سورة (MAKIYYAH)
Biba ẹsin awọn ẹlẹbọ jẹ, pẹlu alaye isesi awọn aljannu ati igbagbọ wọn lẹyin gbigbọ Al-Qur'an.
قُلۡ أُوحِيَ إِلَيَّ أَنَّهُ ٱسۡتَمَعَ نَفَرٞ مِّنَ ٱلۡجِنِّ فَقَالُوٓاْ إِنَّا سَمِعۡنَا قُرۡءَانًا عَجَبٗا 1
Sọ - irẹ ojisẹ - fun ijọ rẹ: Allah ransẹ imisi si mi wipe dajudaju ijọ kan ninu awọn alujannu ni agbegbe kan ti a npe ni ‘batinu nakila’ wipe o tẹti gbọ kike Alukuraani mi, nigbati wọn wa sẹri si ọdọ ijọ wọn, wọn sọ fun wọn pe: dajudaju awa gbọ ọrọ kan ti wọn ke, ti o jọni loju ninu alaye rẹ ati didantọ rẹ.
يَهۡدِيٓ إِلَى ٱلرُّشۡدِ فََٔامَنَّا بِهِۦۖ وَلَن نُّشۡرِكَ بِرَبِّنَآ أَحَدٗا 2
Ọrọ ti a gbọ yii tọka si sise deede nibi adisọkan ati gbolohun ati isẹ, a si nigbagbọ si i, a ko si nii se ẹbọ kankan si Ọlọhun wa eyiti o sọ ọ kalẹ.
وَأَنَّهُۥ تَعَٰلَىٰ جَدُّ رَبِّنَا مَا ٱتَّخَذَ صَٰحِبَةٗ وَلَا وَلَدٗا 3
A si nigbagbọ wipe dajudaju - titobi Ọlọhun wa ga ati gbigbọngbọn Rẹ - ko ni iyawo ati ọmọ gẹgẹ bi awọn ẹlẹbọ se nsọ.
وَأَنَّهُۥ كَانَ يَقُولُ سَفِيهُنَا عَلَى ٱللَّهِ شَطَطٗا 4
Atipe dajudaju esu nsọ gbolohun ti ko yẹ nipa Allah nipa fifi iyawo ati ọmọ ti si ọdọ Rẹ ti mimọ nbẹ fun.
وَأَنَّا ظَنَنَّآ أَن لَّن تَقُولَ ٱلۡإِنسُ وَٱلۡجِنُّ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗا 5
Atipe dajudaju Awa lero wipe awọn ẹlẹbọ ninu eniyan ati alujannu wọn ko nii pa irọ nigbati wọn ti nlero wipe O ni iyawo ati ọmọ, a si gba ọrọ wọn gbọ niti kikọse wọn.
وَأَنَّهُۥ كَانَ رِجَالٞ مِّنَ ٱلۡإِنسِ يَعُوذُونَ بِرِجَالٖ مِّنَ ٱلۡجِنِّ فَزَادُوهُمۡ رَهَقٗا 6
Atipe dajudaju awọn ọkunrin kan ninu eniyan ma nfi awọn ọkunrin kan ninu alujannu se idaabobo nigbati wọn ba sọ si aaye ipaya ni igba imọkan, ikan ninu wọn yoo sọpe: mo fi asiwaju ọgbun yii wa isọ kuro nibi aburu awọn omugọ ijọ naa, bayi ni awọn ọkunrin ninu eniyan wa lekun ni ipaya ati ẹru lọdọ awọn ọkunrin ninu alujannu.
وَأَنَّهُمۡ ظَنُّواْ كَمَا ظَنَنتُمۡ أَن لَّن يَبۡعَثَ ٱللَّهُ أَحَدٗا 7
Atipe eniyan lero gẹgẹ bi ẹ se lero - irẹ alujann- wipe dajudaju Allah ko le gbe ẹnikankan dide lẹyin iku rẹ fun isiro ati ẹsan.
