وَكَيۡفَ تَكۡفُرُونَ وَأَنتُمۡ تُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ ءَايَٰتُ ٱللَّهِ وَفِيكُمۡ رَسُولُهُۥۗ وَمَن يَعۡتَصِم بِٱللَّهِ فَقَدۡ هُدِيَ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ 101
Ati wipe bawo ni ẹyin yoo se se aini igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah lẹyin igbagbọ yin pẹlu Rẹ, tosi nbẹ pẹlu yin, idi ti o tobi lati duro sinsin lori igbagbọ! Awọn aayah Ọlọhun Ọba Allah, wọn nka fun yin, ojisẹ Rẹ Muhammad (ki Ọlọhun Ọba se ikẹ ati igẹ fun un) si nse alaye rẹ fun yin, ẹniti o ba gba tira Ọlọhun Ọba Allah mu ati oju ọna ojisẹ Rẹ, paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti fi iru ẹni bẹẹ se kongẹ oju ọna ti o tọ, ti ko si gigun nibẹ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ حَقَّ تُقَاتِهِۦ وَلَا تَمُوتُنَّ إِلَّا وَأَنتُم مُّسۡلِمُونَ 102
Mo pe ẹyin ti ẹ gba Ọlọhun Ọba Allah gb, ti wọn si ntẹle ojisẹ Rẹ, ẹ paya ỌLọhun Ọba yin niti paapa ipaya, ohun naa ni pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, ati mima dupẹ fun Un lori awọn idẹra Rẹ, ki ẹ si gba ẹsin yin mu sinsin titi ti iku yoo fi wa ba yin, ti ẹyin si wa lori nkan naa.
وَٱعۡتَصِمُواْ بِحَبۡلِ ٱللَّهِ جَمِيعٗا وَلَا تَفَرَّقُواْۚ وَٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ إِذۡ كُنتُمۡ أَعۡدَآءٗ فَأَلَّفَ بَيۡنَ قُلُوبِكُمۡ فَأَصۡبَحۡتُم بِنِعۡمَتِهِۦٓ إِخۡوَٰنٗا وَكُنتُمۡ عَلَىٰ شَفَا حُفۡرَةٖ مِّنَ ٱلنَّارِ فَأَنقَذَكُم مِّنۡهَاۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ 103
Ẹ gba tira ati oju ọna Anọbi mu, ẹyin olugbagbọ ododo, ki ẹ si ma se se ohun ti yoo ko yin sinu iyapa, ki ẹ si ranti idẹra Ọlọhun Ọba Allah leyin lori nigbati ẹ jẹ ọta siwaju Islam, ti ẹ ma nba ara yin ja lori okunfa ti o kere, ti O wa ko ọkan yin jọ pẹlu Islam, ni ẹyin wa di ọmọiya ninu ẹsin pẹlu ọla Rẹ, ni ẹniti nkẹ ara wọn, ti si nse isiti fun ara wọn, ti ẹyin si jẹ siwaju rẹ ẹniti nse idari lori wiwọ ina pẹlu aigbagbọ yin, ti Ọlọhun Ọba Allah si la yin kuro nibẹ pẹlu Islam, O si wa fi yin mọna lọsi ibi igbagbọ, ati gẹgẹ bi Ọlọhun Ọba Allah se se aalaye eleyi fun yin , ni O se nsalaye ohun ti yoo tun awọn isesi yin ni ile aye ati Ọjọ Ikẹyin, ki ẹ le baa mọna lọsi oju ọnaamọ, ki ẹ si le ba tọ oju ọna oduro deede.
وَلۡتَكُن مِّنكُمۡ أُمَّةٞ يَدۡعُونَ إِلَى ٱلۡخَيۡرِ وَيَأۡمُرُونَ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَيَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡمُنكَرِۚ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ 104
Ati wipe ki o ya maa bẹ ninu yin - ẹyin olugbagbọ ododo - akojọ awọn eniyan kan, ti wọn yoo maa pe lọsi ibi gbogbo oore, ti Ọlọhun Ọba Allah nifẹ rẹ, wọn yoo si maa pasẹ daadaa, eyiti Ṣẹria tọka si, ti laakaye naa si fi ọwọ si daadaa, wọn si tun maa kọ ohun ti ọkan kọ, eyiti Ṣẹria kọ, ti laakaye si ri si aida rẹ, awọn ti wọn ba royin pẹlu iroyin yii, awọn ni ẹniti o ni ere ti o pe ni aye ati ni ọjọ ikẹyin.
