فِيهِنَّ خَيۡرَٰتٌ حِسَانٞ 70
Awọn obinrin ti wọn mọ ni iwa, ti wọn dara ni oju wa ninu awọn ọgba idẹra naa.
فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ 71
Ewo ninu idẹkun Allah ti o pọ le yin lori -ẹyin awujọ alujannu ati eniyan- npe nirọ bi?!
حُورٞ مَّقۡصُورَٰتٞ فِي ٱلۡخِيَامِ 72
Ẹlẹyinju ẹgẹ ti a bo lasiri si inu aka, ti o jẹ idaabobo fun wọn.
فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ 73
Ewo ninu idẹkun Allah ti o pọ le yin lori - ẹyin awujọ alujannu ati eniyan - npe nirọ bi?!
لَمۡ يَطۡمِثۡهُنَّ إِنسٞ قَبۡلَهُمۡ وَلَا جَآنّٞ 74
Eniyan tabi alujannu ko sun mọ wọn siwaju awọn ọkọ wọn.
فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ 75
Ewo ninu idẹkun Allah ti o pọ le yin lori - ẹyin awujọ alujannu ati eniyan - npe nirọ bi?!
مُتَّكِِٔينَ عَلَىٰ رَفۡرَفٍ خُضۡرٖ وَعَبۡقَرِيٍّ حِسَانٖ 76
Ni ẹniti wọn nrọgbọku lori awọn irọri ti a fi awọn nkan ti o tutu gbọdọ bo ati awọn itẹ ti o dara.
فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ 77
Ewo ninu idẹkun Allah ti o pọ le yin lori - ẹyin awujọ alujannu ati eniyan - npe nirọ bi?!
تَبَٰرَكَ ٱسۡمُ رَبِّكَ ذِي ٱلۡجَلَٰلِ وَٱلۡإِكۡرَامِ 78
Orukọ Ọlọhun rẹ Ẹniti o tobi, ti O si ni daadaa, ti o si nse ọla lori awọn ẹru Rẹ pataki, O si ni oore ti o pọ.
سورة (MAKIYYAH)
Alaye isesi awọn ẹrusin ni ọjọ ibusẹrisi.
إِذَا وَقَعَتِ ٱلۡوَاقِعَةُ 1
Nigbati igbende ba to, ti ko si ibuyẹ.
لَيۡسَ لِوَقۡعَتِهَا كَاذِبَةٌ 2
O ko le ri ẹmin kankan ti yoo pe e nirọ gẹgẹ bi o se nparọ ni ile aye.
خَافِضَةٞ رَّافِعَةٌ 3
Ti yoo rẹlẹ fun awọn keferi ẹlẹsẹ pẹlu fifi wọn wọn si inu ina naa, ti yoo si ga fun awọn olugbagbọ ododo, olubẹru pẹlu fifi wọn wọ si inu ọgba idẹra naa.
إِذَا رُجَّتِ ٱلۡأَرۡضُ رَجّٗا 4
Nigbati wọn ba gbọn ilẹ niti gbigban ti o tobi.
وَبُسَّتِ ٱلۡجِبَالُ بَسّٗا 5
Ti wọn si fọ awọn oke niti fifọ.
فَكَانَتۡ هَبَآءٗ مُّنۢبَثّٗا 6
Ti awọn eeru ti o fanka, ti ko ni oripa ba hande nibi fifọ naa.
وَكُنتُمۡ أَزۡوَٰجٗا ثَلَٰثَةٗ 7
Ti ẹ wa di iran mẹta ni ọjọ yii.
فَأَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ 8
Ti awọn ẹni ọtun, ti wọn fi ọwọ ọtun wọn gba iwe wọn, bawo ni giga ati titobi ipo wọn yoo se ri naa!
وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشَۡٔمَةِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشَۡٔمَةِ 9
Ati awọn ẹni osi ti wọn yoo fi ọwọ osi wọn gba iwe wọn, bawo ni yiyẹpẹrẹ ati biburu ipo wọn yoo se ri naa!
وَٱلسَّٰبِقُونَ ٱلسَّٰبِقُونَ 10
Awọn ti o si gbawaju pẹlu sise awọn isẹ rere n ile aye, awọn naa ni ẹni igbawaju ni ọrun nibi wiwọ ọgba idẹra naa.
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلۡمُقَرَّبُونَ 11
Awọn wọnyi ni ẹni isunmọ ni ọdọ Allah.
فِي جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ 12
Wọn yoo maa gbadun oniranran idẹkun ninu awọn ọgba idẹra naa.
ثُلَّةٞ مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ 13
Awọn ijọ kan ninu awọn ijọ wọnyi ati awọn ijọ ti wọn siwaju.
وَقَلِيلٞ مِّنَ ٱلۡأٓخِرِينَ 14
Atipe diẹ ninu awọn eniyan ni igbẹyin asiko, awọn ni ẹni igbawaju alasunmọ.
عَلَىٰ سُرُرٖ مَّوۡضُونَةٖ 15
Wọn yoo wa lori awọn ibusun ti a fi wura hun.
مُّتَّكِِٔينَ عَلَيۡهَا مُتَقَٰبِلِينَ 16
Ni ẹniti wọn yoo rọgbọku lori awọn ibusun ni ẹniti wọn yoo dojukọ ara wọn, ti ẹnikan ninu wọn ko nii ri ipakọ ẹlomiran.
Lilọ gbere riranti awọn idẹkun Allah ati awọn amin Rẹ ti mimọ nbẹ fun ma nsọ gbigbe titobi Allah ati titẹle E ni daradara di dandan.
Didopin irọ pipa awọn keferi nigbati wọn ba fi oju kan ọjọ igbende.
Nini ipele awọn ipo awọn ẹni ile idẹra ni ibamun si ipele awọn isẹ wọn.