سورة (MAKIYYAH)
Sise afihan pipe ọla Allah ati agbara Rẹ; ki O le tani ji si ipaya Rẹ ati ikilọ kuro nibi iya Rẹ.
تَبَٰرَكَ ٱلَّذِي بِيَدِهِ ٱلۡمُلۡكُ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ 1
Oore Allah ẹniti Oun nikan ni ọla wa ni ọwọ Rẹ tobi, O si pọ, O si jẹ alagbara lori gbogbo nkan, nkankan ko le ko agara ba A.
ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلۡمَوۡتَ وَٱلۡحَيَوٰةَ لِيَبۡلُوَكُمۡ أَيُّكُمۡ أَحۡسَنُ عَمَلٗاۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡغَفُورُ 2
Ẹniti O da iku, O si da aaye lati se idanwo fun yin -ẹyin eniyan- taani ninu yin ti yoo se isẹ ti o dara, Oun ni alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, oluforijin gbogbo ẹsẹ ẹniti o ba sẹri ninu awọn ẹru Rẹ.
ٱلَّذِي خَلَقَ سَبۡعَ سَمَٰوَٰتٖ طِبَاقٗاۖ مَّا تَرَىٰ فِي خَلۡقِ ٱلرَّحۡمَٰنِ مِن تَفَٰوُتٖۖ فَٱرۡجِعِ ٱلۡبَصَرَ هَلۡ تَرَىٰ مِن فُطُورٖ 3
Ẹniti O da sanmọ mejeeje, gbogbo sanmọ jẹ ipele loke eyiti o siwaju rẹ laisi isopọ laarin sanmọ kan si sanmọ miran, o ko le ri - irẹ oluworan - afonifoji tabi aidọgba nibi ohun ti Allah sẹda., da iriran pada boya yoo ri sisan tabi lila?! O ko le ri eleyi, ohun ti iwọ yo ri ni isẹda ti o lọgbọn, ti o si yanju.
ثُمَّ ٱرۡجِعِ ٱلۡبَصَرَ كَرَّتَيۡنِ يَنقَلِبۡ إِلَيۡكَ ٱلۡبَصَرُ خَاسِئٗا وَهُوَ حَسِيرٞ 4
Lẹyin naa da iriran pada ni igba kan si igba miran, oju rẹ yoo sẹri si ọ ni ikọlẹ ni ẹniti ko nii ri aleebu tabi aayẹ nibi isẹda sanmọ, oju naa yoo di ikọlẹ ti ko nii le tẹsiwaju nibi iriran.
وَلَقَدۡ زَيَّنَّا ٱلسَّمَآءَ ٱلدُّنۡيَا بِمَصَٰبِيحَ وَجَعَلۡنَٰهَا رُجُومٗا لِّلشَّيَٰطِينِۖ وَأَعۡتَدۡنَا لَهُمۡ عَذَابَ ٱلسَّعِيرِ 5
Paapaa a si ti se ọsọ si sanmọ ti o sun mọ si ilẹ pẹlu awọn irawọ ti o ntan imọlẹ, a si se awọn irawọ naa ni ogunna ti wọn nju mọ awọn esu ti wọn nji ọrọ gbọ, ti o si njo wọn, a si tun pese ina ti o njo geregere fun wọn ni ọrun.
وَلِلَّذِينَ كَفَرُواْ بِرَبِّهِمۡ عَذَابُ جَهَنَّمَۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ 6
Iya ina ti wọn nko nbẹ fun awọn ti wọn se keferi si Ọlọhun wọn ni ọjọ igbende, ibusẹrisi ti yoo sẹri si si buru.
إِذَآ أُلۡقُواْ فِيهَا سَمِعُواْ لَهَا شَهِيقٗا وَهِيَ تَفُورُ 7
Nigbati wọn ba ju wọn si inu ina, wọn yoo gbọ ohun buruku ti o le, ti yoo maa ho ni iho ikona.
