سورة (MADANIYYAH)
Tita awọn olugbagbọ ododo ji si jijagun ki o le jẹ ifunni lagbara fun wọn ati sisọ awọn keferi di ọlẹ.
ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ أَضَلَّ أَعۡمَٰلَهُمۡ 1
Awọn ti wọn se keferi si Allah, ti wọn si nmu awọn eniyan kuro nibi ẹsin Allah, Allah yoo mu ibajẹ ba isẹ wọn.
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَءَامَنُواْ بِمَا نُزِّلَ عَلَىٰ مُحَمَّدٖ وَهُوَ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّهِمۡ كَفَّرَ عَنۡهُمۡ سَئَِّاتِهِمۡ وَأَصۡلَحَ بَالَهُمۡ 2
Awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah ti wọn si nse ọpọlọpọ isẹẹre, ti wọn si nigbagbọ si ohun ti Allah sọkalẹ fun ojisẹ Rẹ Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun -ohun si ni ododo lati ọdọ Ọlọhun wọn- yoo pa awọn asise wọn rẹ, wọn ko nii gba wọn mu le lori, yoo si se atunse alamọri wọn laye ati lọrun.
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱتَّبَعُواْ ٱلۡبَٰطِلَ وَأَنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّبَعُواْ ٱلۡحَقَّ مِن رَّبِّهِمۡۚ كَذَٰلِكَ يَضۡرِبُ ٱللَّهُ لِلنَّاسِ أَمۡثَٰلَهُمۡ 3
Ẹsan ti a sọ yii fun ijọ meji jẹ nitori wipe awọn ti wọn se keferi si Allah ti wọn si tẹle ibajẹ ati wipe dajudaju awọn ti wọn nigbagbọ ninu llah ati ojisẹ Rẹ tẹle ododo ni ọdọ Ọlọhun Ọba wọn, ẹsan awọn mejeeji yatọ si ara wọn nitori yiyapa igbesẹ awọn mejeeji, gẹgẹ bi Allah se salaye ọgbọn Rẹ ni ipin mejeeji: ipin awọn olugbagbọ ati ipin awọn keferi, Allah nfi apejuwe wọn lelẹ fun awọn eniyan, ki oluwoye yaa papọ mọ oluwoye miran.
فَإِذَا لَقِيتُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَضَرۡبَ ٱلرِّقَابِ حَتَّىٰٓ إِذَآ أَثۡخَنتُمُوهُمۡ فَشُدُّواْ ٱلۡوَثَاقَ فَإِمَّا مَنَّۢا بَعۡدُ وَإِمَّا فِدَآءً حَتَّىٰ تَضَعَ ٱلۡحَرۡبُ أَوۡزَارَهَاۚ ذَٰلِكَۖ وَلَوۡ يَشَآءُ ٱللَّهُ لَٱنتَصَرَ مِنۡهُمۡ وَلَٰكِن لِّيَبۡلُوَاْ بَعۡضَكُم بِبَعۡضٖۗ وَٱلَّذِينَ قُتِلُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ فَلَن يُضِلَّ أَعۡمَٰلَهُمۡ 4
Ti ẹ ba pade - ẹyin olugbagbọ ododo - awọn olubajagun ninu awọn ti o se keferi, ki ẹ fi ida yin ge ọrun wọn, ki ẹ si tẹsiwa nibi biba wọn ja titi ẹ o fi pa pupọ ninu wọn, ti ẹ o fi wu iwalẹ ẹsẹ wọn tiditidi, ti ẹ ba pa pupọ ninu wọn, ẹ so okun awọn ẹbi ki o le dan in dan in, ti ẹ ba mu wọn lẹru, ti yin ni ẹsa ni ibamun si ohun ti yoo mu anfaani wa; laarin ki ẹ sọla le wọn lori pẹlu titu okun wọn silẹ laini si ijiirọ tabi ki ẹ paarọ wọn pẹlu dukia tabi ohun ti o yatọ si i, ki ẹ tẹsiwaju nibi pipa wọn ati mimu wọn lẹru titi ogun yoo fi pari sibi gbigbafa awọn keferi tabi jijọse adehun pẹlu wọn, eyiti a sọ yii ninu adanwo fun awọn olugbagbọ ododo pẹlu awọn keferi ati pipaarọ awọn ọjọ ati riri aranse apakan lori apakan jẹ idajọ Allah, ti Allah ba fẹ riri aranse lati ọdọ awọn keferi laini si ogun, ki ba se aranse fun wọn sugbọn O se igbiyanju ni ofin ki O le fi apakan yin dan apakan wo, yoo dan ẹniti o njagun ninu awọn olugbagbọ ododo wo ati ẹniti ko le jagun, O si nfi olugbagbọ ododo dan keferi wo, bẹẹni ti wọn ba pa olugbagbọ ododo yoo wọ ọgba idẹra, ti olugbagbọ ododo ba si pa a, oo wọ ina, awọn ti wọn ba pa si oju ọna Allah, Allah ko le mu ibajẹ bna isẹ wọn.
