عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ خَيۡرٗا مِّنۡهُمۡ وَمَا نَحۡنُ بِمَسۡبُوقِينَ 41
Lori pipaa rọ wọn pẹlu ẹlomiran ti o yatọ si wọn ninu ẹniti o ntẹle ti Allah ati ki a mu iparun ba wọn, a ko kagara nibi eleyi, awa kii si se ẹni ibori nigbati a ba gbero iparun wọn ati ipaarọ wọn pẹlu ẹlomiran ti o yatọ si wọn.
فَذَرۡهُمۡ يَخُوضُواْ وَيَلۡعَبُواْ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ 42
Fi wọn silẹ - irẹ ojisẹ - ki wọn tẹri sinu ibajẹ ati ọna anu ti wọn wa, ki wọn si maa sere ninu isẹmin aye wọn ti wọn yoo fi pade ọjọ igbende eyiti wọn se ni adehun fun wọn ninu Alukuraani.
يَوۡمَ يَخۡرُجُونَ مِنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ سِرَاعٗا كَأَنَّهُمۡ إِلَىٰ نُصُبٖ يُوفِضُونَ 43
Ọjọ ti wọn yoo jade ninu awọn saare yarayara gẹgẹ bi ẹni pe wọn gbawaju ara wọn lọsi ibi oke.
خَٰشِعَةً أَبۡصَٰرُهُمۡ تَرۡهَقُهُمۡ ذِلَّةٞۚ ذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمُ ٱلَّذِي كَانُواْ يُوعَدُونَ 44
Ti oju wọn yoo kọlẹ, iyẹpẹrẹ yoo bo wọn daru, ọjọ yii ni ọjọ ti wọn se ni adehun fun wọn ni ile aye, ti wọn ko si bikita pẹlu rẹ.
سورة (MAKIYYAH)
Sisalaye ilana ipepe fun awọn olupepe, lati ibi itan Nuuh.
إِنَّآ أَرۡسَلۡنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوۡمِهِۦٓ أَنۡ أَنذِرۡ قَوۡمَكَ مِن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ 1
Dajudaju awa ni a gbe Nuha dide si awọn ijọ rẹ, ki o maa pe wọn lati dẹruba awọn ijọ rẹ siwaju ki iya inira to wa ba wọn nitori ẹbọ ti wọn wa lori rẹ si Allah.
قَالَ يَٰقَوۡمِ إِنِّي لَكُمۡ نَذِيرٞ مُّبِينٌ 2
Nuha sọ fun awọn ijọ rẹ: ẹyin ijọ mi, dajudaju mo jẹ olukilọ fun yin ni ikilọ ti o fi oju han kuro nibi iya ti o nreti yin ti ẹ ko ba ronu piwada lọsi ọdọ Allah.
أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱتَّقُوهُ وَأَطِيعُونِ 3
Ohun ti ikilọ mi ko sinu ni wipe ki nsọ fun yin: ẹ maa sin Allah nikan soso, ki ẹ si ma sẹbọ kankan pẹlu rẹ, ki ẹ si bẹru Rẹ pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati ijinna si awọn nkan ti o kọ, ki ẹ si maa tẹle mi nibi ohun ti mo ba payin lasẹ.
يَغۡفِرۡ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمۡ وَيُؤَخِّرۡكُمۡ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمًّىۚ إِنَّ أَجَلَ ٱللَّهِ إِذَا جَآءَ لَا يُؤَخَّرُۚ لَوۡ كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 4
Dajudaju ti ẹ ba se eleyi Allah yoo fi ori awọn ẹsẹ yin jin yin, ti ko ba ni asopọ pẹlu ẹtọ awọn ẹru, yoo si mu asiko yin ninu isẹmin aye jinna di asiko ti a fi asiko si ninu imọ Allah, ẹ o maa sẹmi lorilẹ niwọnba igba ti ẹ ba duro deede lori eleyi, dajudaju ti iku ba de ko le lọra, ko da ti ẹ ba mọ, ẹ ba yara lọsi ibi igbagbọ ninu Allah ati ironu piwada kuro nibi ẹbọ ati anu ti ẹ wa.
قَالَ رَبِّ إِنِّي دَعَوۡتُ قَوۡمِي لَيۡلٗا وَنَهَارٗا 5
Nuhu sọpe: irẹ Ọlọhun mi, dajudaju emi pe awọn ijọ mi lọsi ibi ijọsin Rẹ ati mimu wọn ni ọkan soso loru ati ni ọsan ni tẹle tẹle.
فَلَمۡ يَزِدۡهُمۡ دُعَآءِيٓ إِلَّا فِرَارٗا 6
Ipepe mi ko le nkankan kun fun wọn ayaafi sisa ati jijinna si ohun ti mo npe wọn si.
وَإِنِّي كُلَّمَا دَعَوۡتُهُمۡ لِتَغۡفِرَ لَهُمۡ جَعَلُوٓاْ أَصَٰبِعَهُمۡ فِيٓ ءَاذَانِهِمۡ وَٱسۡتَغۡشَوۡاْ ثِيَابَهُمۡ وَأَصَرُّواْ وَٱسۡتَكۡبَرُواْ ٱسۡتِكۡبَارٗا 7
Atipe dajudaju gbogbo igbati mo ba pe wọn lọsi ibi okunfa aforijin awọn ẹsẹ wọn; nipa jijọsin fun lohun nikan ati titẹle tiRẹ ati titẹle ojisẹ Rẹ, -wọn yoo fi awọn ọmọnika ọwọ wọn di awọn eti wọn; ki wọn le kọ gbigbọ ipepe mi, wọn yoo si fi asọ wọn bo oju wọn ti wọn ko fi nii ri mi, wọn yoo si tẹsiwaju lori ẹbọ ti wọn wa, wọn yoo wa se igberaga lati gba ohun ti mo npe wọn si ati itẹriba fun un.
ثُمَّ إِنِّي دَعَوۡتُهُمۡ جِهَارٗا 8
Lẹyin naa dajudaju emi - irẹ Ọlọhun mi - pe wọn ni gbangba.
ثُمَّ إِنِّيٓ أَعۡلَنتُ لَهُمۡ وَأَسۡرَرۡتُ لَهُمۡ إِسۡرَارٗا 9
Lẹyin naa dajudaju emi gbe ohun mi soke nibi ipepe fun wọn, mo si se ni jẹẹjẹ ti o pa mọ, mo si pe wọn pẹlu ohun irẹlẹ; ni ẹniti o nmu iran iran ba ipepe mi fun wọn.
فَقُلۡتُ ٱسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّكُمۡ إِنَّهُۥ كَانَ غَفَّارٗا 10
Mo si sọ fun wọn - ẹyin ijọ mi - ẹ wa aforijin lọdọ Ọlọhun yin pẹlu ironu piwada lọsi ọdọ Rẹ, dajudaju Oun ti mimọ nbẹ un jẹ alaforijin awọn ẹsẹ ẹniti o ba ronu piwada lọsi ọdọ RẸ ninu awọn ẹru Rẹ.
Ewu ifọnu nipa ọrun.
Ijọsin Allah ati ibẹru Rẹ jẹ okunfa aforijin awọn ẹsẹ.
Titẹsiwaju nibi ipepe ati mimu awọn ojupọnna rẹ wa ni iran iran jẹ iwọ ti o jẹ dandan lori awọn olupepe.