يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا نُودِيَ لِلصَّلَوٰةِ مِن يَوۡمِ ٱلۡجُمُعَةِ فَٱسۡعَوۡاْ إِلَىٰ ذِكۡرِ ٱللَّهِ وَذَرُواْ ٱلۡبَيۡعَۚ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 9
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si se ohun ti wọn se lofin fun wọn, ti oluperun ba pe irun ni ọjọ akojọ, lẹyin igbati olubanisọrọ ti gori pepele, ki ẹ yara lọ si awọn mọsalaasi lati pesi fun ibanisọrọ ati irun, ki ẹ si gbe owo sise ju silẹ; ki o ma ba di yin lọwọ itẹle asẹ, eyiti a pasẹ rẹ yii nipa pipọ sẹsẹ ati gbigbe owo sise ju silẹ lẹyin ipepe fun irun akojọ ni o loore fun yin - ẹyin olugbagbọ ododo - ti ẹ ba mọ eleyi, ki ẹ ya mu ohun ti allah pa yin lasẹ rẹ sẹ.
فَإِذَا قُضِيَتِ ٱلصَّلَوٰةُ فَٱنتَشِرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَٱبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِ ٱللَّهِ وَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ كَثِيرٗا لَّعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ 10
Ti ẹ ba pari irun akojọ, ki ẹ fan ka si orilẹ ni wiwa ijẹ imu ẹtọ ati gbigbọ awọn bukaata yin, ki ẹ si wa ninu ọla Allah ni ojupọnna ijẹ imu ẹtọ ati ere ẹtọ, ki ẹ si ranti Allah ni akoko isewadi arisiki yin ni iranti ti o pọ, sise iwadi arisiki yin ko gbọdọ mu yin gbagbe iranti Allah; ni irankan erenjẹ si ohun ti ẹ nifẹ si ati ọla kuro nibi ohun ti ẹ nbẹru rẹ.
وَإِذَا رَأَوۡاْ تِجَٰرَةً أَوۡ لَهۡوًا ٱنفَضُّوٓاْ إِلَيۡهَا وَتَرَكُوكَ قَآئِمٗاۚ قُلۡ مَا عِندَ ٱللَّهِ خَيۡرٞ مِّنَ ٱللَّهۡوِ وَمِنَ ٱلتِّجَٰرَةِۚ وَٱللَّهُ خَيۡرُ ٱلرَّٰزِقِينَ 11
Ti apakan awọn olugbafa ba fi oju kan owo tabi ere, wọn yoo jade ni ẹniti o fan ka ni ẹniti o jade sibẹ, wọn yoo si pa ọ ti - irẹ ojisẹ - ni ẹniti o duro lori pepele, sọ wipe: - irẹ ojisẹ - : ẹsan ti o wa lọdọ Allah lori isẹ rere loore ju owo sise ati ere eyiti ẹ jade si lọ, Allah si jẹ ẹniti o loore ju ni oluse arisiki.
سورة (MADANIYYAH)
Sisale paapa awọn sọbẹ selu ati sise ikilọ kuro lọdọ wọn.
إِذَا جَآءَكَ ٱلۡمُنَٰفِقُونَ قَالُواْ نَشۡهَدُ إِنَّكَ لَرَسُولُ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ إِنَّكَ لَرَسُولُهُۥ وَٱللَّهُ يَشۡهَدُ إِنَّ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ لَكَٰذِبُونَ 1
Ti awọn sọbẹ selu ba wa si ijoko rẹ - irẹ ojisẹ - awọn ti wọn nse afihan ẹsin Islam ti wọn si fi keferi pamọ, wọn yoo sọpe: a jẹri wipe dajudaju ojisẹ Allah lododo ni ọ, Allah si mọ wipe dajudaju ojisẹ Rẹ lododo ni ọ, Allah si jẹri wipe awọn sọbẹ sele jẹ opurọ nibi ohun ti wọn npe apemọra rẹ wipe awọn jẹri ninu isalẹ salẹ ọkan wọn wipe dajudaju ojisẹ Rẹ ni ọ.
ٱتَّخَذُوٓاْ أَيۡمَٰنَهُمۡ جُنَّةٗ فَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِۚ إِنَّهُمۡ سَآءَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 2
Wọn se ibura wọn eyiti wọn bura lori apemọra igbagbọ ni gaga ati idaabobo fun wọn kuro nibi pipa ati imulẹru, wọn si mu awọn eniyan kuro nibi igbagbọ si ohun ti wọn fan ka ninu iyemeji ati idẹruba, dajudaju ohun ti wọn nse ninu sọbẹ selu ati ibura irọ jẹ ohun ti o buru.
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ ءَامَنُواْ ثُمَّ كَفَرُواْ فَطُبِعَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ فَهُمۡ لَا يَفۡقَهُونَ 3
Eleyi ribẹ nitoripe wọn nigbagbọ niti sọbẹ selu, igbagbọ ko si wọ inu ọkan wọn, lẹyin naa wọn se aimoore si Allah ni kọkọ, wọn si fi edidi di ọkan wọn nitori keferi wọn ti igbagbọ ko nii wọ ibẹ nitori edidi yii, wọn ko le gbọ agbọye ohun ti anfaani nbẹ nibẹ fun wọn ati itọsọna.
۞وَإِذَا رَأَيۡتَهُمۡ تُعۡجِبُكَ أَجۡسَامُهُمۡۖ وَإِن يَقُولُواْ تَسۡمَعۡ لِقَوۡلِهِمۡۖ كَأَنَّهُمۡ خُشُبٞ مُّسَنَّدَةٞۖ يَحۡسَبُونَ كُلَّ صَيۡحَةٍ عَلَيۡهِمۡۚ هُمُ ٱلۡعَدُوُّ فَٱحۡذَرۡهُمۡۚ قَٰتَلَهُمُ ٱللَّهُۖ أَنَّىٰ يُؤۡفَكُونَ 4
Ti o ba si ri wọn - irẹ oluworan - irisi wọn ati aworan wọn yoo jọ ọ loju; nitori titutu gbọdọ ati idẹkun ti wọn wa nibẹ, ti wọn ba sọrọ, iwọ yoo tẹti gbọ ọrọ wọn nitori asọyanju ti wọn ni, nibi ijoko wọn wọn da gẹgẹ bi ire ojise igi ti a fi ti, wọn ko le gbọ nkankan ye, ko si le ran an lọwọ, wọn nlero pe gbogbo ohun ti yoo mu awọn sin nitori ojo ti o wa pẹlu wọn, awọn ni ọta tootọ, sọra fun wọn - irẹ ojisẹ - ki wọn ma ba fan kọkọ ka fun ọ tabi da ete fun ọ niti dida ete, Allah ti sẹbi le wọn, bawo ni wọn se nmu igbagbọ kuro pẹlu ihandfe awọn itọka rẹ ati ihande awọn awijare rẹ?!
Jijẹ dandan pipọ sẹsẹ lọsi ibi akojọ lẹyin ipepe ati jijẹ eewọ ohun ti o yatọ si i ni ile aye ayaafi pẹlu awijare.
Sisẹsa ọgba ọrọ fun awọn sọbẹ selu jẹ ohun ti itaniji wa nibẹ lori ewu wọn ati pipamọ alamọri wọn.
Iwoye jẹ ibamun si atunse ibajẹ kii se ẹwa ti o han, bẹẹni kii se didara agbekalẹ.