وَٱلسَّٰبِقُونَ ٱلۡأَوَّلُونَ مِنَ ٱلۡمُهَٰجِرِينَ وَٱلۡأَنصَارِ وَٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُوهُم بِإِحۡسَٰنٖ رَّضِيَ ٱللَّهُ عَنۡهُمۡ وَرَضُواْ عَنۡهُ وَأَعَدَّ لَهُمۡ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي تَحۡتَهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ 100
Awọn ti wọn gbawaju nigba akọkọ lọ si ibi igbagbọ ninu awọn ti wọn se irin ajo lati ile wọn ati ilu wọn lọ si ọdọ Ọlọhun Allah ati ninu awọn alaranse ti wọn nra anọbi Rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun se, ati awọn ti wọn ntẹle awọn onirin ajo ati alaranse ẹni isaaju lọsi ibi igbagbọ pẹlu sise daadaa ninu adisọkan ati isẹ, Ọlọhun Ọba Allah yoo yọnu si wọn, yoo si tẹwọ gba itẹlasẹ wọn, awọn naa si yọnu si ohun ti o fun wọn ninu ẹsan Rẹ ti o tobi, wọn si pese alujannah onidẹra ti awọn akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ fun wọn, ni ẹniti wọn yoo maa gbe ibẹ gbere, eleyi jẹ ẹsan erenjẹ ti o tobi.
وَمِمَّنۡ حَوۡلَكُم مِّنَ ٱلۡأَعۡرَابِ مُنَٰفِقُونَۖ وَمِنۡ أَهۡلِ ٱلۡمَدِينَةِ مَرَدُواْ عَلَى ٱلنِّفَاقِ لَا تَعۡلَمُهُمۡۖ نَحۡنُ نَعۡلَمُهُمۡۚ سَنُعَذِّبُهُم مَّرَّتَيۡنِ ثُمَّ يُرَدُّونَ إِلَىٰ عَذَابٍ عَظِيمٖ 101
O nbẹ ninu awọn ti wọn sun mọ mẹdinah, ti wọn si jẹ ẹniti o ngbe loko ti o jẹ sọbẹ selu, o nbẹ ninu awọn ara mẹdinah ti wọn jẹ sọbẹ selu, ti wọn si duro sinsin lori sọbẹ selu wọn, iwọ ko le mọ wọn - irẹ ojisẹ - Ọlọhun Ọba Allah ni O mọ wọn, yoo fi iya jẹ wọn ni igba ẹẹmeji: igba akọkọ ni ile aye pẹlu ki o sigbagba sọbẹ selu wọn ati pipa wọn ati mimu wọn lẹru, igba miran ni ọrun pẹlu iya saare lẹyin igbanaa wọn yoo dari wọn sibi iya ti o tobi ni ọjọ igbende ni isalẹ salẹ ina.
وَءَاخَرُونَ ٱعۡتَرَفُواْ بِذُنُوبِهِمۡ خَلَطُواْ عَمَلٗا صَٰلِحٗا وَءَاخَرَ سَيِّئًا عَسَى ٱللَّهُ أَن يَتُوبَ عَلَيۡهِمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٌ 102
O nbẹ ninu awọn ara mẹdinah awọn ijọ miran ti wọn ko jagun laini awijare kankan, wọn si tun nfi rinlẹ fun awọn wọn wipe kosi awijare kankan ara wọn koda wọn ko mu awijare irọ wa, wọn nda awọn isẹẹre wọn ti o siwaju bii titẹle asẹ Allah ati gbigba awọn ofin mu ati gbigbiyanju si oju ọna Rẹ pọ mọ isẹ aburu, wọn si nreti aforijin lati ọdọ Allah, yoo si se amojukuro fun wọn, dajudaju Allah jẹ oluforijin oluronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, O si jẹ olukẹ si wọn.
خُذۡ مِنۡ أَمۡوَٰلِهِمۡ صَدَقَةٗ تُطَهِّرُهُمۡ وَتُزَكِّيهِم بِهَا وَصَلِّ عَلَيۡهِمۡۖ إِنَّ صَلَوٰتَكَ سَكَنٞ لَّهُمۡۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ 103
Mu - irẹ ojisẹ - ninu dukia wọn gẹgẹ bi saka lati se afọmọ fun wọn kuro nibi eeri ẹsẹ ati asise, ki o si tun le mu idagba soke ba daadaa wọn, se adua fun wọn lẹyin igbati o ba gba a lọwọ wọn, dajudaju adua rẹ jẹ ikẹ ati ifọkanbalẹ fun wọn, Ọlọhun Ọba Allah si jẹ olugbọ adua rẹ, onimimọ si isẹ wọn ati adisọkan wọn.
