pẹlu rẹ, ki wọn o mu nkan ija ogun wọn pẹlu wọn ninu irun wọn, ki awọn ijọ miran wa gẹgẹ bi olusọ yin, ti awọn ijọ akọkọ ba ti ki ọpa irun kan pẹlu Imam, ki wọn pe irun wọn fun ara wọn, ti wọn ba ki irun tan, ki wọn o maa wa ni ẹyin yin ni idojukọ ọta, ki awọn ijọ ti wọn wa ni ibi isọ, ti wọn ko si ki irun, ki wọn o wa ki opo irun kan pẹlu Imam, nigbati Imam ba salamọ, ki wọn o pe ohun ti o ku ninu irun wọn, ki wọn o mu nkan isọra wọn kuro ni ọdọ ọta, ki wọn o si tun mu nkan ogun wọn, toripe dajudaju awọn keferi, wọn ngbero ki ẹ gbagbe nipa nkan ija yin ati dukia yin nigbati ẹ ba nkirun, ki wọn o waa bo yin ni bibo ẹẹkan soso, ki wọn o waa gba yin mu nigbati ẹ ti gbagbe, ko si ẹsẹ fun yin ti suta ba se yin nitori ojo tabi ẹjẹ alaarẹ tabi nkan ti o jọ iru rẹ, ki ẹ fi nkan ija yin silẹ, ki ẹ ma gbe dani, ẹ sọra kuro nibi ọta yin pẹlu nkan ti ẹ ba ni lagbara, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ti pese iya iyẹpẹrẹ fun awọn keferi.
فَإِذَا قَضَيۡتُمُ ٱلصَّلَوٰةَ فَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ قِيَٰمٗا وَقُعُودٗا وَعَلَىٰ جُنُوبِكُمۡۚ فَإِذَا ٱطۡمَأۡنَنتُمۡ فَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَۚ إِنَّ ٱلصَّلَوٰةَ كَانَتۡ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ كِتَٰبٗا مَّوۡقُوتٗا 103
Ti ẹ ba pari -ẹyin olugbagbọ ododo- ninu irun, ki ẹ ranti pẹlu sise afọmọ pẹlu sise afọmọ ati didupẹ ati gbigbe titobi fun un nibi gbogbo isesi yin niduro ati ni ijoko ati ni idubulẹ yin, ti ipaya ba kuro fun yin, ti ẹ si fi ọkan balẹ, ki ẹ ki irun yin ni pipe pẹlu awọn origun rẹ ati awọn ọranyan rẹ ati awọn nkan ti a fẹ ninu rẹ, ni ojupọnna ti wọn pa yin lasẹ, dajudaju irun jẹ ọranyan lori awọn olugbagbọ ododo, ti o si ni aala pẹlu asiko, ko tọ lilọọ lara kọja asiko ayaafi pẹlu awojare, eleyi ni igbati ẹ ba wa ni ile, sugbọn ti ẹ ba wa ni irin-ajo, pipa iorun pọ ati didinku wa fun yin.
وَلَا تَهِنُواْ فِي ٱبۡتِغَآءِ ٱلۡقَوۡمِۖ إِن تَكُونُواْ تَأۡلَمُونَ فَإِنَّهُمۡ يَأۡلَمُونَ كَمَا تَأۡلَمُونَۖ وَتَرۡجُونَ مِنَ ٱللَّهِ مَا لَا يَرۡجُونَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا 104
Ẹ ma se ọlẹ - ẹyin olugbagbọ ododo - ẹ si mase oroju lati wa awọn ọta yin n inu awọn keferi, ti ẹ ba jẹ ẹniti njẹrora nitori ohun ti o kan yin ninu pipa ati ọgbẹ, dajudaju awọn na njẹ irora gẹgẹ bi ẹyin naa se njẹ irora, ti o si nsẹlẹ wọn iru ohun ti o nsẹlẹ si ẹyin naa, suuru ti wọn ko gbọdọ tobi ju suuru ti yin lọ, nitori wipe ẹyin nrankan ẹsan ati aranse ati ikunlọwọ lọdọ Ọlọhun Ọba Allah nkan ti awọn ko rankan, Ọlọhun Ọba Allah jẹ onimimọ pẹlu isesi awọn ẹru Rẹ, Ọjọgbọn nibi idari Rẹ ati ofin Rẹ.
إِنَّآ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ لِتَحۡكُمَ بَيۡنَ ٱلنَّاسِ بِمَآ أَرَىٰكَ ٱللَّهُۚ وَلَا تَكُن لِّلۡخَآئِنِينَ خَصِيمٗا 105
Dajudaju awa ni a sọkalẹ fun ọ - ire ojise - Alukuraani eyiti o kọjọ lori ododo; ki o le salaye laarin awọn eniyan nibi gbogbo alamọri ọrọ wọn pẹlu imọ ti Ọlọhun Ọba Allah fi mọ ọ ati agbọye ti O fun ọ, kii se pẹlu ifẹ inu rẹ ati ero rẹ, mase jẹ oludaabobo fun awọn olutan ẹmion ara wọn jẹ ati afọkantan wọn kuro fun ọ lati wa ododo.
Sise irun ipaya lẹtọ ati alaye awọn idajọ rẹ ati iroyin rẹ.
Mimaa mu okunfa nibi gbogbo isesi, ati wipe dajudaju olugbagbọ ododo ko gbọdọ wa awijare nibi gbigbe ju silẹ, titi ti o fi kan ọrọ ijọsin.
Sise lofin didunnimọ iranti Ọlọhun Ọba Allah ti o ga nibi gbogbo isesi, ohun ni isẹmi ọkan ati okunfa ifọkanbalẹ rẹ.
Kikọ fun ni kuro nibi ijọlẹ, oroju ni igba ijagun pẹlu ọta, ati pipasẹ sise suuru lori jijagun rẹ.