سورة (MADANIYYAH)
Tito awujọ Musulumi ati mimo ajosepo re, ati sisọ awọn ẹtọ, ati siseni lojuoyin lori ogun jija, ati biba pipe lo sibi pipa anabi Isa je.
Wọn npe bẹẹ nitori didarukọ awọn obirin nibẹ, ati sise alaye ọpọlọpọ ninu awọn idajọ wọn.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمُ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن نَّفۡسٖ وَٰحِدَةٖ وَخَلَقَ مِنۡهَا زَوۡجَهَا وَبَثَّ مِنۡهُمَا رِجَالٗا كَثِيرٗا وَنِسَآءٗۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِي تَسَآءَلُونَ بِهِۦ وَٱلۡأَرۡحَامَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَيۡكُمۡ رَقِيبٗا 1
Ẹyin eniyan, ẹ paya Ọlọhun Ọba yin, Oun ni Ẹniti O da yin lati bi ẹmin kan soso, oun naa ni baba yin tii se Aadam, ati wipe O da lati ara Aadam iyawo rẹ Hawahu, tii se iya yin, ti o si fọn ka lati dọ awọn mejeeji si awọn aaye ori ilẹ abara ti o pọ lọkunrin ati lobirin, ati wipe ki ẹ paya Ọlọhun Ọba Allah eyiti apakan yin fi ma nbẹ apakan pẹlu wipe ki o sọ wipe: mo nfi Ọlọhun Ọba Allah bẹ ọ pe ki o se nkan bayi, ati wipe ki ẹ paya jija awọn okun ibi eyiti o so yin pọ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ ẹniti o nsọ yin, nkankan ko si lee bọ fun Un ninu awọn isẹ yin, bikose wipe Yoo rọkirika gbogbo rẹ, ati wipe Yoo san yin lẹsan le lori.
وَءَاتُواْ ٱلۡيَتَٰمَىٰٓ أَمۡوَٰلَهُمۡۖ وَلَا تَتَبَدَّلُواْ ٱلۡخَبِيثَ بِٱلطَّيِّبِۖ وَلَا تَأۡكُلُوٓاْ أَمۡوَٰلَهُمۡ إِلَىٰٓ أَمۡوَٰلِكُمۡۚ إِنَّهُۥ كَانَ حُوبٗا كَبِيرٗا 2
Ati wipe ki ẹ maa fun - ẹyin ti ẹ gbọ isiti - awọn ọmọ orukan (awọn naa ni awọn ti wọn se afẹku baba wọn, ti wọn ko si tii gbọnju) ni awọn dukia wọn perepere nigbati wọn ba balaga, ti wọn si jẹ ẹniti o gbọn, ati wipe ki ẹ mase fi eewọ paarọ ẹtọ pẹlu pe ki ẹ mu eyiti o dara, ti o ni iye lori ninu awọn dukia ọmọ orukan, ti ẹ yoo waa ti eyiti ko dara, ti ko ni asunsi ninu awọn owo yin si wọn, ni pipaarọ rẹ, ati wipe ki ẹ mase mu dukia awọn ọmọ orukan ni ohun ti ẹ o dapọ mọ dukia yin, dajudaju nkan naa jẹ ẹsẹ ti o tobi ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah.
وَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا تُقۡسِطُواْ فِي ٱلۡيَتَٰمَىٰ فَٱنكِحُواْ مَا طَابَ لَكُم مِّنَ ٱلنِّسَآءِ مَثۡنَىٰ وَثُلَٰثَ وَرُبَٰعَۖ فَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا تَعۡدِلُواْ فَوَٰحِدَةً أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡۚ ذَٰلِكَ أَدۡنَىٰٓ أَلَّا تَعُولُواْ 3
Ati wipe ti ẹ ba nbẹru pe ẹ ko nii le se deedee nigbati ẹ ba fẹ awọn ọmọ orukan ni obirin, awọn ti wọn wa ni abẹ amojuto yin, yala ni ibẹru dindin owo ori wọn ku, eyiti o jẹ dandan fun wọn, tabi biba wọn lo ni ọna aida, ki ẹ ya fi wọn silẹ, ki ẹ si lọ fẹ awọn ti o ba dara ninu awọn obirin ti wọn yatọ si wọn, ti ẹ ba fẹ, ẹ fẹ meji, tabi mẹta, tabi mẹrin, ti o ba jẹ wipe ẹ npaya pe ẹ ko nii le se deedee laarin wọn, ki ẹ ya duro lori ẹyọkan, tabi ki ẹ se igbadun pẹlu eyiti o nbẹ ni awọn ikapani yin ninu awọn ẹrubirin, nitori pe ko jẹ dandan fun wọn, iru ohun ti o jẹ dandan fun awọn iyawo ninu ẹtọ, ohun ti o waye ninu aayah naa nibi alamọri awọn ọmọ orukan, tabi diduro lori fifẹ ẹyọkan, tabi jijẹ igbadun pẹlu awọn ẹrubirin, ni o fi nsumọ ju ki ẹ ma dẹsẹ, ki ẹ si ma yẹsẹ.