وَأَنَّا لَمَسۡنَا ٱلسَّمَآءَ فَوَجَدۡنَٰهَا مُلِئَتۡ حَرَسٗا شَدِيدٗا وَشُهُبٗا 8
Atipe awa beere fun iro sanmọ ati ri sanmọ ni ohun ti o kun fun oludaabobo ti o lagbara ninu awọn malaaika, ti wọn nsọ ọ kuro nibi jiji ọrọ gbọ eyiti a nse, o si tun kun fun ina jijo ti wọn nju si gbogbo ẹniti o ba sun mọ sanmọ.
وَأَنَّا كُنَّا نَقۡعُدُ مِنۡهَا مَقَٰعِدَ لِلسَّمۡعِۖ فَمَن يَسۡتَمِعِ ٱلۡأٓنَ يَجِدۡ لَهُۥ شِهَابٗا رَّصَدٗا 9
Atipe dajudaju awa siwaju jẹ ẹniti o mu aaye kan ni sanmọ ti a ti ngbọ ohun ti awọn malaika ba ri mu, ti a si nfun awọn alagbegba ni ilẹ niro, bẹẹni ọrọ si ti yi pada, ẹniti o ba tẹti gbọ ọ ni isinyii ninu wa, yoo ri ina ti o njo, ti wọn pese fun un, ti o ba sun mọ, wọn yoo ransẹ rẹ si, yoo si jo o.
وَأَنَّا لَا نَدۡرِيٓ أَشَرٌّ أُرِيدَ بِمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ أَمۡ أَرَادَ بِهِمۡ رَبُّهُمۡ رَشَدٗا 10
Atipe dajudaju awa ko mọ okunfa idaabobo ti o le yii; se wọn gbero aburu ro awọn ẹni ilẹ tabi dajudaju Allah gbero rere ro wọn, paapaa iro sanmọ ti ja kuro ni ọdọ wa.
وَأَنَّا مِنَّا ٱلصَّٰلِحُونَ وَمِنَّا دُونَ ذَٰلِكَۖ كُنَّا طَرَآئِقَ قِدَدٗا 11
Atipe dajudaju awa - awujọ alujannu -: awọn olubẹru ẹniire wa ninu wa, awọn keferi ati pokii naa si wa ninu wa; a jẹ iran ti o yatọ ati onifẹ inu ti o ta kete.
وَأَنَّا ظَنَنَّآ أَن لَّن نُّعۡجِزَ ٱللَّهَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَن نُّعۡجِزَهُۥ هَرَبٗا 12
Atipe awa mọ amọdaju wipe a ko le ja bọ mọ Allah lọwọ ti mimọ nbẹ fun ti O ba gbero kan ro wa, a ko si le bọ niti sisa nitori imọ Rẹ ti rọ kirika wa.
وَأَنَّا لَمَّا سَمِعۡنَا ٱلۡهُدَىٰٓ ءَامَنَّا بِهِۦۖ فَمَن يُؤۡمِنۢ بِرَبِّهِۦ فَلَا يَخَافُ بَخۡسٗا وَلَا رَهَقٗا 13
Atipe awa nigbati a gbọ Alukuraani eyiti o ntọni si ohun ti o dọgba, a nigbagbọ si i, ẹniti o ba nigbagbọ si Ọlọhun rẹ ko gbọdọ bẹru ẹdinku awọn daadaa rẹ tabi sise alekun ẹsẹ si awọn ẹsẹ rẹ ti o gbawaju.
Lilapa Alukuraani ti o ga ni ara ẹniti o ba tẹti gbọ pẹlu ọkan mimọ.
Wiwa iranlọwọ pẹlu alujannu wa ninu ẹbọ si Allah ati ohun ti ijiya nbẹ fun ẹniti o ba se e, ti wọn yoo si fi iya jẹ ẹniti o ba se e dipo erongba rẹ ni ile aye.
Jijẹ ibajẹ agbegba nitori igbende anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun.
Ninu ẹkọ olugbagbọ ododo ni ko ma se afiti aburu si ọdọ Allah.