سورة (MADANIYYAH)
Sise alaye idẹkun Allah lori awọn ijọ yii ati ọla ti o wa fun lati ara ojisẹ ijọ naa, ati alaye ọla ti o wa fun ọjọ jum'ah.
يُسَبِّحُ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ ٱلۡمَلِكِ ٱلۡقُدُّوسِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ 1
Gbogbo ohun ti nbẹ ni gbogbo sanmọ ati gbogbo ohun ti nbẹ nilẹ ninu awọn ẹda nse afọmọ fun Allah kuro nibi gbogbo ti ko lẹtọ si I ninu awọn iroyin ẹdinku, o nfọ Ọ mọ, Oun ni ọlọla kan soso ti o ni ọla ẹni mimọ kuro nibi ẹdinku, alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati ofin Rẹ ati ebubu Rẹ.
هُوَ ٱلَّذِي بَعَثَ فِي ٱلۡأُمِّيِّۧنَ رَسُولٗا مِّنۡهُمۡ يَتۡلُواْ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِهِۦ وَيُزَكِّيهِمۡ وَيُعَلِّمُهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَإِن كَانُواْ مِن قَبۡلُ لَفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ 2
Oun ni ẹniti ransẹ ojisẹ kan si iran larubawa ti ko le kọ, ti ko le ka ninu iran wọn, o nka awọn aayah rẹ eyiti wọn sọkalẹ fun un le wọn lori, o si nfọ wọn kuro nibi keferi ati awọn iwa ti ko dara, o si nfi Alukuraani mọ wọn, o si tun nfi ilana rẹ mọ wọn, dajudaju wọn jẹ ẹniti o wa ni ọna anu kuro nibi ododo ti o fi oju han siwaju ki wọn to ran si wọn, nigbati wọn jẹ ẹniti o nsin awọn oosa, ti wọn si nta awọn ẹjẹ silẹ, wọn si nja okun ibi.
وَءَاخَرِينَ مِنۡهُمۡ لَمَّا يَلۡحَقُواْ بِهِمۡۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 3
Wọn tun gbe ojisẹ naa dide si awọn ijọ miran ninu awọn iran larubawa ati ẹniti o yatọ si wọn, ti wọn ko tii de, wọn yoo si pada wa, Oun ni alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati ofin Rẹ ati ipebubu Rẹ.
ذَٰلِكَ فَضۡلُ ٱللَّهِ يُؤۡتِيهِ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ ذُو ٱلۡفَضۡلِ ٱلۡعَظِيمِ 4
Eyiti a sọ yii - nipa gbigbe ojisẹ naa dide si iran larubawa ati ẹniti o yatọ si wọn - ọla Allah ti O ma nfun ẹniti o ba wu U ni, Allah si jẹ onidaadaa ti o tobi, ninu daadaa Rẹ ti o tobi ni riran ojisẹ ijọ yii si awọn eniyan ni apapọ.
Nigbati Allah sọ idẹkun ti o se nipa gbigbe ojisẹ naa dide ati sisọ Alukuraani kalẹ, o si tun sọ ohun ti apakan awọn olutẹle Musa ti ọla nbẹ fun wa lori rẹ nipa gigunri si isẹ ti o wa ninu taoreeta; ni sise ikilọ fun ijọ yii lori awọn olutẹle wọn, O wa sọpe:
مَثَلُ ٱلَّذِينَ حُمِّلُواْ ٱلتَّوۡرَىٰةَ ثُمَّ لَمۡ يَحۡمِلُوهَا كَمَثَلِ ٱلۡحِمَارِ يَحۡمِلُ أَسۡفَارَۢاۚ بِئۡسَ مَثَلُ ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِۚ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ 5
Apejuwe awọn yahuudi ti wọn la didide si ohun ti o nbẹ ninu taoreeta bọ lọrun, wọn si gbe ohun ti wọn la bọ wọn lọrun ju silẹ da gẹgẹ bi apejuwe kẹtẹkẹtẹ ti o gbe awọn tira ti o pọ, ti ko mọ ohun ti wọn gbe ru u: se awọn iwe ni tabi awọn nkan miran? Apejuwe awọn ijọ ti o pe awọn amin Allah nirọ ma buru, Allah ko si nii fi awọn ijọ alabosi se kongẹ deedee ododo.
قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ هَادُوٓاْ إِن زَعَمۡتُمۡ أَنَّكُمۡ أَوۡلِيَآءُ لِلَّهِ مِن دُونِ ٱلنَّاسِ فَتَمَنَّوُاْ ٱلۡمَوۡتَ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 6
Sọ wipe - irẹ ojisẹ -: mo pe ẹyin ti ẹ sẹku lori ilana yahuudi lẹyin ẹdinku rẹ, ti ẹ ba lero wipe ẹyin ni aayo Allah, ti o fi jijẹ aayo sa yin lẹsa yatọ si awọn eniyan, ki ẹ yaa rankan iku: ki o le kanju se ẹohun ti O sa yin lẹsa fun yin - ni ibamun si ero yin - gẹgẹ bi apọnle ti ẹ ba jẹ olododo nibi ohun ti ẹ npe apemọra rẹ wipe ẹyin ni aayo Allah yatọ si awọn eniyan.
وَلَا يَتَمَنَّوۡنَهُۥٓ أَبَدَۢا بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلظَّٰلِمِينَ 7
Wọn ko nii rankan iku lailai bikosepe wọn yoo maa rankan gbere ni ile aye nitori okunfa ohun ti wọn se ni keferi ati awọn ẹsẹ ati abosi ati yiyi taoreeta pada ati pipaarọ rẹ, Allah jẹ onimimọ awọn alabosi, nkankan ko pamọ fun Un ninu awọn isẹ wọn, yoo si san wọn lẹsan le lori.
قُلۡ إِنَّ ٱلۡمَوۡتَ ٱلَّذِي تَفِرُّونَ مِنۡهُ فَإِنَّهُۥ مُلَٰقِيكُمۡۖ ثُمَّ تُرَدُّونَ إِلَىٰ عَٰلِمِ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 8
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn yahuudi wọnyi: dajudaju iku ti ẹ nsaa fun yoo pade yin ti ko si ibuyẹ nibẹ boya kiakia tabi ni igba pipẹ, lẹyin naa ẹ o sẹri lọ si ọdọ Allah Onimimọ ohun ti o pamọ ati ohun ti o peju ni ọjọ igbende, nkankan ko pamọ fun Un ninu mejeeji, yoo si fun yin niro nkan ti ẹ nse ni ile aye, yoo si san yin lẹsan le lori.
Titobi idẹkun anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun lori abara lapapọ ati lori iran larubawa ni adayanri nigbati wọn wa ni aimọkan ati irare.
ọnaamọ jẹ ọla lati ọdọ Allah nikan soso ti wọn ma ngbero ninu rẹ, wọn si ma nwa pẹlu itẹle tiRẹ.
Pipe apemọra yahuudi nirọ wipe awọn ni awọn aayo Allah; pẹlu pipe wọn nija lati rankan iku, ti wọn ba jẹ olododo nibi apemọra wọn nitoripe dajudaju aayo yoo maa jẹ ran ẹniti o nifẹ si.