سورة (MAKIYYAH)
Tita awọn ọkan ji pẹlu iku ati ajinde.
قٓۚ وَٱلۡقُرۡءَانِ ٱلۡمَجِيدِ 1
(قٓۚ) (Qọọf) ọrọ ti gbawaju lori awọn iran rẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọrah. Allah fi Alukuraani alapọnle bura nitori awọn itumọ ati ọpọ rere ati ibukun ti o wa nibẹ; paapaa julọ wọn yoo gbe yin dide ni ọjọ igbende fun isiro ati ẹsan.
بَلۡ عَجِبُوٓاْ أَن جَآءَهُم مُّنذِرٞ مِّنۡهُمۡ فَقَالَ ٱلۡكَٰفِرُونَ هَٰذَا شَيۡءٌ عَجِيبٌ 2
Okunfa kikọ wọn ko jẹ rirankan wipe iwọ yoo parọ nitoripe wọn mọ ododo rẹ bikosepe wọn se eemọ wiwa ojisẹ olukilọ ninu iru iran wọn si wọn, ti kii si se iran awọn malaika, wọn sọ nitori eemọ wọn: wiwa ojisẹ ninu abara si wa jẹ eemọ!
أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗاۖ ذَٰلِكَ رَجۡعُۢ بَعِيدٞ 3
Se ẹwọn yoo gbe wa dide ti a ba ku, ti a si ti yerupẹ?! Ijidide yii ati pipada isẹmin si ara wa lẹyin igbati a ti kẹfun jẹ nkan ti ko sun mọ, ko rọrun ki o sẹlẹ.
قَدۡ عَلِمۡنَا مَا تَنقُصُ ٱلۡأَرۡضُ مِنۡهُمۡۖ وَعِندَنَا كِتَٰبٌ حَفِيظُۢ 4
A ti mọ ohun ti ilẹ njẹ ninu ra wọn lẹyin iku wọn ati titan rẹ, nkankan ko pawa laya ninu rẹ, iwe ti o sọ gbogbo ohun ti Allah pebubu le wọn lori ninu isẹmin wọn ati lẹyin iku wọn wa lọdọ wa.
بَلۡ كَذَّبُواْ بِٱلۡحَقِّ لَمَّا جَآءَهُمۡ فَهُمۡ فِيٓ أَمۡرٖ مَّرِيجٍ 5
Bikosepe awọn ẹlẹbọ yii pe Alukuraani nirọ nigbati ojisẹ naa mu wa ba wọn, wọn wa ninu ọrọ royiroyi, wọn ko duro lori nkankan nipa ọrọ wọn.
Nigbati o sọ atako awọn ẹlẹbọ si ajinde, o ran wọn lẹti awọn ẹri lori sisẹlẹ rẹ, o si sọpe:
أَفَلَمۡ يَنظُرُوٓاْ إِلَى ٱلسَّمَآءِ فَوۡقَهُمۡ كَيۡفَ بَنَيۡنَٰهَا وَزَيَّنَّٰهَا وَمَا لَهَا مِن فُرُوجٖ 6
Se awọn olupe ajinde nirọ yii ko wa ronu si sanmọ ti o wa loke wọn ni; bi a se da a, a si mọ ọ, a tun se e lọsọ pẹlu awọn irawọ ti a fi sinu rẹ, ko si sisan kankan ti o le ko alaeebu ba a?! ẹniti o da sanmọ yii, jiji awọn oku dide ni alaaye ko le ko agara ba A.
وَٱلۡأَرۡضَ مَدَدۡنَٰهَا وَأَلۡقَيۡنَا فِيهَا رَوَٰسِيَ وَأَنۢبَتۡنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوۡجِۢ بَهِيجٖ 7
A tẹ ilẹ naa ki o le rọrun fun awọn olugbe le lori, a si fi awọn oke rinlẹ nibẹ ki o ma ba mi, a si mu awọn oniranran irugbin jade nibẹ ati igi ti o dun ri.
