سورة (MADANIYYAH)
Sise alaye awọn idajọ ikọra ẹni silẹ ati itobi aala rẹ ati awọn anfaani ipaya.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ إِذَا طَلَّقۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَطَلِّقُوهُنَّ لِعِدَّتِهِنَّ وَأَحۡصُواْ ٱلۡعِدَّةَۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ رَبَّكُمۡۖ لَا تُخۡرِجُوهُنَّ مِنۢ بُيُوتِهِنَّ وَلَا يَخۡرُجۡنَ إِلَّآ أَن يَأۡتِينَ بِفَٰحِشَةٖ مُّبَيِّنَةٖۚ وَتِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِۚ وَمَن يَتَعَدَّ حُدُودَ ٱللَّهِ فَقَدۡ ظَلَمَ نَفۡسَهُۥۚ لَا تَدۡرِي لَعَلَّ ٱللَّهَ يُحۡدِثُ بَعۡدَ ذَٰلِكَ أَمۡرٗا 1
A pe irẹ Anọbi ti iwọ ba gbero tabi ẹnikan ninu ijọ rẹ naa ba gbero kikọ iyawo rẹ silẹ, ki o ya kọ ọ silẹ ni igba opo akọkọ rẹ; pẹlu ki ikọsilẹ naa jẹ igba imọra ti ko ba ni asepọ lọkọ laya nibẹ, ki ẹ si kiyesi onka naa, ki ẹ le fọkan balẹ lati sẹri pada si ọdọ awọn obinrin yin nibẹ, ti ẹ ba gbero dida wọn pada, ki ẹ paya Allah Ọlọhun yin pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijina si awọn ohun ti O kọ, ẹ mase mu awọn ti ẹ kọ silẹ kuro ninu awọn ile eyiti wọn ngbe, wọn ko si gbọdọ mu ra wọn jade kuro nibẹ titi opo wọn yoo fi tan; ayaafi ti wọn ba se ibajẹ ti o fi oju han gẹgẹ bi agbere, awọn idajọ yii si ni ẹnu aala Allah eyiti o fi lelẹ fun awọn ẹru Rẹ, ẹniti o ba si kọja awọn ẹnu aala Allah, paapaa o ti se abosi si ẹmin ara rẹ nipa mimu lọ si ibi iparun nitori iyapa rẹ si Ọlọhun rẹ, iwọ ko mọ - irẹ olukọni - boya Allah yoo se alamọri oore ti iwọ ko lero lẹyin ikọni silẹ.
فَإِذَا بَلَغۡنَ أَجَلَهُنَّ فَأَمۡسِكُوهُنَّ بِمَعۡرُوفٍ أَوۡ فَارِقُوهُنَّ بِمَعۡرُوفٖ وَأَشۡهِدُواْ ذَوَيۡ عَدۡلٖ مِّنكُمۡ وَأَقِيمُواْ ٱلشَّهَٰدَةَ لِلَّهِۚ ذَٰلِكُمۡ يُوعَظُ بِهِۦ مَن كَانَ يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۚ وَمَن يَتَّقِ ٱللَّهَ يَجۡعَل لَّهُۥ مَخۡرَجٗا 2
Ti wọn ba si sun mọ asiko pipari opo wọn, Ki ẹ ya da wọn pada ni atinuwa ati ibasepọ daadaa tabi ki ẹ gbe dida wọn pada ju silẹ titi opo wọn yoo fi tan, ti wọn yoo fi nikapa lori ọrọ ara wọn pẹlu ki ẹ fun wọn ni awọn ẹtọ ti o nbẹ fun wọn, ti ẹ ba gbero lati da wọn pada tabi lati ya wọn ki ẹ fi onideede meji se ẹlẹri ninu yin lati fi dopin ija, ki ẹ si mu - ẹyin ẹlẹri - ẹri wa niti wiwa oju rere Allah; eyiti a sọ ninu awọn idajọ yii jẹ ohun ti wọn fi nse iranti fun ẹniti o ba nigbagbọ ninu Allah, ti o si nigbagbọ si ọjọ igbende; nitoripe dajudaju oun ni yoo se anfaani pẹlu iranti ati isiti, ẹniti o ba paya Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn nkan ti o kọ, Allah yoo se ibujade fun un kuro nibi gbogbo ifunpinpin ati idaamun ti o ba bọ si.
