سورة (MAKIYYAH)
Alaye pipe ofin Allah, ati pipa dandan titẹlee, ati sisọra nibi yiyapa rẹ.
حمٓ 1
(حمٓ) ﰀ عٓسٓقٓ ﰁ (Ha Mim. 1, ‘Ha sin kọf) ọrọ ti gbawaju nipa awọn iran rẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọrah.
عٓسٓقٓ 2
(حمٓ) ﰀ عٓسٓقٓ ﰁ (Ha Mim. 1, ‘Ha sin kọf) ọrọ ti gbawaju nipa awọn iran rẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọrah.
كَذَٰلِكَ يُوحِيٓ إِلَيۡكَ وَإِلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكَ ٱللَّهُ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 3
Iru imisi yii ni wọn fi ransẹ si ọ irẹ Muhammad ati si awọn ti o siwaju rẹ ninu awọn anọbi Allah, Allah alagbara nibi igbẹsan lara awọn ọta Rẹ, ọjọgbọn nibi idari Rẹ ati isẹda Rẹ.
لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡعَظِيمُ 4
Ohun ti o nbẹ ni gbogbo sanmọ ati ohun ti o nbẹ ni gbogbo ilẹ niti ẹda ati ọla ati idari jẹ ti Allah nikan soso, Oun si ni Ẹniti bibẹ Rẹ ga ati odiwọn Rẹ ati ibori Rẹ, Ẹniti O tobi nibi bibẹ Rẹ.
تَكَادُ ٱلسَّمَٰوَٰتُ يَتَفَطَّرۡنَ مِن فَوۡقِهِنَّۚ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يُسَبِّحُونَ بِحَمۡدِ رَبِّهِمۡ وَيَسۡتَغۡفِرُونَ لِمَن فِي ٱلۡأَرۡضِۗ أَلَآ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ 5
Nibi titobi Rẹ ti mimọ nbẹ fun, gbogbo sanmọ pẹlu titobi Rẹ ati giga Rẹ fẹẹ le lanu lati oke gbogbo ilẹ, bẹẹni awọn Malaaika nse afọmọ Ọlọhun wọn, wọn si ngbe titobi fun Un ni ẹniti nse ọpẹ fun Un ni itẹriba ati ipataki, wọn si nwa aforijin ni ọdọ Allah fun awọn ti wọn wa lori ilẹ, ẹ tẹti gbọ dajudaju Allah ni alaforijin awọn ẹsẹ ẹniti o ba sẹri ninu awọn ẹru Rẹ, O si jẹ onikẹ si wọn.
وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَ ٱللَّهُ حَفِيظٌ عَلَيۡهِمۡ وَمَآ أَنتَ عَلَيۡهِم بِوَكِيلٖ 6
Awọn ti wọn nmu awọn oosa yatọ si Allah, ti wọn gbarale wọn, ti wọn si nsin wọn yatọ si Allah, Allah wa ni ilugọ de wọn ti O nkọ awọn isẹ wọn silẹ, yoo si san wọn lẹsan le lori, iwọ kii se - irẹ ojisẹ - ẹniti a la sisọ awọn isẹ wọn bọ lọrun, a ko nii bi ọ leere nipa awọn isẹ wọn, ohun ti o ko jẹ ni olumudetigbọ.
