كَلَّا بَلۡ تُحِبُّونَ ٱلۡعَاجِلَةَ 20
Ko ri bẹẹ, ọrọ ko ri bi ẹ se npe apemọra rẹ nipa aini amusẹ ajinde, ẹyin mọ wipe ẹniti o lagbara lati da yin ni ipilẹ ko le kagara lati ta yin ji lẹyin iku yin sugbọn okunfa ti ẹ fi npe ajinde nirọ ni ifẹ yin si isẹmin aye eyiti yoo kanju tan.
وَتَذَرُونَ ٱلۡأٓخِرَةَ 21
Ati gbigbe isẹmin ọrun ti ẹ gbe ju silẹ eyiti oju ọna rẹ jẹ didide si ohun ti Allah pa yin lasẹ ninu itẹle ati gbigbe ohun ti O kọ fun yin ju silẹ ninu awọn eewọ.
وُجُوهٞ يَوۡمَئِذٖ نَّاضِرَةٌ 22
Oju awọn ẹni igbagbọ ati oriire ni ọjọ yii yoo tan ti imọlẹ si wa nibẹ.
إِلَىٰ رَبِّهَا نَاظِرَةٞ 23
Ti yoo maa wo Ọlọhun rẹ, ti yoo si maa gbadun rẹ.
وَوُجُوهٞ يَوۡمَئِذِۢ بَاسِرَةٞ 24
Awọn oju awọn ẹni keferi ati oriibu ni ọjọ yii yoo le.
تَظُنُّ أَن يُفۡعَلَ بِهَا فَاقِرَةٞ 25
Yoo mọ amọdaju wipe iya ti o tobi yoo sọkalẹ fun ati iya inira.
كَلَّآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلتَّرَاقِيَ 26
Ọrọ ko ri bi awọn ẹlẹbọ se nyaworan rẹ nibi wipe wọn ko nii fi iya jẹ wọn ti wọn ba ku, ni igbati ẹmin ẹniikọọkan wọn ba de oke igbaaye rẹ.
وَقِيلَ مَنۡۜ رَاقٖ 27
Ti apakan awọn eniyan sọ fun apakan: taani yoo sọrọ wujẹwujẹ si eleyi boya yoo ri iwosan?!
وَظَنَّ أَنَّهُ ٱلۡفِرَاقُ 28
Ti ẹniti ẹmin fẹẹ bọ lara rẹ yoo mọ amọdaju nigba naa wipe iku ni onpinya aye.
وَٱلۡتَفَّتِ ٱلسَّاقُ بِٱلسَّاقِ 29
Ti awọn ilekoko si korajọ si opin aye ati ibẹrẹ ọrun.
إِلَىٰ رَبِّكَ يَوۡمَئِذٍ ٱلۡمَسَاقُ 30
Ti eleyi ba sẹlẹ wọn yoo ti oku lọsi ọdọ Ọlọhun rẹ.
فَلَا صَدَّقَ وَلَا صَلَّىٰ 31
Keferi ko le gba ohun ti ojisẹ Rẹ mu wa fun un lododo, Ko si nii kirun fun Allah ti mimọ nbẹ fun.
وَلَٰكِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ 32
Sugbọn o pe ohun ti ojisẹ Rẹ mu wa nirọ, o si gunri kuro nibẹ.
ثُمَّ ذَهَبَ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ يَتَمَطَّىٰٓ 33
Lẹyin naa keferi si lọ si ọdọ ara ile rẹ, ti o nse akọ nibi irin rẹ niti igberaga.
أَوۡلَىٰ لَكَ فَأَوۡلَىٰ 34
Allah waa se adehun iya fun keferi wipe iya rẹ ti tii lẹyin, o si sun mọ ọ.
ثُمَّ أَوۡلَىٰ لَكَ فَأَوۡلَىٰٓ 35
Lẹyin naa o sẹri akojọ ọrọ naa ni ojupọnna ikanpamọ, o sọpe: (ثُمَّ أَوۡلَىٰ لَكَ فَأَوۡلَىٰٓ) (lẹyin naa o tọ fun ọ, o si tọ).
أَيَحۡسَبُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَن يُتۡرَكَ سُدًى 36
Se ọmọniyan nlero wipe Allah gbe oun ju silẹ lasan ti ko la ofin kankan bọ ọ lọrun ni?