تَكَادُ تَمَيَّزُ مِنَ ٱلۡغَيۡظِۖ كُلَّمَآ أُلۡقِيَ فِيهَا فَوۡجٞ سَأَلَهُمۡ خَزَنَتُهَآ أَلَمۡ يَأۡتِكُمۡ نَذِيرٞ 8
Ti apakan rẹ yoo fẹ le jabọ kuro ni apa miran, ti yoo si da yan ri; nitori lile koko ibinu rẹ si ẹniti o ba wọ ibẹ, gbogbo igbati wọn ba ju awọn ẹni rẹ ti o jẹ keferi si inu rẹ ni igba ẹẹkan soso, awọn Malaika ti wọn fi sibẹ yoo maa bi wọn leere ni ibeere ijanilaya: se ojisẹ ko waa ba yin ni ile aye ti o nfi iya Allah dẹru ba yin ni?!
قَالُواْ بَلَىٰ قَدۡ جَآءَنَا نَذِيرٞ فَكَذَّبۡنَا وَقُلۡنَا مَا نَزَّلَ ٱللَّهُ مِن شَيۡءٍ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا فِي ضَلَٰلٖ كَبِيرٖ 9
Awọn keferi sọpe: bẹẹ lo ri, paapaa ojisẹ kan ti waa ba wa ti o fi iya Allah dẹruba wa sugbọn a pe e nirọ, a si sọ fun pe: Allah ko sọ imisi kankan kalẹ, ẹyin kii se nkankan - ẹyin ojisẹ - ayaafi ninu anu ti o tobi kuro nibi ododo.
وَقَالُواْ لَوۡ كُنَّا نَسۡمَعُ أَوۡ نَعۡقِلُ مَا كُنَّا فِيٓ أَصۡحَٰبِ ٱلسَّعِيرِ 10
Awọn keferi si sọpe: ti o ba jasi pe a ngbọ ni gbigbọ sise anfaani pẹlu rẹ ni tabi a se laakaye niti sise laakaye ẹniti o nse adayanri ododo kuro nibi ibajẹ, a ko ni si ninu awujọ awọn ẹni ina bikosepe a jẹ ẹniti o nigbagbọ si awọn ojisẹ, a si gba ohun ti wọn mu wa lododo, a si wa ninu awọn ẹni ọgba idẹra naa.
فَٱعۡتَرَفُواْ بِذَنۢبِهِمۡ فَسُحۡقٗا لِّأَصۡحَٰبِ ٱلسَّعِيرِ 11
Wọn si fi keferi sise ati irọ pipa rinlẹ fun ara wọn, wọn wa lẹtọ si ina, ijina tefe si awọn ẹni ina.
Nigbati Allah sọ awọn iroyin ẹni keferi ati ẹsan wọn, O fi iranti awọn iroyin ẹni igbagbọ ati ẹsan wọn kẹyin rẹ, O wa sọpe:
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَخۡشَوۡنَ رَبَّهُم بِٱلۡغَيۡبِ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَأَجۡرٞ كَبِيرٞ 12
Dajudaju awọn ti wọn nbẹru Allah ni ikọkọ wọn, aforijin fun ẹsẹ wọn nbẹ fun wọn, ẹsan ti o tobi si wa fun wọn, ohun si ni ọgba idẹra.
Nibi mimọ ọgbọn ti o wa nibi isẹda iku ati aaye sọ yiyara gaga sibi isẹ rere siwaju iku di dandan.
Ibinu lile ina jahannamọ lori awọn keferi ati inu lile rẹ jẹ owu Allah ti mimọ nbẹ fun.
Gbigbawaju alujannu ati eniyan si oferefe sanmọ ati gbogbo ẹniti o ba kọja ẹnu aala Rẹ, dajudaju ẹmu yoo ba pẹlu iya.
Titẹle ti Allah ati ibẹru Rẹ ni kọkọ wa ninu awọn okunfa aforijin ati wiwọ ọgba idẹra.