سورة (MAKIYYAH)
Riran awọn keferi ti wọn koni ibasepọ pẹlu Ọlọhun Ọba wọn leti pẹlu awọn ẹri igbedide.
عَبَسَ وَتَوَلَّىٰٓ 1
Ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun dari oju rẹ, o si gunri.
أَن جَآءَهُ ٱلۡأَعۡمَىٰ 2
Nitori wiwa Abdullah ọmọ Umu Maktuum ti o wa itọsọna lọdọ rẹ, o si jẹ afọju, o de nigbati ojisẹ ko iroju pẹlu awọn agbalagba ẹlẹbọ niti irankan si imọna wọn.
وَمَا يُدۡرِيكَ لَعَلَّهُۥ يَزَّكَّىٰٓ 3
Kinni o fi mọ ọ - irẹ ojisẹ - boya afọju yii yoo mọ kuro nibi awọn ẹsẹ rẹ?
أَوۡ يَذَّكَّرُ فَتَنفَعَهُ ٱلذِّكۡرَىٰٓ 4
Tabi ki o gba isiti pẹlu ohun ti o ngbọ ni ọdọ rẹ ninu awọn isiti, ki o si se anfaani pẹlu rẹ.
أَمَّا مَنِ ٱسۡتَغۡنَىٰ 5
Sugbọn ẹniti o rọrọ pẹlu ẹmin rẹ nipa dukia ti o wa lọdọ rẹ kuro nibi igbagbọ si ohun ti o mu wa.
فَأَنتَ لَهُۥ تَصَدَّىٰ 6
Ohun ni iwọ sẹri si, ti o si bo oju wo.
وَمَا عَلَيۡكَ أَلَّا يَزَّكَّىٰ 7
Kinni yoo bẹ pẹlu rẹ nigbati ko ba mọra kuro nibi awọn ẹsẹ rẹ pẹlu ironu piwada lọsi ọdọ Allah.
وَأَمَّا مَن جَآءَكَ يَسۡعَىٰ 8
Sugbọn ẹniti o ba wa ba ọ, ti o wa nse iwadi nipa rere.
وَهُوَ يَخۡشَىٰ 9
Ti o si npaya Ọlọhun rẹ.
فَأَنتَ عَنۡهُ تَلَهَّىٰ 10
Iwọ ko airoju kuro lọdọ rẹ si ọdọ ẹlomiran ti o yatọ si i ninu awọn agbalagba ẹlẹbọ.
كَلَّآ إِنَّهَا تَذۡكِرَةٞ 11
Ọrọ ko ri bayi, dajudaju o jẹ isiti ati iranti fun ẹniti o ba gba.
فَمَن شَآءَ ذَكَرَهُۥ 12
Ẹniti o ba fẹ lati ranti Allah ki o ranti Rẹ, ki o si gba isiti pẹlu ohun ti o wa ninu Alukuraani yii.
فِي صُحُفٖ مُّكَرَّمَةٖ 13
Alukuraani yii wa ninu oju ewe ti o ni apọnle ni ọdọ awọn Malaika.
مَّرۡفُوعَةٖ مُّطَهَّرَةِۢ 14
Ni ohun ti a gbe ga si aaye ti o ga, ni ohun ti o mọ ti ẹgbin tabi eeri ko kan an.
بِأَيۡدِي سَفَرَةٖ 15
O wa lọwọ awn ojisẹ ninu awọn Malaika.
كِرَامِۢ بَرَرَةٖ 16
Ẹniti apọnle lọdọ Ọlọhun wọn, olupọ ni isẹ rere ati awọn itẹle.
قُتِلَ ٱلۡإِنسَٰنُ مَآ أَكۡفَرَهُۥ 17
Wọn gbe ọmọniyan ti o jẹ keferi jinna si ikẹ, ko si ohun ti o lagbara to sise keferi rẹ si Allah!
مِنۡ أَيِّ شَيۡءٍ خَلَقَهُۥ 18
Nibo ni Allah ti da a, ti o fi wa nse igberaga ni ori ilẹ, ti o si se aimoore si I?!
مِن نُّطۡفَةٍ خَلَقَهُۥ فَقَدَّرَهُۥ 19
Lati inu omin kekere ni wọn ti da a, wọn si pebubu isẹmin rẹ ni ipele kan lẹyin ipele.
ثُمَّ ٱلسَّبِيلَ يَسَّرَهُۥ 20
Lẹyin naa, wọn rọ jijade kuro ninu iya rẹ fun un lẹyin awọn ipele wọn yii.
ثُمَّ أَمَاتَهُۥ فَأَقۡبَرَهُۥ 21
Lẹyin naa, O mu iku ba a lẹyin igbati wọn ti pebubu fun ọjọ ori fun un ni isẹmin aye, O si se saare fun un ti yoo ma wa nibẹ titi di ajinde.