أَلَمۡ يَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ هُوَ يَقۡبَلُ ٱلتَّوۡبَةَ عَنۡ عِبَادِهِۦ وَيَأۡخُذُ ٱلصَّدَقَٰتِ وَأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ 104
Awọn ti wọn yapa kuro nibi igbaiyanju yii, ki wọn o yaa mọ, awọn ti wọn ronu piwada lọsi ọdọ Ọlọhun Ọba Allah wipe dajudaju Allah yoo tẹwọgba ironu piwada awọn ẹru Rẹ ti wọn ba ronu piwada, ati wipe O ma nda saara sugbọn O rọrọ tayọ rẹ, O si ma nsẹsan fun oluse saara lori saara rẹ, ati wipe dajudaju oun ti mimọ nbẹ fun ni olugba ironu piwada fun ẹru Rẹ ti o ba ronu piwada, onikẹ si ni.
وَقُلِ ٱعۡمَلُواْ فَسَيَرَى ٱللَّهُ عَمَلَكُمۡ وَرَسُولُهُۥ وَٱلۡمُؤۡمِنُونَۖ وَسَتُرَدُّونَ إِلَىٰ عَٰلِمِ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 105
Tun sọ fun - irẹ ojisẹ - awọn oluyapa kuro nibi igbiyanju ati awọn oluyapa kuro nibi ẹsẹ wọn: ẹ fara da inira ohun ti o bọ ma yin lọwọ, ki ẹ si se afọmọ gbogbo isẹ yin fun Allah, ki ẹ si maa se ohun ti yoo yọ Ọ ninu, Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ ati awọn olugbagbọ ododo yoo ri awọn isẹẹ yin, ẹ o si sẹri pada ni ọjọ igbende lọsi ọdọ Ọlọhun Ọba yin eyiti o mọ gbogbo nkan, O mọ ohun ti ẹ fi pamọ ati ohun ti ẹ kede, Yoo si fun yin niro nkan ti ẹ se ni ile aye, Yoo si san yin lẹsan le lori.
وَءَاخَرُونَ مُرۡجَوۡنَ لِأَمۡرِ ٱللَّهِ إِمَّا يُعَذِّبُهُمۡ وَإِمَّا يَتُوبُ عَلَيۡهِمۡۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ 106
O wa ninu awọn ti o yapa kuro nibi ogun tabuuki awọn ijọ miran, awọn ti wọn ko ni awijare, awọn wọnyi yoo di ẹni ilọlọra fun eto Ọlọhun ati idajọ Rẹ lori wọn, Yoo si dajọ nipa wọn bi O ti fẹ: ninu ki O fi iya jẹ wọn ti wọn ko ba ronu piwada lọsi ọdọ Rẹ tabi ki o gba ironu piwada wọn nigbati wọn ba ronu piwada, Ọlọhun Ọba Allah jẹ onimimọ nipa ẹniti o lẹtọ si iya ati ẹniti o lẹtọ si amojukuro Rẹ, ọjọgbọn nibi ofin Rẹ ati idari Rẹ, awọn wọnyi ni: Murọọrọ ọmọ Rọbii’i ati Ka’b ọmọ Malik ati Hilaalu ọmọ Umayyah.
Ọla ti nbẹ fun igbawaju lọsi ibi igbagbọ ati ise irin ajo si oju ọna Allah ati riran ẹsin se ati titẹle oju ọna awọn ẹniire ti o ti rekọja.
Sise ayaafi Ọlọhun Ọba pẹlu imọ kọkọ, ẹnikankan ko mọ ohun ti o nbẹ ninu ọkan ayaafi Allah.
Ireti nbẹ fun awọn ẹlẹsẹ ninu awọn olugbagbọ ododo ti wọn ba ronu piwada wipe Allah yoo gba ironu piwada wọn, Yoo si fi ori jin wọn, Yoo si tun isẹ wọn se.
Jijẹ dandan saka ati sise alaye ọla ti nbẹ fun un ati didagba soke dukia ati fifọ ẹmin mọ kuro nibi ahun ati ohun ti yatọ si ninu awọn aleebu.