وَلَا تَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ تَفَرَّقُواْ وَٱخۡتَلَفُواْ مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلۡبَيِّنَٰتُۚ وَأُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ 105
Ẹ mase jẹ, ẹyin olugbagbọ ododo, iru awọn ti o ni tira, awọn ti wọn yapa, ti wọn waa di ijọ-ijọ, ati ẹya-ẹya, ti wọn waa yapa ninu ẹsin wọn lẹyin igbati awọn amin ti o fi oju han ti waa ba wọn lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) , awọn ti A sọ naa, ni iya ti o tobi nbẹ fun lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah.
يَوۡمَ تَبۡيَضُّ وُجُوهٞ وَتَسۡوَدُّ وُجُوهٞۚ فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ٱسۡوَدَّتۡ وُجُوهُهُمۡ أَكَفَرۡتُم بَعۡدَ إِيمَٰنِكُمۡ فَذُوقُواْ ٱلۡعَذَابَ بِمَا كُنتُمۡ تَكۡفُرُونَ 106
Iya ti o tobi yii yoo bọ si ori wọn ni Ọjọ Igbende, nigbati awọn oju awọn ti o ni igbagbọ yoo maa mọlẹ, niti idunnu ati oriire, ti awọn oju awọn alaigbagbọ yoo si dudu niti ibanujẹ ati oriibu, awọn ti oju wọn waa dudu ni Ọjọ ti o tobi naa, wọn yoo maa sọ niti eebu fun wọn wipe, se ẹyin se aigbagbọ pẹlu sise Ọlọhun Ọba Allah ni aaso, ati adehun Rẹ, eyiti O gba ni ọdọ yin wipe ẹ ko gbọdọ mu orogun kankan pẹlu Rẹ, lẹyin igbagbọ yin, ati ofin ilẹ yin? ! ẹ waa maa tọ iya Ọlọhun Ọba Allah wo, eyiti O pese rẹ kalẹ fun yin pẹlu okunfa sise aigbagbọ yin.
وَأَمَّا ٱلَّذِينَ ٱبۡيَضَّتۡ وُجُوهُهُمۡ فَفِي رَحۡمَةِ ٱللَّهِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ 107
Ẹ ko ri awọn ti oju wọn funfun, ibuduro si wọn ni inu awọn Ọgba Idẹra, ni ẹniti yoo maa bẹ nibẹ lọ gbere, ninu idẹra kan ti ko nii yẹ, ti ko si ni yi pada.
تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱللَّهِ نَتۡلُوهَا عَلَيۡكَ بِٱلۡحَقِّۗ وَمَا ٱللَّهُ يُرِيدُ ظُلۡمٗا لِّلۡعَٰلَمِينَ 108
Awọn aayah naa, eyiti ti o ko adehun ikẹ ti Ọlọhun Ọba Allah sinu ati adehun iya Rẹ, ni A nka fun ọ - irẹ Anọbi -, pẹlu ododo nibi awọn iro ati deede nibi awọn idajọ, Ọlọhun Ọba Allah ko gbero abosi fun ẹnikankan ninu agbanla aye, bikose wipe ko nii jẹ ẹnikankan niya ayaafi pẹlu ohun ti o ba fi ọwọ rẹ fa.
titẹle awọn ti o ni tira nibi awọn ifẹ inu wọn, yoo se atọkun lọsi ibi anu, ati jijinna si ẹsin Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) .
Gbigba tira mu ati oju ọna Anọbi, ati gbiga imọna awọn mejeeji mu, ni atẹgun ti o tobi lati duro sinsin lori ododo, ati lati sọra kuro nibi anu ati pinpin yẹlẹyẹlẹ.
Pinpin yẹlẹyẹlẹ ati yiyapa eyiti o sẹlẹ ninu ijọ yii, ninu awọn alamọri adisọkan, o nbẹ nibẹ afijọ awọn ti o siwaju ninu awọn ti o ni tira.
Jijẹ dandan mima pasẹ daadaa, ati mima kọ aburu; toripe pẹlu ni iyege ijọ yii, ati okunfa didayatọ rẹ.