سورة (MADANIYYAH)
Bibopa bose kuro lodo awon osebo ati awon sobeselu ati jijawon logun, ati sisi ojupona ironupiwada fun olutuuba.
بَرَآءَةٞ مِّنَ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦٓ إِلَى ٱلَّذِينَ عَٰهَدتُّم مِّنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ 1
Eleyi ni ibọpa bọsẹ lati Ọlọhun Ọba Allah ati lati ọdọ ojisẹ Rẹ, ati kikede adehun eyi ti ẹ jọ se - ẹyin olugbafa - le lori awọn ọsẹbọ ni erekusu ilẹ larubawa.
فَسِيحُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ أَرۡبَعَةَ أَشۡهُرٖ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّكُمۡ غَيۡرُ مُعۡجِزِي ٱللَّهِ وَأَنَّ ٱللَّهَ مُخۡزِي ٱلۡكَٰفِرِينَ 2
Ki ẹ yaa rin - ẹyin ọlọsẹbọ - lori ilẹ fun osu mẹrin ni ẹni ifọkan balẹ, ko si adehun fun yin lẹyin rẹ, bẹẹ ni ko si ifọkanbalẹ, ki ẹ si mọ amọdaju wipe ẹ ko le bọ kuro nibi iya Ọlọhun Ọba Allah, ti ẹ ba tẹsiwaju lori sise aimoore pẹlu Rẹ, ki ẹ mọ amọdaju wipoe dajudaju Ọlọhun Ọba yoo yẹpẹrẹ awọn keferi pẹlu pipa wọn ati mimuni lẹru ni ile aye, ati mimu wọn wọ ina ni ọjọ igbende, yoo ko sinu eleyi gbogbo ẹniti o ba ja adehun wọn, ati ẹniti adehun wọn ba jẹ nkan ti ko ni asiko kan pato, sugbọn awọn ti wọn ba ni asiko pato koda ki o pọ ju osu mẹrin lọ, wọn yoo pe adehun fun titi di asiko naa.
وَأَذَٰنٞ مِّنَ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦٓ إِلَى ٱلنَّاسِ يَوۡمَ ٱلۡحَجِّ ٱلۡأَكۡبَرِ أَنَّ ٱللَّهَ بَرِيٓءٞ مِّنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ وَرَسُولُهُۥۚ فَإِن تُبۡتُمۡ فَهُوَ خَيۡرٞ لَّكُمۡۖ وَإِن تَوَلَّيۡتُمۡ فَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّكُمۡ غَيۡرُ مُعۡجِزِي ٱللَّهِۗ وَبَشِّرِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ 3
Fifi mọ lati ọdọ Ọlọhun Ọba ati ifimọ lati ọdọ ojisẹ Rẹ si gbogbo awọn eniyan ni ọjọ igunran pe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun bọpa bọsẹ kuro nibi awọn olusẹbọ, ati wipe dajudaju ojisẹ Rẹ naa bọpa bọsẹ kuro ni ọdọ wọn, ti ẹ ba sẹri pada - ẹyin olusẹbọ - kuro nibi ẹbọ yin, ironu piwada yin loore fun yin, sugbọn ti ẹ ba gunri kuro nibi ironu piwada, ki ẹ mọ amọdaju wipe ẹ ko le bọ mọ Ọlọhun Ọba Allah lọwọ, bẹẹ ni ẹ ko le bọ mọ iya Rẹ lọwọ, fun niro - irẹ ojisẹ - awọn ti wọn se aimoore si Ọlọhun Ọba Allah pẹlu nkan ti ko tẹ wọn lọrun, oun ni iya ẹlẹta ti wọn nreti.
إِلَّا ٱلَّذِينَ عَٰهَدتُّم مِّنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ ثُمَّ لَمۡ يَنقُصُوكُمۡ شَيۡٔٗا وَلَمۡ يُظَٰهِرُواْ عَلَيۡكُمۡ أَحَدٗا فَأَتِمُّوٓاْ إِلَيۡهِمۡ عَهۡدَهُمۡ إِلَىٰ مُدَّتِهِمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُتَّقِينَ 4
Ayaafi awọn ti ẹ jọ ni adehun ninu awọn ọlọsẹbọ, ti wọn si pe adehun yin, ti wọn ko ja nkankan nibẹ rara, awọn nikan ni a se adayanri rẹ ninu idajọ ti re kọja, ki ẹ pe adehun wọn fun wọn titi ti asiko rẹ yoo fi tan, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah nifẹ awọn olupaya Ọlọhun Ọba pẹlu sise awọn nkan ti O pa lasẹ ninu rẹ si ni pipe adehun, ati jijinna si nkan ti o kọ ninu rẹ ni ijanba.