سَيَهۡدِيهِمۡ وَيُصۡلِحُ بَالَهُمۡ 5
Yoo fi wọn se kongẹ lati tẹle ododo ni isẹmin aye wọn, yoo si tun isesi wọn se.
وَيُدۡخِلُهُمُ ٱلۡجَنَّةَ عَرَّفَهَا لَهُمۡ 6
Yoo fi wọn wọ si inu ọgba idẹra ni ọjọ igbende, o ti salaye iroyin rẹ ni ile aye fun wọn, wọn si ti mọ ọ, O si fi awọn aaye wọn nibẹ mọ wọn ni ọrun.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِن تَنصُرُواْ ٱللَّهَ يَنصُرۡكُمۡ وَيُثَبِّتۡ أَقۡدَامَكُمۡ 7
Ẹyin ti ẹ jẹ olugbagbọ ninu Allah, ti wọn si se ohun ti A se lofin fun wọn, ti ẹ ba se iranlọwọ fun Allah pẹlu sise aranse fun anọbi Rẹ ati ẹsin rẹ ati pipa awọn keferi, yoo ta yin lọrẹ aranse bibori wọn, yoo si fi awọn ẹsẹ yin rinlẹ ni oju ogun ti nigbati ẹ ba pade wọn.
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَتَعۡسٗا لَّهُمۡ وَأَضَلَّ أَعۡمَٰلَهُمۡ 8
Awọn ti wọn se keferi si Allah ati si ojisẹ Rẹ, ofo ati iparun nbẹ fun wọn, Allah yoo si mu ibajẹ ba ẹsan awọn isẹ wọn.
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَرِهُواْ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فَأَحۡبَطَ أَعۡمَٰلَهُمۡ 9
Iya ti o sẹlẹ si wọn yii jẹ nitori ikorira wọn si ohun allah sọkalẹ fun ojisẹ Rẹ ninu Alukuraani nitori mimu Allah lọkan ti o wa nibẹ, Allah wa mu ibajẹ ba awọn isẹ wọn, wọn si sofo laye ati lọrun.
۞أَفَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۖ دَمَّرَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡۖ وَلِلۡكَٰفِرِينَ أَمۡثَٰلُهَا 10
Se awọn opurọ yii ko rin lorilẹ ni, ki wọn le ronu si bi igbẹyin awọn ti wọn parọ siwaju wọn se ri, paapaa igbẹyin naa jẹ igbẹyin inira, Allah mu iparun ba awọn ibugbe wọn, O mu iparun ba wọn, O si mu iparun awọn ọmọ wọn ati awọn dukia wọn ni gbogbo igba ati aaye ni apejuwe iru awọn iya naa nbẹ fun awọn keferi.
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ مَوۡلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَأَنَّ ٱلۡكَٰفِرِينَ لَا مَوۡلَىٰ لَهُمۡ 11
Ẹsan ti a sọ fun awọn ipin meji yii: jẹ nitoripe Allah jẹ alaranse fun awọn ti wọn nigbagbọ si I, ati wipe dajudaju ko si alaranse fun awọn keferi.
Ijiya lara ọta pẹlu ipani jẹ ọna igbẹsan lati tẹ ẹ lori ba.
Sise idẹkun ati ifidi ati ipani ati imunilẹru jẹ awọn ẹsa ninu ẹsin alaafia nibi ibasepọ pẹlu awọn ẹru keferi, ti wọn yoo mu ninu eyiti yoo sọ anfaani di ododo.
Titobi ọla ipakoda si oju ọna Allah.
Aranse Allah fun awọn olugbagbọ ododo ni majẹmu sise aranse wọn fun ẹsin Rẹ ninu.