سورة (MAKIYYAH)
Alaye ẹri nini agbara lati se igbedide ati idẹruba nipa atibọtan.
عَمَّ يَتَسَآءَلُونَ 1
Nipa kinni awọn ẹlẹbọ wọnyi nbeere fun lẹyin igbati Allah ti gbe ojisẹ Rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun dide si wọn?!
عَنِ ٱلنَّبَإِ ٱلۡعَظِيمِ 2
Apakan wọn nbeere lọwọ apakan nipa iro ti o tobi, ohun si ni Alukuraani ti a sọkalẹ fun ojisẹ wọn, ti o kun fun iro ajinde.
ٱلَّذِي هُمۡ فِيهِ مُخۡتَلِفُونَ 3
Alukurani yii ti wọn nse iyapa nipa ohun ti wọn fi royin rẹ; nibi wipe o jẹ idan tabi orin tabi agbegba tabi aalọ awọn ẹni akọkọ.
كَلَّا سَيَعۡلَمُونَ 4
Ọrọ ko ri bi wọn se lero. Awọn olupe Alukuraani nirọ yii yoo pada mọ igbẹyin irọ pipa wọn ti ko dara.
ثُمَّ كَلَّا سَيَعۡلَمُونَ 5
Lẹyin naa, eleyi yoo si rinlẹ fun wọn.
أَلَمۡ نَجۡعَلِ ٱلۡأَرۡضَ مِهَٰدٗا 6
Se a ko se ilẹ ni pẹrẹsẹ fun wọn ti o dara fun diduro le lori ni?!
وَٱلۡجِبَالَ أَوۡتَادٗا 7
A si se oke sibẹ ni ipo awọn eekan ti o nkọ fun gbigbọn riri.
وَخَلَقۡنَٰكُمۡ أَزۡوَٰجٗا 8
A si da yin - ẹyin eniyan - ni iran iran: akọ ati abo wa ninu yin.
وَجَعَلۡنَا نَوۡمَكُمۡ سُبَاتٗا 9
A si se oorun yin ohun ti ẹ o fi maa ja kuro nibi sisapa, ki ẹ le sin min.
وَجَعَلۡنَا ٱلَّيۡلَ لِبَاسٗا 10
A si se oru ni asiri fun yin nibi okunkun rẹ gẹgẹbi asọ ti ẹ fi nbo awọn hihoho yin.
وَجَعَلۡنَا ٱلنَّهَارَ مَعَاشٗا 11
A si se ọsan ni aaye ikọrọjọ ati wiwa arisiki.
وَبَنَيۡنَا فَوۡقَكُمۡ سَبۡعٗا شِدَادٗا 12
A si mọ sanmọ meje ti o yi ni mimọ, ti sise rẹ lọgbọn ninu si ike yin.
وَجَعَلۡنَا سِرَاجٗا وَهَّاجٗا 13
A si sọ oorun di atupa ti kiko rẹ lagbara ati titan na rẹ.
وَأَنزَلۡنَا مِنَ ٱلۡمُعۡصِرَٰتِ مَآءٗ ثَجَّاجٗا 14
A si nsọ ọpọ ekikan omin kalẹ lati inu ẹsujo eyiti asiko rirọjo rẹ to.
لِّنُخۡرِجَ بِهِۦ حَبّٗا وَنَبَاتٗا 15
Ki a le mu oniranran horo jade ati oniranran awọn irugbin.
وَجَنَّٰتٍ أَلۡفَافًا 16
A si mu jade lati ara rẹ awọn ọgba ti ọpọ ẹka igi rẹ yipo.
Nigbati Allah sọ idẹkun ti o tọka si agbara Rẹ yii, o tun sọ ajinde ati alukiyaamọ tẹle e; nitoripe ẹniti o lagbara lati da awọn idẹkun yii lagbara lori jiji awọn oku dide ati isiro wọn, O wa sọpe:
إِنَّ يَوۡمَ ٱلۡفَصۡلِ كَانَ مِيقَٰتٗا 17
Dajudaju ọjọ onpinya laarin awọn ẹda jẹ adehun ti a fi aala si pẹlu asiko ti ko nii yapa.
يَوۡمَ يُنفَخُ فِي ٱلصُّورِ فَتَأۡتُونَ أَفۡوَاجٗا 18
Ọjọ ti Malaika yoo fẹ atẹgun si inu iwo ni fifẹ ẹlẹẹkeji, ti awọn ijọ ijọ yoo maa wa - ẹyin eniyan -.
وَفُتِحَتِ ٱلسَّمَآءُ فَكَانَتۡ أَبۡوَٰبٗا 19
Wọn yoo si si sanmọ, awọn iho gẹgẹ bi awọn ilẹkun ti a si yoo si wa nibẹ.
وَسُيِّرَتِ ٱلۡجِبَالُ فَكَانَتۡ سَرَابًا 20
Wọn yoo si se awọn oke ni ohun ti yoo maa rin, ti yoo fi parada di eruku ti a fan ka, yoo da gẹgẹ bi anpeenọ.
إِنَّ جَهَنَّمَ كَانَتۡ مِرۡصَادٗا 21
Dajudaju ina jahannamọ jẹ ohun ti o nlugọ, ti o si nsọni.
لِّلطَّٰغِينَ مََٔابٗا 22
Fun awọn alabosi ni ibusẹrisi ti wọn yoo sẹri si.
لَّٰبِثِينَ فِيهَآ أَحۡقَابٗا 23
Wọn yoo maa wa nibẹ ni awọn asiko kan ati awọn igba kan ti ko lopin.
لَّا يَذُوقُونَ فِيهَا بَرۡدٗا وَلَا شَرَابًا 24
Wọn ko nii tọ atẹgun tutu wo nibẹ, ti yoo mu ki igbona sẹhiru tutu fun wọn, wọn ko si nii tọ nkankan mimu ti yoo dun mọ wọn wo nibẹ.
إِلَّا حَمِيمٗا وَغَسَّاقٗا 25
Wọn ko nii tọ wo ayaafi omin ti o gbona gidigidi ati awọnuwọjẹ ti o nsan lati ara awọn ẹni ina.
جَزَآءٗ وِفَاقًا 26
Ni ẹsan ti o se keferi ti wọn wa lori rẹ ati anu.
إِنَّهُمۡ كَانُواْ لَا يَرۡجُونَ حِسَابٗا 27
Dajudaju nigbati wọn wa ni ile aye, wọn kii paya isiro Allah ti yoo se fun wọn lọrun; nitoripe wọn nigbagbọ si ajinde, ti wọn ba jẹ ẹniti o paya ajinde ni, wọn ko ba nigbagbọ ninu Allah, wọn ko ba si maa sisẹ rere.
وَكَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَا كِذَّابٗا 28
Wọn pe awọn amin wa ti a sọkọlẹ fun ojisẹ Wa nirọ niti pipe e nirọ.
وَكُلَّ شَيۡءٍ أَحۡصَيۡنَٰهُ كِتَٰبٗا 29
Gbogbo isẹ wọn ni a si tọju, ti a si ka, o jẹ ohun ti a kọ si oju ewe awọn isẹ wọn.
فَذُوقُواْ فَلَن نَّزِيدَكُمۡ إِلَّا عَذَابًا 30
Ki ẹ ya tọ iya gbere yii wo -ẹyin olukọja ẹnu aala- a ko nii se alekun nkankan fun yin ju iya lori iya yin lọ.
Lilo ọgbọn Allah lori isẹda jẹ itọka si agbara Rẹ lori dida a pada.
Ikọja ẹnu aala jẹ okunfa wiwọ ina.
Adipele iya wa lori awọn keferi.