ثُمَّ إِذَا شَآءَ أَنشَرَهُۥ 22
Lẹyin naa yoo gbe dide fun isiro ati ẹsan ti o ba fẹ.
كَلَّا لَمَّا يَقۡضِ مَآ أَمَرَهُۥ 23
Ọrọ ko ri bi keferi yii se nlero wipe oun ti se ohun ti o jẹ ọranyan fun oun ninu ẹtọ Ọlọhun rẹ, ko pe ohun ti Allah se ni dandan fun ninu awọn ọranyan.
فَلۡيَنظُرِ ٱلۡإِنسَٰنُ إِلَىٰ طَعَامِهِۦٓ 24
Ki ọmọniyan ti o jẹ keferi si Allah ya boju wo ounjẹ rẹ eyiti o njẹ, bawo ni o se sẹlẹ?!
أَنَّا صَبَبۡنَا ٱلۡمَآءَ صَبّٗا 25
Ipilẹ rẹ wa lati inu ojo ti a sọkalẹ ni sanmọ pẹlu agbara ati pipọ.
ثُمَّ شَقَقۡنَا ٱلۡأَرۡضَ شَقّٗا 26
Lẹyin naa, a la ilẹ lẹnu, o si yanu fun awọn irugbin.
فَأَنۢبَتۡنَا فِيهَا حَبّٗا 27
A si mu awọn nkan horo gẹgẹ bi jeero ati agbado ati ohun ti o yatọ si mejeeji jade ninu rẹ.
وَعِنَبٗا وَقَضۡبٗا 28
A si mu eso inabi ati ounjẹ tutu; ki o le jẹ ounjẹ fun awọn ẹranko wọn.
وَزَيۡتُونٗا وَنَخۡلٗا 29
A si mu eso saetun ati ọpẹ jade nibẹ.
وَحَدَآئِقَ غُلۡبٗا 30
A si mu awọn ọgba ti igi rẹ pọ jade nibẹ.
وَفَٰكِهَةٗ وَأَبّٗا 31
A si mu iapapanu jade, a si mu ohun ti awọn ẹran yin yoo maa jẹ jade nibẹ.
مَّتَٰعٗا لَّكُمۡ وَلِأَنۡعَٰمِكُمۡ 32
Ki o le jẹ anfaani fun yin ati anfaani fun awọn ẹranko yin.
فَإِذَا جَآءَتِ ٱلصَّآخَّةُ 33
Nigbati igbe ti o tobi eyiti yoo rinlẹ ninu awọn eti ba de, ohun si ni ifanfere ẹlẹẹkeji.
يَوۡمَ يَفِرُّ ٱلۡمَرۡءُ مِنۡ أَخِيهِ 34
Ọjọ ti ọmọniyan yoo sare kuro lọdọ ọmọ iya rẹ.
وَأُمِّهِۦ وَأَبِيهِ 35
Ti yoo si salọ kuro lọdọ mama rẹ ati baba rẹ.
وَصَٰحِبَتِهِۦ وَبَنِيهِ 36
Yoo si salọ kuro lọdọ iyawo ati awọn ọmọ rẹ.
لِكُلِّ ٱمۡرِيٕٖ مِّنۡهُمۡ يَوۡمَئِذٖ شَأۡنٞ يُغۡنِيهِ 37
Ẹnikọọkan ninu wọn ni yoo ko airoju kuro lọdọ ẹlomiran nibi lile koko ibanujẹ ni ọjọ yii.
وُجُوهٞ يَوۡمَئِذٖ مُّسۡفِرَةٞ 38
Oju awọn oloriire yoo tan imọlẹ ni ọjọ naa.
ضَاحِكَةٞ مُّسۡتَبۡشِرَةٞ 39
Ni ẹniti o nrẹrin, ti o ndunnu pẹlu ohun ti Allah pese fun un ninu ikẹ Rẹ.
وَوُجُوهٞ يَوۡمَئِذٍ عَلَيۡهَا غَبَرَةٞ 40
Bẹẹni, oju awọn olori buruku yoo keruku ni ọjọ naa.
Eebu Allah si anọbi Rẹ ni ọrọ Abdullahi ọmọ Umu Maktuum tọka si wipe Alukuraani wa lati ọdọ Allah.
Nini ikolekan si akẹkọ mimọ ati wiwa olutọni sọna.
Lile koko awọn ipaya ọjọ igbende nibiti ọmọniyan ko nii ko airoju ayaafi pẹlu ẹmin ara rẹ titi kan awọn anọbi Ọlọhun ti wọn yoo maa sọpe: ẹmin mi, ẹmin mi.