وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَآ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَحِيمِ 10
Awọn ti wọn se aimoore si Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si pe awọn amin Rẹ ni irọ, ọkẹ aimọye wọn ẹni ina ni wọn, awọn yoo wọ ibẹ ni ijiya lori sise keferi wọn ati irọ pipa wọn, wọn yoo wa pẹlu rẹ pẹkipẹki bii ọrẹ se ma nwa pẹlu ọrẹ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ إِذۡ هَمَّ قَوۡمٌ أَن يَبۡسُطُوٓاْ إِلَيۡكُمۡ أَيۡدِيَهُمۡ فَكَفَّ أَيۡدِيَهُمۡ عَنكُمۡۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ 11
Ẹyin olugbagbọ ododo, ẹ maa ranti pẹlu ọkan yin ati ahọn yin ifọkanbalẹ ti Ọlọhun Ọba Allah se fun yin, ati ipaya si inu ọkan awọn ọta yin, ni igbakiigba ti wọn ba gbero lati nawọ si yin, lati gba yin mu tabi lati pa yin, Ọlọhun Ọba Allah sẹri wọn kuro lọdọ yin, bẹẹ ni O si layin lọwọ wọn, ẹ paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu titẹle asẹ Rẹ, ki ẹ si jinna si awọn nkan ti O kọ, Ọlọhun Ọba Allah nikan niki olugbagbọ ododo gbara le, nibi ohun ti o le ki aye ati ọrun dara.
۞وَلَقَدۡ أَخَذَ ٱللَّهُ مِيثَٰقَ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ وَبَعَثۡنَا مِنۡهُمُ ٱثۡنَيۡ عَشَرَ نَقِيبٗاۖ وَقَالَ ٱللَّهُ إِنِّي مَعَكُمۡۖ لَئِنۡ أَقَمۡتُمُ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَيۡتُمُ ٱلزَّكَوٰةَ وَءَامَنتُم بِرُسُلِي وَعَزَّرۡتُمُوهُمۡ وَأَقۡرَضۡتُمُ ٱللَّهَ قَرۡضًا حَسَنٗا لَّأُكَفِّرَنَّ عَنكُمۡ سَئَِّاتِكُمۡ وَلَأُدۡخِلَنَّكُمۡ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ فَمَن كَفَرَ بَعۡدَ ذَٰلِكَ مِنكُمۡ فَقَدۡ ضَلَّ سَوَآءَ ٱلسَّبِيلِ 12
Paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti gba adehun ti o kanpa ni ọdọ awọn arọmọdọmọ Isirẹli pẹlu awọn nkan ti a o maa darukọ laipẹ, o si gbe adari mejila dide le wọn lori, gbogbo adari kọọkan ni nmojuto ẹniti nbẹ ni abẹẹ rẹ, Ọlọhun Ọba Allah waa sọ fun awọn ọmọ isirẹli: dajudaju Mo wa pẹlu yin pẹlu aranse ati ikunlọwọ nigbati ẹ ba kirun ni ojupọnna ti o pe, ti ẹ si nyọ saka ninu owow yin, ti ẹ si gba gbogbo awọn ojisẹ Mi gbọ laise onipinya laarin wọn, ti ẹ si ngbe wọn tobi, bakannaa ni ẹ nse aranse fun wọn, ti ẹ si tun nna si ojupọnna daadaa, igbati ẹ ba se gbogbo eleyi patapata, Maa pa gbogbo asise yin ti ẹ ti se rẹ, Maa si yin wọ si inu Alujannah ti awọn akeremọdo nsan ni abẹ orule rẹ ni ọjọ igbende, ẹniti o ba se aimoore lẹyin gbigba adehun eyiti o yi yii, paapaa o ti kuna kuro ni oju ọna ti o tọ niti mọọmọ.
فَبِمَا نَقۡضِهِم مِّيثَٰقَهُمۡ لَعَنَّٰهُمۡ وَجَعَلۡنَا قُلُوبَهُمۡ قَٰسِيَةٗۖ يُحَرِّفُونَ ٱلۡكَلِمَ عَن مَّوَاضِعِهِۦ وَنَسُواْ حَظّٗا مِّمَّا ذُكِّرُواْ بِهِۦۚ وَلَا تَزَالُ تَطَّلِعُ عَلَىٰ خَآئِنَةٖ مِّنۡهُمۡ إِلَّا قَلِيلٗا مِّنۡهُمۡۖ فَٱعۡفُ عَنۡهُمۡ وَٱصۡفَحۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 13
Nitori jija adehun eyiti a gba ni ọwọ wọn yii, a le wọn jinna kuro nibi ikẹ wa, a si sọ ọkan wọn din nkan ti o le koko, daadaa kankan ko le wọ inu rẹ, isiti kankan ko le se ni anfaani, wọn nwọ pada kuro ni ojupọnna rẹ pẹlu pipaarọ awọn gbolohun rẹ ati yiyi itumọ rẹ si nkan ti yoo ba ifẹ inu wọn mu, wọn si gbe isẹ ju silẹ pẹlu abala nkan ti wọn sọ, mọyẹ-mọgbo –ire ojise- lati sipaya ijanba wọbn fun Ọlọhun Ọba Allah ati fun awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ododo, ayaafi diẹ ninu wọn, wọn pe adehun ti wọn gba, se amojukuro fun wọn, mase gba wọn mu, bẹẹni koo se amọkan kuro; dajudaju eyi wa ninu daradara sise, bẹẹni Ọlọhun Ọba Allah fẹran awọn oluse daradara.
Ninu idẹkun Ọlọhun Ọba Allah ti o tobi lori Anọbi ẹniti ikẹ ati ọla nbẹ fun ati awọn ọmọlẹyin rẹ, ohun ni sisọ ti O sọ wọn ati kiko ọwọ awọn keferi ro, ati inira wọn.
Dajudaju igbagbọ ninu awọn ojisẹ, ati sise aranse fun wọn bakanna ni gbigbe irun duro ati yiyọ saka ni ojupọnna ti a fẹ, o jẹ okunfa nla lati ri ibẹ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga, ati sisẹlẹ awọn okunfa aranse ati igbalaaye, ati aforijin ati wiwọ alujannah.
Jija awọn adehun eyiti yoo sọ titẹle awọn ojisẹ di dandan jẹ okunfa lile ọkan ati yiyi rẹ.
Fif ẹni ẹgan kan ojupọnna awọn yahuudi nibi yiyi ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ fun wọn ninu awọn tira ti o wa lati oke sanmọ.