سورة (MAKIYYAH)
Alaye awọn okunfa ti o nranni lọwọ lati le se isẹ ipepe.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمُزَّمِّلُ 1
Mo pe irẹ ti o da asẹ rẹ bora (tumọ si: anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun).
قُمِ ٱلَّيۡلَ إِلَّا قَلِيلٗا 2
Kirin ni ilẹ ayaafi ni igba diẹ ninu rẹ.
نِّصۡفَهُۥٓ أَوِ ٱنقُصۡ مِنۡهُ قَلِيلًا 3
Kirin ni idaji rẹ ti o ba fẹ tabi kirin ni odiwọn ti o kere si ilaji diẹ ti yoo fi de idata rẹ.
أَوۡ زِدۡ عَلَيۡهِ وَرَتِّلِ ٱلۡقُرۡءَانَ تَرۡتِيلًا 4
Tabi ki o lekun un ti yoo fi de idameji idata, ki o se alaye Alukuraani nigbati o ba ka a, ki o se pẹlẹ nibi kika rẹ.
إِنَّا سَنُلۡقِي عَلَيۡكَ قَوۡلٗا ثَقِيلًا 5
Awa ni a o ju Alukuraani - irẹ ojisẹ - si ọ, o si jẹ gbolohun ti o wuwo; nitori awọn ọranyan ati awọn aala ati awọn idajọ ati awọn ẹkọ ti o wa nibẹ ati ohun ti o yatọ si i.
إِنَّ نَاشِئَةَ ٱلَّيۡلِ هِيَ أَشَدُّ وَطۡٔٗا وَأَقۡوَمُ قِيلًا 6
Dajudaju awọn asiko oru jẹ ohun ti o le ni sise deedee ọkan pẹlu kike e ati gbolohun ti o se deedee ju.
إِنَّ لَكَ فِي ٱلنَّهَارِ سَبۡحٗا طَوِيلٗا 7
Dajudaju lilọ bibọ nibi awọn isẹ rẹ nbẹ fun ọ ni ọsan, ti iwọ yoo fi ri idiwọ kuro nibi kika Alukuraani, ki o ya rirun loru.
وَٱذۡكُرِ ٱسۡمَ رَبِّكَ وَتَبَتَّلۡ إِلَيۡهِ تَبۡتِيلٗا 8
Ki o si ranti Allah ni oniranran iranti, ki o dawa ni ọdọ Rẹ ti mimọ nbẹ fun niti didara pẹlu sise afọmọ ijọsin fun Un.
رَّبُّ ٱلۡمَشۡرِقِ وَٱلۡمَغۡرِبِ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ فَٱتَّخِذۡهُ وَكِيلٗا 9
Ọba ibuyọ ati Ọba ibuwọ, ko si ẹni ijọsin fun tootọ ayaafi Oun, ki o mu U ni alatilẹyin ti iwọ yoo gbara le nibi alamọri rẹ patapata.
وَٱصۡبِرۡ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَٱهۡجُرۡهُمۡ هَجۡرٗا جَمِيلٗا 10
Ki o se suuru lori ohun ti awọn opurọ nsọ nipa sise yẹyẹ ati eebu, ki o si jinna si wọn ni ijina ti ko si suta nibẹ.
وَذَرۡنِي وَٱلۡمُكَذِّبِينَ أُوْلِي ٱلنَّعۡمَةِ وَمَهِّلۡهُمۡ قَلِيلًا 11
Mase ko isesi awọn opurọ si ọkan, awọn igbadun pẹlu awọn igbadun aye, fi emi ati wọn silẹ, ki o si se suuru diẹ fun wọn ti asiko wọn yoo fi de.
إِنَّ لَدَيۡنَآ أَنكَالٗا وَجَحِيمٗا 12
Dajudaju onde ti o nipọn ati ina ti o njo geere nbẹ ni ọdọ Wa lọrun.
وَطَعَامٗا ذَا غُصَّةٖ وَعَذَابًا أَلِيمٗا 13
Ati ounjẹ ti yoo maa ja ọfun nitori lile koko kikoro rẹ ati iya ti o nira ni alekun lori ohun ti o ti gbawaju.
يَوۡمَ تَرۡجُفُ ٱلۡأَرۡضُ وَٱلۡجِبَالُ وَكَانَتِ ٱلۡجِبَالُ كَثِيبٗا مَّهِيلًا 14
Iya ti yoo sẹlẹ fun awọn opurọ yii jẹ ni ọjọ ti ilẹ yoo maa min ati awọn oke, oke yoo di yerupẹ ti yoo maa san, ti yoo si fan ka nitori lile koko ipaya rẹ.
إِنَّآ أَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡكُمۡ رَسُولٗا شَٰهِدًا عَلَيۡكُمۡ كَمَآ أَرۡسَلۡنَآ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ رَسُولٗا 15
Dajudaju Awa ni a gbe ojisẹ kan ni ẹlẹri lori awọn isẹ yin dide si yin ni ọjọ igbende gẹgẹ bi a se ran ojisẹ kan tii se Musa ẹniti ọla nbẹ fun si fir'aona.
فَعَصَىٰ فِرۡعَوۡنُ ٱلرَّسُولَ فَأَخَذۡنَٰهُ أَخۡذٗا وَبِيلٗا 16
Fir'aona si yapa ojisẹ naa ti a ran si lati ọdọ Ọlọhun rẹ, a si fi iya ti o le koko pẹlu itẹri jẹ ẹ ni ile aye, ni ọrun iya ina si wa fun un, ki ẹyin mase yapa ojisẹ yin, ki ohun ti o kan wọn maẹa sẹlẹ si yin.
فَكَيۡفَ تَتَّقُونَ إِن كَفَرۡتُمۡ يَوۡمٗا يَجۡعَلُ ٱلۡوِلۡدَٰنَ شِيبًا 17
Bawo ni ẹ o se kọ fun ẹmin yin, ti ẹ o si daaboboo - ti ẹ ba se keferi si Allah, ti ẹ si pe ojisẹ Rẹ nirọ - ni ọjọ ti ile koko rẹ gun pẹlu wiwu ewu ori awọn ọmọ keekee ke nitori lile koko ipaya rẹ ati gigun rẹ.
ٱلسَّمَآءُ مُنفَطِرُۢ بِهِۦۚ كَانَ وَعۡدُهُۥ مَفۡعُولًا 18
Sanmọ yoo san nitori ipaya rẹ adehun Allah yoo ni imusẹ laini iye meji.
إِنَّ هَٰذِهِۦ تَذۡكِرَةٞۖ فَمَن شَآءَ ٱتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ سَبِيلًا 19
Dajudaju isiti yii - ti o kun fun alaye ohun ti nbẹ ni ọjọ igbende ni ipaya ati ile koko - jẹ iranti ti awọn olugbagbọ ododo yoo se anfaani pẹlu rẹ, ẹniti o ba fẹ igbamun ọna ti yoo mu de ọdọ Ọlọhun rẹ, ki o gba a mun.
Pataki didide loru ati kike Alukuraani ati iranti Allah ati suuru fun olupepe si ọdọ Allah.
Pipa lofo ọkan loru ni oripa nibi akọsori ati agbọye.
Lila ojuse bọrun bukaata si itọju ojiji.
Ayọpọrọ ati igbalaaye ninu idẹkun ma nkọdini kuro ni oju ọna Allah.