وَبَدَا لَهُمۡ سَئَِّاتُ مَا عَمِلُواْ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ 33
Aburu ohun ti wọn se ni isẹ ni ile aye ninu keferi ati awọn ẹsẹ yoo han si wọn, iya ti wọn si nfi se yẹyẹ nigbati wọn se ikilọ fun wọn kuro nibẹ yoo sọ kalẹ fun wọn.
وَقِيلَ ٱلۡيَوۡمَ نَنسَىٰكُمۡ كَمَا نَسِيتُمۡ لِقَآءَ يَوۡمِكُمۡ هَٰذَا وَمَأۡوَىٰكُمُ ٱلنَّارُ وَمَا لَكُم مِّن نَّٰصِرِينَ 34
Allah yoo wa sọ fun wọn pe, a o fi yin silẹ ni oni ninu ina gẹgẹ bi ẹyin naa se gbagbe ipade ọjọ yin yii, wọn ko mura silẹ fun pẹlu igbagbọ ati isẹ rere, ibusọkalẹ si yin ti ẹ o sin mi si ni ina, ko si alaranse ti yoo kọ iya Allah fun yin.
ذَٰلِكُم بِأَنَّكُمُ ٱتَّخَذۡتُمۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ هُزُوٗا وَغَرَّتۡكُمُ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَاۚ فَٱلۡيَوۡمَ لَا يُخۡرَجُونَ مِنۡهَا وَلَا هُمۡ يُسۡتَعۡتَبُونَ 35
Iya eyiti wọn fi jẹ yin yii jẹ nitoripe ẹ mu awọn aayah Allah ni yẹyẹ ti ẹ fi nse awada, isẹmin adun aye ati awọn yodoyindin rẹ si tan yin jẹ, ni oni yii awọn keferi olufi amin Allah se yẹyẹ ko nii jade ni inu ina, bikosepe wọn yoo sẹku ninu rẹ gbere, wọn ko si nii da wọn pada si isẹmin aye lati se isẹ rere, Ọlọhun Ọba wọn ko si nii yọnu si wọn.
فَلِلَّهِ ٱلۡحَمۡدُ رَبِّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَرَبِّ ٱلۡأَرۡضِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 36
Ti Allah nikan ni ọpẹ, Ọba ti O ni gbogbo sanmọ ti O si ni ilẹ, Oun naa ni Ọba ti O ni gbogbo ẹda.
وَلَهُ ٱلۡكِبۡرِيَآءُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 37
Tirẹ ni gbigbọngbọ titobi ninu gbogbo sanmọ ati ni ilẹ, Oun si ni alagbara ti ẹnikankan ko le bori rẹ, Ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati ipebubu Rẹ ati idari eto Rẹ ati ofin Rẹ.
سورة (MAKIYYAH)
Sise alaye bi ijọmọniyan se ni bukaata si isẹ ti a fi ran ojisẹ ati kikilọ fun awọn ti wọn gunri si.
حمٓ 1
(حمٓ) (Ha Mim) ọrọ ti gbawaju lori iran iru rẹ ti ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọrah
تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ 2
Isọkalẹ Alukuraani jẹ lati ọdọ Allah alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati ipebubu Rẹ ati ofin Rẹ.
مَا خَلَقۡنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَآ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَأَجَلٖ مُّسَمّٗىۚ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ عَمَّآ أُنذِرُواْ مُعۡرِضُونَ 3
A ko da gbogbo sanmọ ati ilẹ ati ohun ti o wa laarin mejeeji ni ere bikosepe a da gbogbo eleyi pẹlu ododo nitori awọn ọgbọn ti o de ogongo, ninu rẹ ni ki ẹru le mọ Ọn, ki o si le maa sin lohun nikan soso, ki o si maa mu ẹbọ kankan pẹlu Rẹ, ki wọn si le dide si ohun ti ifirole wọn lorilẹ ko sinu titi di asiko ti a fi aala si, ti Allah nikan mọ ọ, awọn ti o jẹ alaimoore si Allah jẹ ẹniti o ngunri kuro nibi ohun ti wọn fi se ikilọ fun wọn kuro nibi tira Allah, wọn ko bikita pẹlu Rẹ.
قُلۡ أَرَءَيۡتُم مَّا تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُواْ مِنَ ٱلۡأَرۡضِ أَمۡ لَهُمۡ شِرۡكٞ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِۖ ٱئۡتُونِي بِكِتَٰبٖ مِّن قَبۡلِ هَٰذَآ أَوۡ أَثَٰرَةٖ مِّنۡ عِلۡمٍ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 4
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ ti wọn gunri kuro nibi ododo naa: ẹ fun mi niro nipa awọn ẹbọ yin eyiti ẹ nsin yatọ si Allah, kinni ohun ti wọn da ninu awọn abala ilẹ? Se wọn da oke ni? Tabi wọn da odo? Tabi akẹgbẹ nbẹ fun wọn ati ipin pẹlu Allah nibi dida gbogbo sanmọ? ẹ mu wa fun mi iwe kan ti o sọkalẹ lati ọdọ Allah siwaju Alukuraani tabi asẹkubọ imọ ninu ohun ti awọn ẹni akọkọ fi silẹ, ti ẹ ba jẹ sootọ sootọ nibi ohun ti ẹ npe apemọra wipe awọn ẹbọ yin lẹtọ si ijọsin.
وَمَنۡ أَضَلُّ مِمَّن يَدۡعُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَن لَّا يَسۡتَجِيبُ لَهُۥٓ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَهُمۡ عَن دُعَآئِهِمۡ غَٰفِلُونَ 5
Ko si ẹniti o sọnu to ẹniti o nsin nkan miran yatọ si Allah ni oosa ti ko le jẹpe ipepe rẹ titi di ọjọ igbende, awọn oosa yii eyiti wọn nsin yatọ si Allah jẹ afọnu nipa adura awọn ti o njọsin fun wọn; debi wipe yoo wa se wọn ni anfaani tabi yoo ko inira ba wọn.
Fifi awọn aayah Allah se yẹyẹ jẹ keferi.
Ewo ti o nbẹ nibi gbigba itanjẹ pẹlu awọn adun aye ati yodiyindin rẹ.
Ririnlẹ iroyin moto moto fun Allah ti O ga.
Jijẹpe adura jẹ eyiti o han ju ninu ẹri bibẹ Allah ti mimọ nbẹ fun ati ilẹtọ Rẹ si ijọsin.