سورة (MAKIYYAH)
Sise alaye agbara Allah kikari rẹ nibi dida ọmọniyan ati didaapada.
وَٱلسَّمَآءِ وَٱلطَّارِقِ 1
Allah fi sanmọ bura, O si fi irawọ eyiti o yọ loru bura.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلطَّارِقُ 2
Kiini o fi mọ ọ - irẹ ojisẹ - isesi irawọ ti o tobi yii?!
ٱلنَّجۡمُ ٱلثَّاقِبُ 3
O nni irawọ ti o nlu iho si sanmọ pẹlu itansan rẹ ti o mọlẹ gan an.
إِن كُلُّ نَفۡسٖ لَّمَّا عَلَيۡهَا حَافِظٞ 4
Ko si ẹmin kan ayaafi ki Allah fi Malaika ti yoo daabobo awọn isẹ rẹ fun isiro ni ọjọ igbende ti i.
فَلۡيَنظُرِ ٱلۡإِنسَٰنُ مِمَّ خُلِقَ 5
Ki ọmọniyan yaa ronu si ibiti Allah ti da a; ki agbara Allah le hande si ati kikagara ọmọniyan.
خُلِقَ مِن مَّآءٖ دَافِقٖ 6
Allah da a lati ibi omin ti nti ara wọn lọpọnpọn, ti o ntu si inu apo ibi.
يَخۡرُجُ مِنۢ بَيۡنِ ٱلصُّلۡبِ وَٱلتَّرَآئِبِ 7
Omin yi njade lati ipi ọpa ẹyin de ibara idi ọkunrin ati eegun igbaaya.
إِنَّهُۥ عَلَىٰ رَجۡعِهِۦ لَقَادِرٞ 8
Dajudaju Oun ti mimọ nbẹ fun –nigbati o da a lati ibi omin yẹpẹrẹ yii- o lagbara lati gbe e dide lẹyin iku rẹ ni alaaye fun isiro ati ẹsan.
يَوۡمَ تُبۡلَى ٱلسَّرَآئِرُ 9
Ọjọ ti wọn yoo se idanwo gbogbo kọkọ, ti wọn yoo si sipaya ohun ti ọkan fi pamọ ninu awọn aniyan ati awọn adisọkan ati ohun ti o yatọ si i, ti ohun ti o dara yoo si da yanri kuro nibi ohun ti o bajẹ.
فَمَا لَهُۥ مِن قُوَّةٖ وَلَا نَاصِرٖ 10
Ko si agbara fun ọmọniyan ni ọjọ yii ti yoo fi kọdi iya Allah, bẹẹni ko si olukunlọwọ ti yoo kun un lọwọ.
وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلرَّجۡعِ 11
Allah fi sanmọ ti o nrọ ojo bura; nitoripe o sọkalẹ ni abala rẹ ni asiko kan lẹyin asiko.
وَٱلۡأَرۡضِ ذَاتِ ٱلصَّدۡعِ 12
O si fi ilẹ bura eyiti o lanu fun ohun ti o wa nibẹ ninu awọn irugbin ati esi ati igi.
إِنَّهُۥ لَقَوۡلٞ فَصۡلٞ 13
Dajudaju Alukuraani ti o sọkalẹ fun Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun jẹ gbolohun kan ti o nse onpinya laarin ododo ati ibajẹ ati otitọ ati irọ.
وَمَا هُوَ بِٱلۡهَزۡلِ 14
Kii se ere ati ibajẹ bikosepe o jẹ igbiyanju ati ododo.
إِنَّهُمۡ يَكِيدُونَ كَيۡدٗا 15
Dajudaju awọn ti wọn npe ohun ti ojisẹ wọn mu wa nirọ, wọn da ete ti o pọ lati da ipepe rẹ pada, ki wọn si ba a jẹ.
وَأَكِيدُ كَيۡدٗا 16
Emi si ndete niti ete lati se afihan ẹsin dida oju ibajẹ bolẹ.
فَمَهِّلِ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَمۡهِلۡهُمۡ رُوَيۡدَۢا 17
Ki o lọ lara - irẹ ojisẹ - awọn keferi yii, lọ wọn lara fun igba diẹ, mase kanju ijiya wọn ati iparun wọn.
سورة (MAKIYYAH)
Riran ẹmin leti isẹmin ọjọ ikẹhun ati lila a kuro nibi siso papọ mọ aye.
سَبِّحِ ٱسۡمَ رَبِّكَ ٱلۡأَعۡلَى 1
Fọ Ọlọhun rẹ mọ ẹniti o ga lori ẹda Rẹ ni ẹniti o npe orukọ Rẹ nigbati o ba ranti Rẹ, ti o si ngbe tobi.
ٱلَّذِي خَلَقَ فَسَوَّىٰ 2
Ẹniti o da ọmọniyan dọgba, ti o si se inaro rẹ ni deedee.
وَٱلَّذِي قَدَّرَ فَهَدَىٰ 3
Ẹniti o fi ebubu si awọn ẹda ni awọn ẹya ẹya ati awọn iran iran rẹ ati awọn iroyin rẹ, o si fi gbogbo ẹda mọ ọna si ohun ti yoo se deede rẹ, ti yoo si bamu.
وَٱلَّذِيٓ أَخۡرَجَ ٱلۡمَرۡعَىٰ 4
Ẹniti o mu ohun ti awọn ẹran yin jẹ jade ni inu ilẹ.
فَجَعَلَهُۥ غُثَآءً أَحۡوَىٰ 5
O si sọ ọ di koriko ti o gbẹ, ti o ti ndi dudu lẹyin igbati ti o ti jẹ tutu gbọdọ.
سَنُقۡرِئُكَ فَلَا تَنسَىٰٓ 6
A o pada ka Alukuraani fun ọ - irẹ ojisẹ - , a o si kojọ si igbaaya rẹ, ti o ko nii gbagbe rẹ, mase gbawaju Jibril nibi kike rẹ gẹgẹ bi o se nse niti oju kokoro ki o mase gbagbe rẹ.
إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُۚ إِنَّهُۥ يَعۡلَمُ ٱلۡجَهۡرَ وَمَا يَخۡفَىٰ 7
Ayaafi ohun ti Allah ba fẹ ki o gbagbe rẹ nitori ọgbọn kan, dajudaju Oun ti mimọ nbẹ fun mọ ohun ti wọn kede rẹ, ati ohun ti wọn fi pamọ, nkankan ko pamọ fun Un ninu eleyi.
وَنُيَسِّرُكَ لِلۡيُسۡرَىٰ 8
A o si sọ isẹ ti yoo yọ Allah ninu di irọrun fun ọ ninu awọn isẹ ti o nmuni wọ ọgba idẹra.
فَذَكِّرۡ إِن نَّفَعَتِ ٱلذِّكۡرَىٰ 9
Se isiti fun awọn eniyan pẹlu ohun ti a nse imisi rẹ si ọ ninu Alukuraani, ki o si ran wọn leti niwọnba igbati iranti ba jẹ gbigbọ.
سَيَذَّكَّرُ مَن يَخۡشَىٰ 10
Ẹniti o npaya Allah ni yoo gba isiti pẹlu awọn isiti rẹ; nitoripe oun ni ẹniti yoo se anfaani pẹlu isiti.
Awọn malaaika yoo daabobo ọmọniyan ati awọn isẹ rẹ, rere rẹ ni tabi aburu rẹ ki o le se isiro le lori.
Lilẹ ete awọn keferi nigbati wọn ba koju ete Allah ti mimọ nbẹ fun.
Ipaya Allah ma ngbeni dide si igba isiti.