سورة (MAKIYYAH)
Sise alaye awọn isesi ẹda lati ara awọn amin ti o jẹ ti ofin ati ti aye, ati biba awọn ẹri awọn ti wọn lodi si igbedide jẹ, ti wọn jẹ olugberaga, ati didẹru bawọn.
حمٓ 1
(حمٓ) (Ha Mim) ọrọ ti re kọja lori awọn iran rẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọrah
تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ 2
Sisọkalẹ Alukuraani jẹ lati ọdọ Allah alagbara ti ẹnikankan ko le bori, ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati ipebubu Rẹ ati idari eto Rẹ.
إِنَّ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ لَأٓيَٰتٖ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ 3
Dajudaju nibi gbogbo sanmọ ati ilẹ jẹ awọn itọka lori agbara Allah ati ijọkan soso Rẹ fun awọn olugbagbọ ododo; nitoripe awọn ni yoo se ariwoye pẹlu awọn amin Rẹ.
وَفِي خَلۡقِكُمۡ وَمَا يَبُثُّ مِن دَآبَّةٍ ءَايَٰتٞ لِّقَوۡمٖ يُوقِنُونَ 4
Atipe nibi isẹda yin - ẹyin eniyan - jẹ lati inu omin lọgbọ, lẹyin naa lati baasi, lẹyin naa lati ẹjẹ kiki, ati nibi isẹda ohun ti Allah nfan ka lati ara ẹranko ti o rin lori ilẹ jẹ awọn itọka lori ijọkan soso Rẹ fun awọn ijọ ti o mọ amọdaju wipe dajudaju Allah ni asẹda.
وَٱخۡتِلَٰفِ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مِن رِّزۡقٖ فَأَحۡيَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَا وَتَصۡرِيفِ ٱلرِّيَٰحِ ءَايَٰتٞ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ 5
Atipe nibi pipaara oru ati ọsan ati nibi ojo ti Allah sọkalẹ ni sanmọ, ti O si fi nta ilẹ ji pẹlu mimu irugbin jade lẹyin igbati o ti di oku ti ko si irugbin nibẹ ati nibi didari awọn atẹgun pẹlu mimuwa ni abala kan ni asiko kan ati ni igba miran ni ibo miran fun anfaani yin; jẹ awọn itọka fun awọn ijọ ti wọn se laakaye, ti wọn yoo fi maa se ẹri lori ijọkan soso Allah ati agbara Rẹ lori ajinde ati agbara Rẹ lori gbogbo nkan.
تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱللَّهِ نَتۡلُوهَا عَلَيۡكَ بِٱلۡحَقِّۖ فَبِأَيِّ حَدِيثِۢ بَعۡدَ ٱللَّهِ وَءَايَٰتِهِۦ يُؤۡمِنُونَ 6
Awọn amin yii ati awọn awijare yii, a nka a fun ọ - irẹ ojisẹ - pẹlu ododo, ti wọn ko ba nigbagbọ si ọrọ Allah ti o sọkalẹ fun ẹru Rẹ ati awọn awijare Rẹ, ewo ninu ọrọ lẹyin eleyi ni wọn yoo nigbagbọ si, bẹẹni ewo ninu awọn awijare lẹyin eleyi ni wọn yoo gba lododo?!
وَيۡلٞ لِّكُلِّ أَفَّاكٍ أَثِيمٖ 7
Iya kan lati ọdọ Allah ati iparun fun gbogbo opurọ ẹlẹsẹ pupọ.
يَسۡمَعُ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ثُمَّ يُصِرُّ مُسۡتَكۡبِرٗا كَأَن لَّمۡ يَسۡمَعۡهَاۖ فَبَشِّرۡهُ بِعَذَابٍ أَلِيمٖ 8
Keferi yoo maa gbọ awọn aayah Allah ninu Alukuraani ti wọn ka a fun un, lẹyin naa yoo maa tẹsiwaju lori keferi ti o wa ati awọn ẹsẹ; ni ẹniti yoo maa se igberaga ninu ẹmin rẹ lati tẹle ododo, gẹgẹ bi ẹnipe ko gbọ awọn aayah yii eyiti wọn nka fun yii, fun niro - irẹ ojisẹ - pẹlu ohun ti yoo buru fun un ni ọrun, ohun si ni iya inira ti nreti rẹ nibẹ.