أَلَمۡ يَكُ نُطۡفَةٗ مِّن مَّنِيّٖ يُمۡنَىٰ 37
Se ọmọniyan ko jẹ omin lọgbọ lati ibi aatọ, ti a tu si inu apo ibi ni ọjọ kan ni.
ثُمَّ كَانَ عَلَقَةٗ فَخَلَقَ فَسَوَّىٰ 38
Lẹyin eyi ti o wa di egige ẹjẹ didi, lẹyin naa Allah se ẹda rẹ, O si se ẹda rẹ ni dọgba.
فَجَعَلَ مِنۡهُ ٱلزَّوۡجَيۡنِ ٱلذَّكَرَ وَٱلۡأُنثَىٰٓ 39
O si se iran meji ninu iran rẹ: akọ ati abo?!
أَلَيۡسَ ذَٰلِكَ بِقَٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يُحۡـِۧيَ ٱلۡمَوۡتَىٰ 40
Se ẹniti o da ọmọniyan ninu omin lọgbọ, ti o di ẹjẹ kiki ko wa lagbara lati ta awọn oku ji fun isiro ati ẹsan ni titun ni?! Bẹẹni, dajudaju alagbara ni.
سورة (MADANIYYAH)
Riran ọmọniyan leti ipilẹ isẹda rẹ ati ibusẹrisi rẹ, ati alaye ohun ti Allah pese silẹ ninu fun awọn ẹni rẹ.
هَلۡ أَتَىٰ عَلَى ٱلۡإِنسَٰنِ حِينٞ مِّنَ ٱلدَّهۡرِ لَمۡ يَكُن شَيۡٔٗا مَّذۡكُورًا 1
Paapaa asiko ti o gun, ti o jẹ aimọ, ti ko si iranti fun un, ti re kọja ọmọniyan.
إِنَّا خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ مِن نُّطۡفَةٍ أَمۡشَاجٖ نَّبۡتَلِيهِ فَجَعَلۡنَٰهُ سَمِيعَۢا بَصِيرًا 2
Dajudaju Awa ni a da ọmọniyan lati ibi omin lọgbọ ti a ropọ laarin omin ọkunrin ati omin obinrin, a se idanwo fun un lori ohun ti a se ni dandan fun un ninu awọn nkan ilabọrun, a si se e ni olugbọ oluri ki o le dide si ohun ti a la bọ ọ lọrun ninu ofin.
إِنَّا هَدَيۡنَٰهُ ٱلسَّبِيلَ إِمَّا شَاكِرٗا وَإِمَّا كَفُورًا 3
Dajudaju Awa ni a se alaye oju ọna imọna fun un lori ahọn awọn ojisẹ Wa eleyi si jẹ ki oju ọna hande fun, ninu ki o m, ọna si oju ọna ti o tọ, ki o si jẹ ẹru olugbagbọ oludupẹ fun Allah lẹyin eleyi tabi ki o sọnu kuro nibẹ, ki o di ẹru, keferi, oniyan fun awọn amin Allah.
Nigbati Allah salaye iran meji olumọna ati ẹni isina, O tun salaye ẹsan awọn mejeeji, O si sọpe:
إِنَّآ أَعۡتَدۡنَا لِلۡكَٰفِرِينَ سَلَٰسِلَاْ وَأَغۡلَٰلٗا وَسَعِيرًا 4
Dajudaju Awa ni a pese awọn sẹkẹsẹkẹ ti wọn yoo fi maa wọ awọn ti wọn se keferi si Allah ati si awọn ojisẹ Rẹ ninu ina ati awọn ẹwọn Rẹ ti wọn yoo ki bọ wọn lọrun ni ibẹ ati ina ti o njo.
إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ يَشۡرَبُونَ مِن كَأۡسٖ كَانَ مِزَاجُهَا كَافُورًا 5
Dajudaju awọn olugbagbọ ododo ti wọn ntẹle ti Allah yoo maa mu ninu ife ọti ti o kun, ti a ro pọ mọ kafuurọ nitori didun oorun rẹ ni ọjọ igbende.
Ewu ifẹ aye ati igunri kuro ni ọrun.
Fifi idanwo sise fun ọmọniyan rinlẹ eleyi si jẹ ninu apọnle Allah fun un.
Wiwo adojukọ Allah ti o lapọnle wa ninu idẹkun ti o tobi.