يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ إِذَا جَآءَكَ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتُ يُبَايِعۡنَكَ عَلَىٰٓ أَن لَّا يُشۡرِكۡنَ بِٱللَّهِ شَيۡٔٗا وَلَا يَسۡرِقۡنَ وَلَا يَزۡنِينَ وَلَا يَقۡتُلۡنَ أَوۡلَٰدَهُنَّ وَلَا يَأۡتِينَ بِبُهۡتَٰنٖ يَفۡتَرِينَهُۥ بَيۡنَ أَيۡدِيهِنَّ وَأَرۡجُلِهِنَّ وَلَا يَعۡصِينَكَ فِي مَعۡرُوفٖ فَبَايِعۡهُنَّ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لَهُنَّ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 12
Mo pe irẹ anọbi, nigbati awọn obinrin olugbagbọ ododo ba waa ba ọ, ti wọn nse majẹmu pẹlu rẹ - iru ohun ti o sẹlẹ nibi isipaya mẹkkah - lori wipe wọn ko gbọdọ sẹbọ pẹlu Allah kankan, bikosepe wọn yoo maa jọsin fun Un lohun nikan, wọn ko si gbọdọ jale, wọn ko si gbọdọ se agbere, wọn ko si gbọdọ pa awọn ọmọ wọn niti titẹle isesi awọn alaimọkan, wọn ko si gbọdọ gbe awọn ọmọ wọn ti wọn bi lati ibi sina fun awọn ọkọ wọn, wọn ko si gbọdọ yapa rẹ nibi daadaa gẹgẹ bi kikọ kuro nibi ẹkun aro tabi fifarun (nitori ibanujẹ) ati yiya ọrun asọ -: ki o ya ba wọn se majẹmu, ki o si wa aforijin ni ọdọ Allah fun ẹsẹ wọn lẹyin igbati wọn ba ba ọ se majẹmu tan, dajudaju Allah jẹ oluforijin ẹniti o ba sẹri ninu awọn ẹru Rẹ, onikẹ si wọn.
Nigbati ọgba ọrọ naa bẹrẹ pẹlu sise ikilọ kuro nibi ifọkanjin fun awọn ọta Allah, o wa pari pẹlu sise ikilọ kuro nibẹ niti kikanpa mọ eyiti o ti re kọja, Oun ti o ga waa sọpe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَوَلَّوۡاْ قَوۡمًا غَضِبَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡ قَدۡ يَئِسُواْ مِنَ ٱلۡأٓخِرَةِ كَمَا يَئِسَ ٱلۡكُفَّارُ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡقُبُورِ 13
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si se ohun ti wọn se lofin fun wọn, ẹ mase fi ẹmin jin fun awọn ijọ kan ti Allah binu si, wọn ko ni amọdaju nipa ọjọ ikẹyin, bikose wọn jẹ ẹniti o jakan kuro nibẹ gẹgẹ bi ijakan wọn kuro nibi sisẹri pada awọn oku wọn si ọdọ wọn, nitori sise keferi wọn si ajinde.
سورة (MADANIYYAH)
Gbigbẹ awọn olugbagbọ ododo loungbẹ sise aranse fun ẹsin Allah.
سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 1
Ohun ti o wa ni gbogbo sanmọ ati ohun ti o nbẹ ni ilẹ nfọ Allah mọ ti mimọ nbẹ fun, ti O si ga ju, O si mọ kanga kuro nibi gbogbo ohun ti ko lẹtọ si I, Oun ni alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati ipebubu Rẹ ati isofin Rẹ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لِمَ تَقُولُونَ مَا لَا تَفۡعَلُونَ 2
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, kilode ti ẹ nsọ wipe: a se nkankan, ti a ko si se niti tootọ?! Gẹgẹ bi gbolohun ẹnikan ninu yin: mo fi ida mi yii jagun, mo si fi lu sugbọn ko jagun pẹlu ida rẹ, bẹẹni ko si fi lu.
كَبُرَ مَقۡتًا عِندَ ٱللَّهِ أَن تَقُولُواْ مَا لَا تَفۡعَلُونَ 3
Nkan ikorira yii tobi ni ọdọ Allah, ohun si ni ki ẹ sọ ohu ti ẹ ko se, ko tọ fun olugbagbọ ododo ju ki o jẹ olododo pẹlu Allah lọ, ti isẹ rẹ yoo maa pe ọrọ rẹ lododo.
إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلَّذِينَ يُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِهِۦ صَفّٗا كَأَنَّهُم بُنۡيَٰنٞ مَّرۡصُوصٞ 4
Dajudaju Allah nifẹ si awọn olugbagbọ ododo, awọn ti wọn njagun si oju ọna tiRẹ nitori wiwa iyọnu Rẹ niti tito lọwọọwọ apakan wọn nibi apakan, wọn wa da gẹgẹ bi ogiri ti apakan rẹ lẹ mọ apakan.
Nigbati Allah sọ ijagun, ti O si yin awọn olugbagbọ ododo ti wọn duro lọwọọwọ nibi jijagun ni oju ọna Rẹ, O wa sọ ohun ti awọn ọmọlẹyin Musa ati Isa wa lori rẹ nipa yiyapa ojisẹ awọn mejeeji niti sise ikilọ fun awọn olugbagbọ kuro nibi yiyapa anọbi wọn, O wa sọpe:
وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِۦ يَٰقَوۡمِ لِمَ تُؤۡذُونَنِي وَقَد تَّعۡلَمُونَ أَنِّي رَسُولُ ٱللَّهِ إِلَيۡكُمۡۖ فَلَمَّا زَاغُوٓاْ أَزَاغَ ٱللَّهُ قُلُوبَهُمۡۚ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡفَٰسِقِينَ 5
Tun ranti - irẹ ojisẹ - nigbati Musa sọ fun ijọ rẹ: irẹ ijọ mi, kilode ti ẹ nfi suta se mi pẹlu ki ẹ maa yapa asẹ mi, ti ẹyin si mọ wipe dajudaju ojisẹ Allah si yin ni mo jẹ?! Nigbati wọn lọ, ti wọn si yẹ kuro nibi ohun ti wọn mu wa ba wọn lododo, Allah wa mu ọkan wọn kuro nibi ododo ati iduro sinsin, Allah kii fi ijọ ti o ba jade kuro itẹle asẹ Rẹ se kongẹ ododo.
Sise lofin dida majẹmu fun ẹniti asẹ kan lori mogbọ ati mogba ati ipaya.
Jijẹ ọranyan sisọ ododo nibi awọn isẹ ati biba awọn gbolohun mu.
Alllah salaye ọna rere ati aburu fun ẹru nigbati ẹru ba wa yan yiyẹ kuro ati anu laayo ti ko si sẹri, dajudaju Allah yoo fi lilekun ni yiyẹ rẹ ati anu rẹ se ijiya fun un.