وَإِذَا عَلِمَ مِنۡ ءَايَٰتِنَا شَيًۡٔا ٱتَّخَذَهَا هُزُوًاۚ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٞ مُّهِينٞ 9
Ti nkankan ba de etigbọ rẹ ninu Alukuraani, yoo mu ni yẹyẹ ti yoo fi maa se awada, awọn wọnyi ni a fi iroyin yẹyẹ royin ni Alukuraani, iya ti o yẹpẹrẹ ni o bẹ fun wọn ni ọjọ igbende.
مِّن وَرَآئِهِمۡ جَهَنَّمُۖ وَلَا يُغۡنِي عَنۡهُم مَّا كَسَبُواْ شَيۡٔٗا وَلَا مَا ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَوۡلِيَآءَۖ وَلَهُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٌ 10
Ina jahannamọ nbẹ ni iwaju wọn, ti nreti wọn lọrun, gbogbo dukia ti wọn kojọ ko le rọ wọn lọrọ kankan ni ọdọ Allah, nkan miran ti nmu ninu oosa ti wọn nsin yatọ si Allah ko si le mu idaabobo kankan fun wọn, iya ti o tobi si nbẹ fun wọn ni ọjọ igbende.
هَٰذَا هُدٗىۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بَِٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ لَهُمۡ عَذَابٞ مِّن رِّجۡزٍ أَلِيمٌ 11
Iwe yii ti a sọkalẹ fun ojisẹ wa muhammad jẹ olutọni si ọna ododo, iya buburu ti o nira nbẹ fun awọn ti o se keferi si ayah Ọlọhun wọn ti a sọkalẹ fun ojisẹ Rẹ nbẹ fun wọn.
۞ٱللَّهُ ٱلَّذِي سَخَّرَ لَكُمُ ٱلۡبَحۡرَ لِتَجۡرِيَ ٱلۡفُلۡكُ فِيهِ بِأَمۡرِهِۦ وَلِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ 12
Allah nikan ni ẹniti o rọ odo fun yin - ẹyin eniyan - ki awọn ọkọ oju omin le maa rin nibẹ pẹlu asẹ Rẹ, ki ẹ si le ba fi maa wa awọn oniranran nkan ẹtọ ninu ọla Rẹ ati ki ẹ le ba dupẹ idẹkun Allah le wọn lori.
وَسَخَّرَ لَكُم مَّا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا مِّنۡهُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ 13
Oun ti mimọ nbẹ fun si tun rọ ohun ti nbẹ ninu gbogbo sanmọ gẹgẹ bi oorun ati osupa ati awọn irawọ fun yin ati ohun ti nbẹ ni ilẹ gẹgẹ bi awọn omin ati awọn igi ati awọn oke ati ohun ti o yatọ si i, gbogbo awọn idẹra yi ninu ọla Rẹ ati daaada Rẹ ni, dajudaju awọn ẹri lori agbara Allah ati ijọkan soso Rẹ nbẹ nibi rirọ eleyi fun yin fun awọn ijọ ti wọn nronu nipa awọn amin Rẹ, ti wọn le woye pẹlu Rẹ.
Irọ pipa ati itaku lori ẹsẹ ati igberaga ati ifi awọn ayah Allah se yẹyẹ: jẹ awọn iroyin awọn ẹni anu, paapaa allah si ti se adehun iya fun ẹniti o ba gba iroyin yii.
Awọn idẹkun Allah lori awọn ẹru Rẹ pọ, ninu rẹ ni rirọ awọn ohun ti nbẹ ni aye yii fun wọn.
Awọn idẹkun ni bukaata lọdọ ẹru si ọpẹ fun ẹniti a nsin ti o ta wọn lọrẹ rẹ.