وَيَرۡزُقۡهُ مِنۡ حَيۡثُ لَا يَحۡتَسِبُۚ وَمَن يَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِ فَهُوَ حَسۡبُهُۥٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ بَٰلِغُ أَمۡرِهِۦۚ قَدۡ جَعَلَ ٱللَّهُ لِكُلِّ شَيۡءٖ قَدۡرٗا 3
Yoo ran an se nibi ti ko ru wuyẹ ni ọkan rẹ, ti ko si si ninu ero rẹ, ẹniti o ba gbe ara le Allah nibi awọn ọrọ Rẹ, Oun yoo to o, dajudaju Allah ni olumusẹ ọrọ Rẹ, dajudaju Allah ni olumusẹ asẹ Rẹ, nkankan ko ka lagara, bẹẹni nkankan ko bọ mọ lọwọ, paapaa Allah ti fi odinwọn si ibiti gbogbo nkan yoo pari si, ilekoko ni odiwọn, irọrun naa ni odinwọn, ikankan ninu mejeeji ko le wa gbere lori ọmọ ẹda eniyan.
وَٱلَّٰٓـِٔي يَئِسۡنَ مِنَ ٱلۡمَحِيضِ مِن نِّسَآئِكُمۡ إِنِ ٱرۡتَبۡتُمۡ فَعِدَّتُهُنَّ ثَلَٰثَةُ أَشۡهُرٖ وَٱلَّٰٓـِٔي لَمۡ يَحِضۡنَۚ وَأُوْلَٰتُ ٱلۡأَحۡمَالِ أَجَلُهُنَّ أَن يَضَعۡنَ حَمۡلَهُنَّۚ وَمَن يَتَّقِ ٱللَّهَ يَجۡعَل لَّهُۥ مِنۡ أَمۡرِهِۦ يُسۡرٗا 4
Awọn ti a kọ silẹ, ti wọn si ti ja kan kuro nibi sise nkan osu nitori didagba ọjọ ori wọn, ti ẹ ba nse iyemeji si bi wọn yoo se se opo wọn, opo wọn jẹ osu mẹta, awọn ti wọn ko tii dagba de ọjọ ori nkan osu sise nitori kikere wọn, opo wọn bakanna naa jẹ osu mẹta, awọn ti o loyun ninu awọn obinrin ipari opo wọn nibi ikọra ẹni silẹ tabi iku: igbatio wọn ba bimọ, ẹniti o ba npaya Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, Allah yoo rọ awọn alamọri rẹ fun un, yoo si sọ gbogbo ohun ti o soro di irọrun fun un.
ذَٰلِكَ أَمۡرُ ٱللَّهِ أَنزَلَهُۥٓ إِلَيۡكُمۡۚ وَمَن يَتَّقِ ٱللَّهَ يُكَفِّرۡ عَنۡهُ سَئَِّاتِهِۦ وَيُعۡظِمۡ لَهُۥٓ أَجۡرًا 5
Eleyi ti A sọ ninu awọn idajọ ikọra ẹni silẹ ati igani pada ati opo jẹ idajọ Allah ti o sọkalẹ fun yin -ẹyin olugbagbọ ododo- ki ẹ le ba muse nisẹ, ẹniti o ba si npaya Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, yoo pa awọn asise rẹ ti o ti gun le rẹ fun un, yoo si fun un ni ẹsan ti o tobi ni ọrun, ohun si ni wiwọ ọgba idẹra ati idebi idẹkun ti ko nii tan.
Idoju ọrọ kọ anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun jẹ idoju ọrọ kọ awọn ijọ rẹ, ti ise adayanri rẹ ko ba fi ẹsẹ rinlẹ.
Jijẹ dandan ibugbe ati inawo fun ẹniti a kọ ni kikọ igbani pada.
Sise lẹtọ imu ẹri wa niti mimu opin ba isẹlẹ iyapa.
Pipọ awọn anfaani ibẹru ati titobi Rẹ.