فَإِذَا ٱنسَلَخَ ٱلۡأَشۡهُرُ ٱلۡحُرُمُ فَٱقۡتُلُواْ ٱلۡمُشۡرِكِينَ حَيۡثُ وَجَدتُّمُوهُمۡ وَخُذُوهُمۡ وَٱحۡصُرُوهُمۡ وَٱقۡعُدُواْ لَهُمۡ كُلَّ مَرۡصَدٖۚ فَإِن تَابُواْ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَوُاْ ٱلزَّكَوٰةَ فَخَلُّواْ سَبِيلَهُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 5
Ti awọn osu ọwọ ba tan eyiti ẹ fi awọn ọta yin lọkan balẹ lori rẹ, ki ẹ yaa ma ba awọn olusẹbọ ja nibikibi ti ẹ ba ti pade wọn, ẹ fun ilẹ mọ wọn ni gbogbo abule wọn, ẹ sọ wọn ni gbogbo oju ọna wọn, ti wọn ba jawọ kuro nibi ẹbọ lọ si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si ngbe irun duro, ti wọn si nyo zaka ninu dukia wọn; wọn ti di ọmọ iya yin ninu ẹsin Islam; ẹ gbe ibawọnja ju silẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ oluforijin fun ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, o si jẹ olukẹ si wọn.
وَإِنۡ أَحَدٞ مِّنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ ٱسۡتَجَارَكَ فَأَجِرۡهُ حَتَّىٰ يَسۡمَعَ كَلَٰمَ ٱللَّهِ ثُمَّ أَبۡلِغۡهُ مَأۡمَنَهُۥۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَوۡمٞ لَّا يَعۡلَمُونَ 6
Ti ẹnikan ninu awọn ti a se ọjọ rẹ lẹtọ ati dukia rẹ ba wọle, ti o si nwa wiwa lẹgbẹ rẹ -ire ojise- da lohun fun ibeere rẹ titi yoo fi gbọ alukuraani, ki o si mu de aaye ti yoo fi ri ifọkanbalẹ, nitori wipe awọn keferi jẹ ijọ ti ko mọ paapaa ẹsin yii, ti wọn ba mọ lati ibi gbigbọ alukuraani rẹ, o seese ki wọn mọ ọna.
Ẹri ti o fi oju han wa nibi aaya yi lori oju kokoro Islam si idọgbọọgba ajọsepọ ti ita pẹlu awọn ọta lori ijupasilẹ ati ifọkanbalẹ ati igbọra ẹni ye.
Islam ka adehun sise kun, o si se mimu se nisẹ ni ọranyan, o si ka imojuto adehun kun aseyọri igbagbọ, ati ohun ti o sun mọ ipaya Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga.
Dajudaju igberun duro ati yiyọ saka jẹ ẹri lori Islam, ati wipe dajudaju mejeeji jẹ aabo fun Islam, O si sọ di dandan fun ẹniti o ba mojuto mejeeji ninu awọn olugbafa, mimaa sọ ẹjẹ rẹ ati dukia rẹ ayaafi pẹlu ẹtọ Islam; gẹgẹ bi sise nkan ti yoo sọ pipani di dandan, bi pipa ẹmin ti ko lẹsẹ, tabi sise agbere alagbere ti o ti segbeyawo, tabi kikoomọ sinu keferi lẹyin igbagbọ.
Sise ifọkanbalẹ lofin; itumọ rẹ ni wipe: lilẹtọ fifi awọn jagun jagun lọkan balẹ nigbati wọn ba beere fun ni ọdọ awọn olugbafa; ki o le ba gbọ nkan ti o tọka si nini alaafia Islam, nibi eleyi ni a ti ri amojukuro ati apọnle ti nbẹ nibi ibasepọ awọn keferi, o si tun ntọka si gbigbe ọla fun ijupa jusẹ silẹ.