سورة (MADANIYYAH)
Ipepe lọsi ibi itọju ile lori titobi awọn aala Allah ati pipataki iyọnu Rẹ loun nikan.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ لِمَ تُحَرِّمُ مَآ أَحَلَّ ٱللَّهُ لَكَۖ تَبۡتَغِي مَرۡضَاتَ أَزۡوَٰجِكَۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 1
Mo pe irẹ ojisẹ, kilode ti o nse ohun ti Allah se lẹtọ fun ọ leewọ; nipa gbigbadun ẹrubinrin rẹ Maariyah, o nfi eleyi wa iyọnu awọn iyawo rẹ nigbati wọn njowu rẹ? !, Allah si jẹ oluforijin ọ, onikẹ si ọ.
قَدۡ فَرَضَ ٱللَّهُ لَكُمۡ تَحِلَّةَ أَيۡمَٰنِكُمۡۚ وَٱللَّهُ مَوۡلَىٰكُمۡۖ وَهُوَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ 2
Paapaa Allah ti se lofin fun yin lati fi itanran bọra kuro nibi awọn ibura yin, ti ẹ ba ri daadaa nibẹ tabi ẹ ri ẹsẹ nibẹ, Allah yoo si jẹ alaranse fun yin, Oun si ni onimimọ nipa awọn isesi ati ohun ti yoo se yin ni anfaani, ọjọgbọn nibi ofin Rẹ ati ipebubu Rẹ.
وَإِذۡ أَسَرَّ ٱلنَّبِيُّ إِلَىٰ بَعۡضِ أَزۡوَٰجِهِۦ حَدِيثٗا فَلَمَّا نَبَّأَتۡ بِهِۦ وَأَظۡهَرَهُ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ عَرَّفَ بَعۡضَهُۥ وَأَعۡرَضَ عَنۢ بَعۡضٖۖ فَلَمَّا نَبَّأَهَا بِهِۦ قَالَتۡ مَنۡ أَنۢبَأَكَ هَٰذَاۖ قَالَ نَبَّأَنِيَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡخَبِيرُ 3
Tun ranti nigbati anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun sa Hafsọ lẹsa iro kan, ohun ti o wa ninu rẹ ni pe oun ko nii sun mọ iyawo rẹ Maariyah, nigbati Hafsọ fun Aisha ni iro naa, ti Allah si ti fi mọ anọbi nipa fifanka kọkọ rẹ, o bu Hafsọ, o wa sọ fun apakan ninu ohun ti o sọ, o si dakẹ nipa apakan, o si bi leere wipe: taani o fun ọ niro eleyi? O sọpe: Onimimọ nipa gbogbo nkan, Olufunni niro ohun ti o pamọ ni o fun mi niro.
إِن تَتُوبَآ إِلَى ٱللَّهِ فَقَدۡ صَغَتۡ قُلُوبُكُمَاۖ وَإِن تَظَٰهَرَا عَلَيۡهِ فَإِنَّ ٱللَّهَ هُوَ مَوۡلَىٰهُ وَجِبۡرِيلُ وَصَٰلِحُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ بَعۡدَ ذَٰلِكَ ظَهِيرٌ 4
O tọ fun ẹyin mejeeji ki ẹ ronu piwada; nitori ọkan ẹyin mejeeji ti fi si ibi inifẹsi ohun ti ojisẹ Allah korira nipa jijinna si ẹru binrin rẹ ati sise leewọ fun ara rẹ, ti ẹyin mejeeji ba taku lori sisẹri si dida ibajẹ yin silẹ fun un, dajudaju Allah ni alatilẹyin rẹ ati alaranse rẹ, bẹẹni Jibril ati awọn ẹni ẹsa ninu awọn olugbagbọ ododo jẹ alaayo rẹ ati alaranse rẹ, awọn Malaaika naa si jẹ awọn olukunlọwọ fun un ati alaranse lori ẹniti o fi suta se lẹyin aranse ti Allah.
عَسَىٰ رَبُّهُۥٓ إِن طَلَّقَكُنَّ أَن يُبۡدِلَهُۥٓ أَزۡوَٰجًا خَيۡرٗا مِّنكُنَّ مُسۡلِمَٰتٖ مُّؤۡمِنَٰتٖ قَٰنِتَٰتٖ تَٰٓئِبَٰتٍ عَٰبِدَٰتٖ سَٰٓئِحَٰتٖ ثَيِّبَٰتٖ وَأَبۡكَارٗا 5
Ti ẹ ba kọ anọbi Rẹ silẹ, o sun mọ ki Ọlọhun rẹ ti mimọ nbẹ fun paarọ awọn iyawo ti o loore ju yin lọ fun un, ti wọn yoo jẹ olutẹriba fun asẹ Rẹ, ti wọn yoo jẹ olugbaagbọ ati ojisẹ Rẹ, olutẹle ti Allah, oluronu piwada kuro nibi awọn ẹsẹ wọn, awọn olujọsin fun Ọlọhun wọn, awọn gbaawẹ gbaawẹ ati adelebọ ati ọmọge ti ẹnikankan ko tii wọle ti, sugbọn ko kọ wọn silẹ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ قُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ وَأَهۡلِيكُمۡ نَارٗا وَقُودُهَا ٱلنَّاسُ وَٱلۡحِجَارَةُ عَلَيۡهَا مَلَٰٓئِكَةٌ غِلَاظٞ شِدَادٞ لَّا يَعۡصُونَ ٱللَّهَ مَآ أَمَرَهُمۡ وَيَفۡعَلُونَ مَا يُؤۡمَرُونَ 6
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si tun se ohun ti O se lofin fun wọn, ẹ se idaabobo kuro nibi ina ti o tobi, ti wọn nfi eniyan ati okuta ko fun ẹmin yin ati ara ile yin, awọn malaika ti o le mọ ẹniti o ba wọbẹ niti lile wa nibi ina, wọn ko yapa asẹ Allah nigbati o ba pa wọn lasẹ, wọn si ma nse ohun ti o ba pa wọn lasẹ rẹ lailọra tabi se itẹtẹra.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَا تَعۡتَذِرُواْ ٱلۡيَوۡمَۖ إِنَّمَا تُجۡزَوۡنَ مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 7
Wọn yoo sọ fun awọn keferi ni ọjọ igbende: mo pe ẹyin ti ẹ se keferi si Allah, ẹ mase wi awijare ni oni pẹlu ohun ti ẹ wa ori rẹ ninu keferi ati awọn ẹsẹ, wọn ko nii gba awọn awijare yin, ohun ti wọn yoo fi san yin ni oni ni ohun ti ẹ ba se ni ile aye gẹgẹ bi keferi si Allah ati pipe awọn ojisẹ Rẹ nirọ.
Sise lofin itanran kuro nibi ibura.
Sise alaye ipo anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun lọdọ Ọlọhun rẹ niti didaabobo.
Ninu apọnle ẹni afọmọ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun pẹlu awọn iyawo rẹ nipe dajudaju o jẹ ẹniti kii tọpinpin nibi eebu, o si ma ngunri kuro nibi apakan awọn asise lati sẹ ifẹ ku.
Ojuse olugbagbọ ododo fun ara rẹ ati fun awọn ara ile rẹ.