وَءَاتُواْ ٱلنِّسَآءَ صَدُقَٰتِهِنَّ نِحۡلَةٗۚ فَإِن طِبۡنَ لَكُمۡ عَن شَيۡءٖ مِّنۡهُ نَفۡسٗا فَكُلُوهُ هَنِيٓٔٗا مَّرِيٓٔٗا 4
Ati wipe ki ẹ fun awọn obirin ni awọn owo oei wọn ni fifun kan ti o jẹ dandan, ti o bawa jẹ wipe awọn ẹmin wọn yọnu pẹlu nkankan ninu owo ori fun yin laijẹni nipa, ki ẹ jẹ ni ohun ti yoo maa lọ tirinrin, ti ko si ni kikọ ninu.
وَلَا تُؤۡتُواْ ٱلسُّفَهَآءَ أَمۡوَٰلَكُمُ ٱلَّتِي جَعَلَ ٱللَّهُ لَكُمۡ قِيَٰمٗا وَٱرۡزُقُوهُمۡ فِيهَا وَٱكۡسُوهُمۡ وَقُولُواْ لَهُمۡ قَوۡلٗا مَّعۡرُوفٗا 5
Ati wipe ẹ ko gbọdọ mu - ẹyin alakoso - awọn dukia fun awọn ti wọn ko le se idari daadaa, toripe awọn dukia yii Ọlọhun Ọba Allah se ni okunfa, ti awọn daadaa awọn ẹru yoo maa duro pẹlu rẹ ati awọn alamọri isẹmi wọn, ati wipe awọn wọnyi, wọn kii se ẹniti o lẹtọ lati duro ti awọn dukia ati sisọọ, ati wipe ki ẹ ma na owo le wọn lori, ki ẹ si tun maa wọ wọn l’asọ nibẹ, ati wipe ki ẹ maa sọ fun wọn gbolohun ti o dara, ki ẹ si tun maa se adehun fun wọn ni adehun ti o dara, pe ẹ o fun wọn ni owo wọn ni igbati wọn ba gbọnju, ti wọn si tun le se akoso daadaa.
وَٱبۡتَلُواْ ٱلۡيَتَٰمَىٰ حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغُواْ ٱلنِّكَاحَ فَإِنۡ ءَانَسۡتُم مِّنۡهُمۡ رُشۡدٗا فَٱدۡفَعُوٓاْ إِلَيۡهِمۡ أَمۡوَٰلَهُمۡۖ وَلَا تَأۡكُلُوهَآ إِسۡرَافٗا وَبِدَارًا أَن يَكۡبَرُواْۚ وَمَن كَانَ غَنِيّٗا فَلۡيَسۡتَعۡفِفۡۖ وَمَن كَانَ فَقِيرٗا فَلۡيَأۡكُلۡ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ فَإِذَا دَفَعۡتُمۡ إِلَيۡهِمۡ أَمۡوَٰلَهُمۡ فَأَشۡهِدُواْ عَلَيۡهِمۡۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ حَسِيبٗا 6
Ati wipe ki ẹ gbidanwo - ẹyin alakoso - awọn ọmọ orukan nigbati wọn ba de bi ọjọ ori bibalaga pẹlu ki ẹ fun wọn ni apakan ninu owo wọn, ti wọn yoo se akoso rẹ, ti wọn ba waa se sise akoso daadaa nibẹ, ati wipe gbigbọn si tun han si yin, ki ẹ ya ko gbogbo dukia wọn fun wọn ni perepere ti ko nii ni adinku, ati wipe ki ẹ ma jẹ owo wọn ni ẹniti o nkọja ẹnu aala eyiti Ọlọhun Ọba Allah se ni ẹtọ fun yin ninu awọn dukia wọn nigbati ti bukaata ba sẹlẹ, ati wipe ki ẹ mase tete jẹẹ, niti ipaya pe ki wọn gba nigbati wọn ba balaga, ati wipe ẹniti o ba nbẹ fun owo ti o le rc lọrọ, ki o ya kọ nipa mimu ninu owo ọmọ orukan, ati wipe ẹniti o ba jẹ olosi, ti ko si owo fun un, ki o ya jẹ odiwọn bukaata rẹ, ati wipe ti ẹ ba wa jọwọ awọn dukia wọn fun wọn lẹyin bibalaga ati hihan ini oye ni ọdọ wọn, ki ẹ ya se ijẹri lori ijọwọ naa, niti sisọ awọn ẹtọ ati lati kọ awọn okunfa iyapa, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah to ni Olujẹri lori nkan naa, ati Olusesiro awọn ẹru lori awọn isẹ wọn.
Ipilẹ eyiti abara nsẹri pada sibẹ jẹ ẹyọkan, ohun ti o waa pọn dandan fun ni ki wọn paya Ọlọhun Ọba wọn, Ẹyiti O da wọn, ati apakan wọn maa fẹ apakan.
Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) se isiti pẹlu sise daadaa si awọn ọlẹ ninu awọn obirin ati awọn ọmọ orukan, pẹlu wipe ki ibalopọ pẹlu wọn wa laarin deedee ati ọla.
Nini ẹtọ pipọ iyawo ti yoo fi de obirin mẹrin pẹlu majẹmu sise deedee laarin wọn ati nini agbara lori diduro pẹlu ohun ti o jẹ dandan fun wọn.
Sise ikora duro lori ọdẹ eyiti ko le se akoso daradara fun anfaani rẹ, ati sisọ owo eyiti awọn daadaa aye rẹ yoo duro pẹlu rẹ lati majẹ ki o rare.