وَكَذَٰلِكَ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ قُرۡءَانًا عَرَبِيّٗا لِّتُنذِرَ أُمَّ ٱلۡقُرَىٰ وَمَنۡ حَوۡلَهَا وَتُنذِرَ يَوۡمَ ٱلۡجَمۡعِ لَا رَيۡبَ فِيهِۚ فَرِيقٞ فِي ٱلۡجَنَّةِ وَفَرِيقٞ فِي ٱلسَّعِيرِ 7
Gẹgẹ bi a se ransẹ imisi si awọn anọbi ti o siwaju rẹ - irẹ ojisẹ - naa ni a ransẹ Alukuraani ni ede larubawa si ọ ki o le se ikilọ fun awọn ara Mẹkkah ati agbegbe rẹ, ninu awọn oko larubawa lẹyin naa ni awọn eniyan lapapọ, ki o si fi ọjọ ti allah yoo ko awọn ẹni akọkọ ati awọn ẹni ikẹyin jọ ni ori ilẹ kan soso fun isiro ati ẹsan dẹruba awọn eniyan ni ọjọ igbende, ko si iyemeji nibi sisẹlẹ ọjọ yii, bẹẹni awọn eniyan yoo pin si meji nibẹ: ipin kan jẹ ti ọgba idẹra awọn si ni awọn olugbagbọ ododo, ipin miran si jẹ ti ina awọn si ni awọn keferi.
وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَعَلَهُمۡ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ وَلَٰكِن يُدۡخِلُ مَن يَشَآءُ فِي رَحۡمَتِهِۦۚ وَٱلظَّٰلِمُونَ مَا لَهُم مِّن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٍ 8
Ti Allah ba fẹ ni ki ba se wọn ni ijọkan soso lori ẹsin alaafia, paapaa ki ba se wọn ni ijọ kan soso le lori, ki a si fi wọn lapapọ wọ inu ọgba idẹra, sugbọn eto ọgbọn Rẹ ti pari lati fi ẹniti o ba wu U si inu ẹsin alaafia, ki o si fi wọ si ọgba idẹra, awọn alabosi si ẹmin ara wọn lati ibi keferi sise ati awọn ẹsẹ ko si alatilẹyin ti yoo wa lẹyin wọn, ko si si oluranise ti yoo la wọn kuro nibi iya Allah.
أَمِ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَۖ فَٱللَّهُ هُوَ ٱلۡوَلِيُّ وَهُوَ يُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ 9
Bikosepe awọn ẹlẹbọ yii mu ohun ti o yatọ si Allah ni alatilẹyin ti yoo gba wọn, Allah si ni alatilẹyin ododo, oun ti o yatọ si I ko le se anfaani bẹẹni ko le mu inira wa, Oun ni O nji awọn oku pẹlu gbigbe wọn dide fin isiro ati ẹsan, nkankan ko le kagara ba mimọ Rẹ.
وَمَا ٱخۡتَلَفۡتُمۡ فِيهِ مِن شَيۡءٖ فَحُكۡمُهُۥٓ إِلَى ٱللَّهِۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبِّي عَلَيۡهِ تَوَكَّلۡتُ وَإِلَيۡهِ أُنِيبُ 10
Ohun ti ẹ nse ifanfa - ẹyin eniyan - nibẹ ninu awọn ipilẹ ẹsin yin tabi akẹtun rẹ, idajọ rẹ jẹ ti Allah, ki o sẹri nibẹ lọsi inu tira Rẹ tabi ikọse ojisẹ Rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ẹniti a nfi awọn iroyin yii royin ni Ọlọhun mi, Oun ni mo gbarale nibi gbogbo ọrọ mi patapata, ọdọ Rẹ ni maa si sẹri si pẹlu ironu piwada.
Titobi Allah han nibi gbogbo nkan.
Adura awọn Malaaika fun awọn ẹni igbagbọ lori daadaa.
Alukuraani ati ikọse anọbi jẹ ibusẹrisi meji fun awọn olugbagbọ ododo nibi ọrọ wọn lapapọ, paapaa julọ ni igba iyapa.
Sise ni adayanri lori ikilọ awọn ara ilu Mẹkkah ati agbegbe rẹ; nitoripe awọn ni a gbalero sisẹri ọrọ si nitori atako wọn si isẹriran rẹ - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun -, oun si jẹ ojisẹ fun gbogbo eniyan lapapọ gẹgẹ bi Allah ti o ga se sọ: (وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا كَآفَّةٗ لِّلنَّاسِ) (a ko ran ọ nisẹ ayaafi si apapọ awọn eniyan...)