تَبۡصِرَةٗ وَذِكۡرَىٰ لِكُلِّ عَبۡدٖ مُّنِيبٖ 8
A da gbogbo eleyi ki o le jẹ ariwoye ati iranti fun gbogbo ẹru ti o nsẹri lọ si ọdọ Ọlọhun rẹ pẹlu itẹle.
وَنَزَّلۡنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ مُّبَٰرَكٗا فَأَنۢبَتۡنَا بِهِۦ جَنَّٰتٖ وَحَبَّ ٱلۡحَصِيدِ 9
A si sọ omin ti o pọ ni anfaani ati rere kalẹ ni sanmọ, a si nfi omin naa mu irugbin jade ninu awọn oko, a si nmu ohun ti ẹ nkere rẹ jade gẹgẹ bi horo sẹhiri ati ohun ti yatọ si i.
وَٱلنَّخۡلَ بَاسِقَٰتٖ لَّهَا طَلۡعٞ نَّضِيدٞ 10
A mu ọpẹ hu ni ohun ti o gun, ti o si ga, o ni ọgọmọ ti o gun ara wọn, ti apakan rẹ wa lori apakan.
رِّزۡقٗا لِّلۡعِبَادِۖ وَأَحۡيَيۡنَا بِهِۦ بَلۡدَةٗ مَّيۡتٗاۚ كَذَٰلِكَ ٱلۡخُرُوجُ 11
A mu irugbin ti a mun jade yii ki o le jẹ arisiki fun awọn ẹru ti wọn yoo maa jẹ nibẹ, a si mu ilẹ ti ko ni irugbin ji lati ara rẹ gẹgẹ bi a se nfi ojo yii ta ilẹ ti ko ni irugbin ji, ibẹ ni a ti nji awọn oku, ti wọn yoo si maa jade, ti wọn yoo jade ni alaaye.
كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٖ وَأَصۡحَٰبُ ٱلرَّسِّ وَثَمُودُ 12
Siwaju awọn ti o pe ọ nirọ yii, - irẹ ojisẹ - awọn ijọ kan ti pe awọn anọbi wọn nirọ, ijọ Nuha parọ ati awọn ẹni kanga, ijọ samuudu naa si parọ.
وَعَادٞ وَفِرۡعَوۡنُ وَإِخۡوَٰنُ لُوطٖ 13
Ijọ 'Aadi parọ ati fir'aona ati ijọ Luuth.
وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡأَيۡكَةِ وَقَوۡمُ تُبَّعٖۚ كُلّٞ كَذَّبَ ٱلرُّسُلَ فَحَقَّ وَعِيدِ 14
Ijọ Shuaeb naa pe awọn ẹni aekat nirọ ati ijọ Tubay tii se ọba yamani, gbogbo awọn ijọ wọn yi ni wọn pe awọn ojise Allah ti O ran siwọn ni irọ, ohun ti Allah se ni adehun iya fun wọn rinnlẹ le wọn lori.
أَفَعَيِينَا بِٱلۡخَلۡقِ ٱلۡأَوَّلِۚ بَلۡ هُمۡ فِي لَبۡسٖ مِّنۡ خَلۡقٖ جَدِيدٖ 15
Se a kagara lati sẹda yin ni igba akọkọ ti a o fi wa kagara nipa jiji yin dide?! Bikosepe wọn wa ninu idaamun nipa isẹda tuntun lẹyin isẹda wọn alakọkọ.
Awọn ẹlẹbọ ngbe titobi ijẹ anọbi lori abara, wọn si wa nfi iroyin ijẹ Ọlọhun ta okuta lọrẹ!
Sise ẹda gbogbo sanmọ ati sisẹda ile ati sisọ ojo kalẹ ati mimu ilẹ ti o ti sa hu ati isẹda alakọkọ: gbogbo rẹ jẹ awọn ẹri lori ajinde.
Pipe awọn ojisẹ nirọ jẹ isesi awọn ojisẹ ti o siwaju, bẹẹni fifi iya jẹ awọn opurọ jẹ isesi Ọlọhun.