سورة (MADANIYYAH)
Sise afihan imọ Allah eyiti o kari ati idogongo rẹ ti o dopin niti ikọnilẹkọ fun akiyesi rẹ ati isekilọ kuro nibi yiyapa rẹ.
قَدۡ سَمِعَ ٱللَّهُ قَوۡلَ ٱلَّتِي تُجَٰدِلُكَ فِي زَوۡجِهَا وَتَشۡتَكِيٓ إِلَى ٱللَّهِ وَٱللَّهُ يَسۡمَعُ تَحَاوُرَكُمَآۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعُۢ بَصِيرٌ 1
Paapaa Allah ti gbọ ọrọ obinrin naa (oun si ni khaolah ọmọ thaalabah) eyiti o nran ọ leti - irẹ ojisẹ - nipa ọrọ ọkọ rẹ (oun si ni Aosi ọmọ Sọọmiti) nigbati o fi ẹyin iyawo rẹ we ẹyin iya rẹ, o si ke gbajari lọ si ọdọ Allah fun ohun ti ọkọ rẹ se fun, bẹẹni Allah gbọ irannileti ẹyin mejeeji ninu ọrọ, nkankan ko pamọ fun Un ninu rẹ, dajudaju Allah jẹ Olugbọ ọrọ awọn ẹru Rẹ, Oluri awọn isẹ wọn, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ.
ٱلَّذِينَ يُظَٰهِرُونَ مِنكُم مِّن نِّسَآئِهِم مَّا هُنَّ أُمَّهَٰتِهِمۡۖ إِنۡ أُمَّهَٰتُهُمۡ إِلَّا ٱلَّٰٓـِٔي وَلَدۡنَهُمۡۚ وَإِنَّهُمۡ لَيَقُولُونَ مُنكَرٗا مِّنَ ٱلۡقَوۡلِ وَزُورٗاۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَعَفُوٌّ غَفُورٞ 2
Awọn ti wọn nfi ẹyin iyawo wọn we ẹyin iya wọn; pẹlu ki ẹnikan ninu wọn sọ fun iyawo rẹ pe: iwọ lọdọ mi da gẹgẹ bi ẹyin mama mi, wọn pa irọ nibi gbolpohun wọn yii, awọn iyawo wọn kii se awọn mama wọn, bikosepe awọn mama wọn ni ẹniti o bi wọn, dajudaju nibi ọrọ ti wọn sọ yii, wọn nsọ gbolohun ti o buru gidigidi, ti o si jẹ irọ, atipe dajudaju Allah jẹ alamojukuro oluforijinni, paapaa O si ti se itanran lofin fun wọn; ki O le mu wọn bọ kuro nibi ẹsẹ naa.
وَٱلَّذِينَ يُظَٰهِرُونَ مِن نِّسَآئِهِمۡ ثُمَّ يَعُودُونَ لِمَا قَالُواْ فَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مِّن قَبۡلِ أَن يَتَمَآسَّاۚ ذَٰلِكُمۡ تُوعَظُونَ بِهِۦۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ 3
Awọn ti wọn nsọ gbolohun ti o buru gidi yii, lẹyin naa ti wọn wa ngbero ibalopọ lọkọ laya lọdọ ẹniti wọn fi ẹyin rẹ we ti mama wọn, o di dandan fun wọn ki wọn se itanran pẹlu bibọ okun lọrun ẹru siwaju ki wọn to le ba wọn lopọ, eleyi ti A sọ yii ni idajọ ti wọn pa wọn lasẹ rẹ, ki o le jẹ ijagbemọ fun nipa ifẹyin iyawo ẹni we ti mama ẹni, Allah si jẹ oniro ohun ti ẹ nse nisẹ, nkankan ko pamọ fun Un ninu awọn isẹ yin.
فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ شَهۡرَيۡنِ مُتَتَابِعَيۡنِ مِن قَبۡلِ أَن يَتَمَآسَّاۖ فَمَن لَّمۡ يَسۡتَطِعۡ فَإِطۡعَامُ سِتِّينَ مِسۡكِينٗاۚ ذَٰلِكَ لِتُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦۚ وَتِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِۗ وَلِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٌ أَلِيمٌ 4
Ẹniti ko ba ri ẹru ti yoo bọkun lọrun rẹ, dandan ni fun un ki o gba aawẹ osu meji ti o tẹle ara wọn siwaju ki o to ba iyawo rẹ eyiti o fi ẹyin rẹ we mama rẹ ni asepọ, ẹniti ko ba si nikapa aawẹ osu meji ti o tẹle ara wọn, o di dandan fun un ki o fun alaini ọgọta ni ounjẹ, idajọ ti a se yii yoo jẹ ki ẹ le nigbagbọ wipe dajudaju Allah ni o pasẹ rẹ, ki ẹ si le mu asẹ Rẹ sẹ, ati ki ẹ si le tẹle ojisẹ Rẹ, awọn idajọ eyiti a se lofin naa fun yin jẹ awọn ẹnu aala Allah eyiti O fi lelẹ fun awọn ẹru Rẹ, ẹ ko gbọdọ kọja ẹnu aala Rẹ, iya inira si wa fun awọn keferi lori awọn idajọ Allah ati awọn aala Rẹ ti o fi lelẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ يُحَآدُّونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ كُبِتُواْ كَمَا كُبِتَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ وَقَدۡ أَنزَلۡنَآ ءَايَٰتِۢ بَيِّنَٰتٖۚ وَلِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٞ مُّهِينٞ 5
Dajudaju awọn ti wọn nba Allah ati ojisẹ Rẹ se ọta, wọn di ẹni ilẹ, wọn si di ẹni itiju gẹgẹ bi wọn se sọ awọn ti wọn ba wọn sọta ninu awọn ijọ ti o siwaju di ẹni ilẹ, ti wọn si di ẹni ẹtẹ, paapaa a si ti sọ awọn amin ti o fi oju han kalẹ, iya iyẹpẹrẹ si wa fun awọn keferi si Allah ati si awọn ojisẹ Rẹ ati si awọn amin Rẹ.
يَوۡمَ يَبۡعَثُهُمُ ٱللَّهُ جَمِيعٗا فَيُنَبِّئُهُم بِمَا عَمِلُوٓاْۚ أَحۡصَىٰهُ ٱللَّهُ وَنَسُوهُۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٌ 6
Ọjọ ti Allah yoo gbe wọn dide ni apapọ, ti wọn ko nii fi ẹnikẹni silẹ ninu wọn, wọn yoo wa maa fun wọn niro ohun ti wọn se ni ile aye ninu awọn isẹ buruku, Allah yoo ko o jọ fun wọn, nkankan ko bọ mọ lọwọ ninu isẹ wọn, awọn ti gbagbe rẹ, wọn yoo wa ri ni akọsilẹ ninu awọn oju ewe iwe wọn eyiti kii fi kekere tabi titobi silẹ ayaafi ki o koo jọ, Allah si jẹ oluri gbogbo nkan, nkankan ko si pamọ fun Un ninu awọn isẹ wọn.
Aanu Allah pẹlu awọn ọlẹ ninu awọn ẹru Rẹ nibi jijẹpe adera wọn ati aranse wọn.
Ninu ikẹ Allah si awọn ẹru Rẹ ni sise itanran ni oniranran lori ifẹyin iyawo ẹni we iyawo ẹni ni ibamun si bi ikapa ni se ri lati mu ẹru kuro ninu idaamun.
Nibi ipari awọn aayah ti o sọ nipa fifi ẹyin iyawo ẹni we iya ẹni, o nran awọn keferi leti; ni itọka si bi wipe o wa ninu awọn isẹ wọn lẹyin naa o sun mọ ki apakan ninu isesi awọn keferi waye nibẹ.