كَذَٰلِكَ مَآ أَتَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا قَالُواْ سَاحِرٌ أَوۡ مَجۡنُونٌ 52
Iru irọ yii eyiti wọn pa mọ awọn ara Mẹkkah, awọn ijọ ti o ti siwaju naa ti paru rẹ, ojisẹ kan ko waa ba wọn lati ọdọ Allah ayaafi ki wọn sọ nipa rẹ wipe: o jẹ onidan tabi were.
أَتَوَاصَوۡاْ بِهِۦۚ بَلۡ هُمۡ قَوۡمٞ طَاغُونَ 53
Se awọn ti o siwaju ninu awọn keferi ati awọn ti o kẹyin ninu wọn jọ sọ ajọsọ lori pipe awọn ojisẹ nirọ ni?! Rara, ijọka ẹnu aala wọn ni o ko wọn jọ lori eleyi.
فَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ فَمَآ أَنتَ بِمَلُومٖ 54
Ki o gunri - irẹ ojisẹ - kuro lọdọ awọn opurọ yii, iwọ kii se ẹni eebu, paapaa o ti mu de etigbọ wọn ohun ti wọn fi ran ọ si mi.
وَذَكِّرۡ فَإِنَّ ٱلذِّكۡرَىٰ تَنفَعُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 55
Gigunri rẹ kuro lọdọ wọn ko gbọdọ kọ fun lati ma se isiti fun wọn ati riran wọn leti, se isiti fun wọn ki o si ran wọn leti, dajudaju irannileti yoo se anfaani fun awọn onigbagbọ ninu Allah.
وَمَا خَلَقۡتُ ٱلۡجِنَّ وَٱلۡإِنسَ إِلَّا لِيَعۡبُدُونِ 56
Nko da alujannu ati eniyan ti kii ba se tori ijọsin fun mi lemi nikan soso, nk da wọn ki wọn le mu akẹgbẹ pẹlu Mi.
مَآ أُرِيدُ مِنۡهُم مِّن رِّزۡقٖ وَمَآ أُرِيدُ أَن يُطۡعِمُونِ 57
Nko wa arisiki lọdọ wọn, nko si wa ki wọn fun Mi lounjẹ lọdọ wọn.
إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلرَّزَّاقُ ذُو ٱلۡقُوَّةِ ٱلۡمَتِينُ 58
Dajudaju Allah ni oluse aranse fun awọn ẹru Rẹ, gbogbo eniyan ni wọn jẹ ẹniti o ni bukaata lọsi ibi arisiki Rẹ, Oun ni alagbara ti o yi, ti nkankan ko le bori rẹ, gbogbo alujannau ati eniyan jẹ ẹniti o ntẹri ba fun agbara Rẹ ti mimọ nbẹ fun.
فَإِنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُواْ ذَنُوبٗا مِّثۡلَ ذَنُوبِ أَصۡحَٰبِهِمۡ فَلَا يَسۡتَعۡجِلُونِ 59
Dajudaju ipin ninu iya nbẹ fun awọn ti o se abosi ẹmin ara wọn nibi pipe ọ nirọ - irẹ ojisẹ - iro ipin awọn ijọ wọn ti o siwaju, o si ni asiko ti o ni aala, wọn ko le beere kikanju rẹ ni ọdọ MI siwaju asiko rẹ.
فَوَيۡلٞ لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن يَوۡمِهِمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ 60
Iparun ati ofo si nbẹ fun awọn ti wọn se keferi si Allah, ti wọn si pe ojisẹ wọn nirọ ni ọjọ igbende eyiti wọn se ni adehun sisọkalẹ iya le wọn lori nibẹ.
سورة (MAKIYYAH)
Awọn awijare ati awọn ẹri lati fesi pada fun iruju awọn olupe anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun ma bẹ fun - nirọ.
وَٱلطُّورِ 1
Allah fi eyiti o ba Musa ti ọla nbẹ fun sọrọ lori rẹ bura.
وَكِتَٰبٖ مَّسۡطُورٖ 2
O si tun fi iwe eyiti wọn kọ nkan si ninu bura.
فِي رَقّٖ مَّنشُورٖ 3
Ninu awẹ iwe ti a tẹ pẹrẹsẹ gẹgẹ bi awọn iwe ti o sọkalẹ.
وَٱلۡبَيۡتِ ٱلۡمَعۡمُورِ 4
O si tun fi ile eyiti awọn malaika nrọkirika rẹ ni sanmọ fun ijọsin Allah bura.
وَٱلسَّقۡفِ ٱلۡمَرۡفُوعِ 5
O si tun fi sanmọ eyiti a gbe ga, ti o jẹ aga fun ilẹ bura.
وَٱلۡبَحۡرِ ٱلۡمَسۡجُورِ 6
O si tun fi odo ti o kun fun omin naa bura.
إِنَّ عَذَابَ رَبِّكَ لَوَٰقِعٞ 7
Dajudaju iya Ọlọhun rẹ - irẹ ojisẹ - yoo sẹlẹ ti ko si iyemeji fun awọn keferi.
مَّا لَهُۥ مِن دَافِعٖ 8
Oludi lọna kan ko si fun ti yoo kọ di wọn tabi yoo daabobo wọn kuro nibi sisẹlẹ rẹ si wọn.
يَوۡمَ تَمُورُ ٱلسَّمَآءُ مَوۡرٗا 9
Ọjọ ti sanmọ yoo parada niti piparada, yoo si gbọn niti kikede igbende.
وَتَسِيرُ ٱلۡجِبَالُ سَيۡرٗا 10
Ilẹ yoo rin ni awọn aaye rẹ niti rinrin.
فَوَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ 11
Iparun ati ofo ni ọjọ yii jẹ ti awọn olupe adehun ti Allah se fun awọn keferi ni iya nirọ.
ٱلَّذِينَ هُمۡ فِي خَوۡضٖ يَلۡعَبُونَ 12
Awọn ti wọn tẹri si inu ibajẹ, ti wọn si nsere, wọn kii bikita pẹlu ajinde ati akojọ.
يَوۡمَ يُدَعُّونَ إِلَىٰ نَارِ جَهَنَّمَ دَعًّا 13
Ọjọ ti wọn yoo ti awọn keferi ni ọpọnpọn nibi ilekoko ati ifulẹmọni lọsi inu ina jahannamọ.
هَٰذِهِ ٱلنَّارُ ٱلَّتِي كُنتُم بِهَا تُكَذِّبُونَ 14
Wọn yoo maa wa sọ fun wọn nibi eebu fun wọn: eleyi ni ina eyiti ẹ npe nirọ nigbati awọn ojisẹ yin fi nse idẹruba fun yin.
Keferi sise jẹ ọna kan soso koda ki awọn ojupọnna ti a gbe debẹ yatọ si ara wọn ati ki awọn ẹni rẹ jẹ oniranran ati aaye ati asiko rẹ.
Ẹri fun ojisẹ Rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun pẹlu mimudopin isẹ riran naa.
Ọgbọn ti o wa nibi sisẹda alujannu ati eniyan ni lati mu ijọsin Allah di ododo ni gbogbo ojupọnna rẹ.
Isesi aye yii yoo pada yi pada ni ọjọ igbende.