فَسَنُيَسِّرُهُۥ لِلۡعُسۡرَىٰ 10
A si nrọ isẹ buruku fun un, a si sọ isẹ rere di inira fun un.
وَمَا يُغۡنِي عَنۡهُ مَالُهُۥٓ إِذَا تَرَدَّىٰٓ 11
Owo rẹ eyiti o se ahun pẹlu rẹ ko le rọ ọ lọrọ kankan nigbati o ba parun, ti o si wọ ina.
إِنَّ عَلَيۡنَا لَلۡهُدَىٰ 12
Dajudaju ki a se alaye ọna ododo ati ibajẹ jẹ dandan le wa lori.
وَإِنَّ لَنَا لَلۡأٓخِرَةَ وَٱلۡأُولَىٰ 13
Atipe paapaa isẹmin ọrun jẹ ti wa, bẹẹni isẹmin aye naa jẹ tira, a o maa se bi ose wuwa nibẹ, eleyi ko si fun ẹnikankan yatọ si wa.
فَأَنذَرۡتُكُمۡ نَارٗا تَلَظَّىٰ 14
Mo se ikilọ fun yin - ẹyin eniyan - kuro nibi ina ti wọn nko, ti ẹ ba yapa Allah.
لَا يَصۡلَىٰهَآ إِلَّا ٱلۡأَشۡقَى 15
Ẹnikan ko le fi ara kin gbigbona ina yii ayaafi oloriburuku ju, oun si ni keferi.
ٱلَّذِي كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ 16
Ẹniti o pe ohun ti ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun nirọ, ti o si gunri kuro nibi mimu asẹ Allah sẹ.
وَسَيُجَنَّبُهَا ٱلۡأَتۡقَى 17
Ẹniti o si paya ju tii se Abu Bakr ki Allah yọnu si yoo ta kete kuro nibẹ.
ٱلَّذِي يُؤۡتِي مَالَهُۥ يَتَزَكَّىٰ 18
Ẹniti o na owo rẹ si ojupọnna rere ki o le mọra kuro nibi awọn ẹsẹ.
وَمَا لِأَحَدٍ عِندَهُۥ مِن نِّعۡمَةٖ تُجۡزَىٰٓ 19
Ko si na ohun ti o na ninu owo rẹ lati fi se ẹsan idẹkun kan ti ẹnikan se fun un.
إِلَّا ٱبۡتِغَآءَ وَجۡهِ رَبِّهِ ٱلۡأَعۡلَىٰ 20
Ko gbero nibi ohun ti o nna nibi owo rẹ yii ju oju rere Ọlọhun rẹ ti o ga lori ẹda Rẹ lọ.
وَلَسَوۡفَ يَرۡضَىٰ 21
Yoo si pada yọnu si ohun ti Allah fun ninu ẹsan alapọnle.
سورة (MAKIYYAH)
Sise alaye amojuto Allah fun anọbi Rẹ ni ibẹrẹ alamọri rẹ ati igbẹyin rẹ.
وَٱلضُّحَىٰ 1
Allah fi akọkọ ọsan bura.
وَٱلَّيۡلِ إِذَا سَجَىٰ 2
O si fi oru nigbati o ba sookun, ti awọn eniyan si dakẹ nipa lilọ bibọ nibẹ bura.
مَا وَدَّعَكَ رَبُّكَ وَمَا قَلَىٰ 3
Ọlọhun rẹ ko gbe ọ ju silẹ - irẹ ojisẹ - ko si korira rẹ; gẹgẹ bi awọn ẹlẹbọ se nsọ nigbati imisi ja.
وَلَلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ لَّكَ مِنَ ٱلۡأُولَىٰ 4
Atipe paapaa ile ọrun loore fun ju aye lọ; nitori idẹkun lailai ti ko nii ja ti o wa nibẹ.
وَلَسَوۡفَ يُعۡطِيكَ رَبُّكَ فَتَرۡضَىٰٓ 5
Yoo si pada fun ọ ni ẹsan ti o pọ ati fun awọn ijọ rẹ titi iwọ yoo fi yọnu si ohun ti o fun ọ ati ohun ti o fun ijọ rẹ.
أَلَمۡ يَجِدۡكَ يَتِيمٗا فََٔاوَىٰ 6
Paapaa O ri ọ ni ọmọde ti baba rẹ ti ku, O si se ibusẹrisi fun ọ nitoripe O saanu rẹ pẹlu baba rẹ tii se Abdul Mutọlib, lẹyin naa ni ẹgbọn baba rẹ Abu Tọlib.
وَوَجَدَكَ ضَآلّٗا فَهَدَىٰ 7
O ri ọ ni ẹniti o ko mọ tira naa tabi igbagbọ naa, o si mọ ọ nkan ti o ko mọ ninu eleyi.
وَوَجَدَكَ عَآئِلٗا فَأَغۡنَىٰ 8
O tun ri ọ ni olosi, O si rọ ọ lọrọ.
فَأَمَّا ٱلۡيَتِيمَ فَلَا تَقۡهَرۡ 9
Mase wuwa aida si ẹniti o padanu baba rẹ ni kekere, ki o ma si yẹpẹrẹ rẹ.
وَأَمَّا ٱلسَّآئِلَ فَلَا تَنۡهَرۡ 10
Mase jagbe mọ onibeere ti o ni bukaata.
وَأَمَّا بِنِعۡمَةِ رَبِّكَ فَحَدِّثۡ 11
Ki o si dupẹ awọn idẹkun Allah le ọ lori, ki o si maa sọ.
سورة (MAKIYYAH)
Idẹkun ti nbẹ fun anabi ẹniti ikẹ ati ola nbẹ fun pẹlu pipe awọn idẹra aifojuri ti o wa fun.
أَلَمۡ نَشۡرَحۡ لَكَ صَدۡرَكَ 1
Paapaa A ti sipaya igbaaya rẹ, O si fi ifẹ gbigba imisi si ọ lọkan.
وَوَضَعۡنَا عَنكَ وِزۡرَكَ 2
A si fori ohun ti o se siwaju ninu ẹsẹ jin ọ, A si sọ ohun ti o wuwo kalẹ fun ọ ni awọn asiko aimọkan eyiti o wa tẹlẹ
Ipo anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun lọdọ Ọlọhun rẹ jẹ ohun ti ipo kankan ko sun mọ.
Didupẹ idẹkun jẹ ẹtọ Allah lori ẹru Rẹ.
Jijẹ dandan ikẹ si awọn ọlẹ ati rirọ fun wọn.