سورة (MAKIYYAH)
Kikilọ fun ọmọniyan lati ma gba itanjẹ ati gbigbagbe ọjọ igbende.
إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتۡ 1
Nigbati sanmọ ba lanu fun sisọkalẹ awọn Malaaika ninu rẹ.
وَإِذَا ٱلۡكَوَاكِبُ ٱنتَثَرَتۡ 2
Nigbati awọn irawọ ba jabọ, ti o si fan ka.
وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ فُجِّرَتۡ 3
Nigbati apakan awọn odo ba lanu fun apakan, ti o si jan pọ.
وَإِذَا ٱلۡقُبُورُ بُعۡثِرَتۡ 4
Nigbati awọn saare ba yipo pẹlu yerupẹ ilẹ fun ajinde awọn ti wọn nbẹ nibẹ ninu awọn oku.
عَلِمَتۡ نَفۡسٞ مَّا قَدَّمَتۡ وَأَخَّرَتۡ 5
Nigba yii ni gbogbo ẹmin yoo mọ ohun ti o ti si waju ninu isẹ ati ohun ti o fi sẹyin ninu rẹ, ti ko si se.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡإِنسَٰنُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ ٱلۡكَرِيمِ 6
Ẹyin ọmọ ẹda eniyan ti o jẹ keferi si Ọlọhun rẹ, kinni o mu ọ yapa asẹ Ọlọhun rẹ nigbati o lọ ọ lara, ti ko si kanju fi iya jẹ ọ niti sise apọnle lọdọ Rẹ?!
ٱلَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّىٰكَ فَعَدَلَكَ 7
Ẹniti o mu ọ bẹ lẹyin igbati o ti wa ni aisi, O si se ọ ni ẹniti orikerike rẹ ni dọgba, ti o se ni deede.
فِيٓ أَيِّ صُورَةٖ مَّا شَآءَ رَكَّبَكَ 8
Ninu aworan ti O fẹ lati da ọ ni O ti da ọ, paapaa O si se idẹkun le ọ lori nigbati ko da ọ ni aworan kẹtẹkẹtẹ tabi ọbọ tabi aja tabi ohun ti o yatọ si i.
كَلَّا بَلۡ تُكَذِّبُونَ بِٱلدِّينِ 9
Ọrọ ko ri bi ẹ se nlero rẹ - ẹyin olugba itanjẹ - bikosepe ẹ npe ọjọ iẹsan nirọ, ẹ ko si sisẹ fun un.
وَإِنَّ عَلَيۡكُمۡ لَحَٰفِظِينَ 10
Atipe dajudaju awọn Malaika ti wọn nsọ awọn isẹ yin wa fun yin.
كِرَامٗا كَٰتِبِينَ 11
Ni apọnle lati ọdọ Allah, olukọ nkan ti wọn nkọ awọn isẹ yin.
يَعۡلَمُونَ مَا تَفۡعَلُونَ 12
Wọn mọ ohun ti ẹ nse nisẹ, wọn si nkọ ọ.
إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٖ 13
Dajudaju ọpọ ẹniti o se isẹẹre ti o si ntẹle asẹ yoo wa ninu idẹkun gbere ni ọjọ igbende.
وَإِنَّ ٱلۡفُجَّارَ لَفِي جَحِيمٖ 14
Dajudaju awọn ẹlẹsẹ yoo wa ninu ina ti yoo maa jo wọn.
يَصۡلَوۡنَهَا يَوۡمَ ٱلدِّينِ 15
Wọn yoo wọ ibẹ ni ọjọ ẹsan, ti wọn yoo maa fi ara kin gbigbona rẹ.
وَمَا هُمۡ عَنۡهَا بِغَآئِبِينَ 16
Wọn ko le kuro nibẹ lailai bikosepe wọn yoo wa nibẹ gbere.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ 17
Kinni o fi mọ ọ - irẹ ojisẹ - nipa ọjọ ẹsan?!
ثُمَّ مَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ 18
Lẹyin naa kinni o fi mọ ọ nipa ọjọ ẹsan?!
يَوۡمَ لَا تَمۡلِكُ نَفۡسٞ لِّنَفۡسٖ شَيۡٔٗاۖ وَٱلۡأَمۡرُ يَوۡمَئِذٖ لِّلَّهِ 19
Ọjọ ti ẹnikankan ko nikapa lati se anfaani fun ẹnikankan, gbogbo alamọri pata ni ọjọ yii jẹ ti Allah nikan soso, yoo se bi o se wu U, ko si fun ẹnikankan yatọ si.
سورة (MAKIYYAH)
O da lori alaye isesi awọn eniyan nibi awọn osuwọn ati awọn aaye ọrun niti idẹruba fun awọn oludin osunwọn ku ati awọn opurọ ati jijẹ inaju fun awọn olugbagbọ ododo ti o jẹ ọlẹ.
وَيۡلٞ لِّلۡمُطَفِّفِينَ 1
Iparun ati ofo fun awọn oludin osunwọn ku.
ٱلَّذِينَ إِذَا ٱكۡتَالُواْ عَلَى ٱلنَّاسِ يَسۡتَوۡفُونَ 2
Awọn si ni ẹniti o ma nwa pipe nibi ẹtọ wọn ti wọn ba nwọn osuwọn lọdọ ẹniti o yatọ si wọn laini din ku.
وَإِذَا كَالُوهُمۡ أَو وَّزَنُوهُمۡ يُخۡسِرُونَ 3
Ti wọn ba si nwọn fun eniyan tabi wọn se odiwọn rẹ fun wọn, wọn yoo maa din odiwọn ati osuwọn ku; eleyi si jẹ isesi awọn ara mẹdinah nigbati anọbi se irin ajo ti ikẹ ati ọla nbẹ fun lọ ba wọn.
أَلَا يَظُنُّ أُوْلَٰٓئِكَ أَنَّهُم مَّبۡعُوثُونَ 4
Se awọn ti wọn nse nkan ti ko tọ yii ko mọ amọdaju ni wipe wọn yoo gbe awọn dide lọ si ọdọ Allah?!
Sise ikilọ kuro nibi itanjẹ eyiti o nkọ fun ni lati tẹle ododo.
Kikanra lọdọ awọn sowo sowo wa ninu awọn iwa yẹpẹrẹ, ẹnikan ko si le la kuro nibẹ ayaafi ẹniti o npaya Allah.
Riranti ipaya ọjọ igbende wa ninu ohun ti o tobi ju lati dẹru bani kuro nibi ẹsẹ.