قَالَ فَٱلۡحَقُّ وَٱلۡحَقَّ أَقُولُ 84
Allah ti o ga sọpe: ododo wa ni ọdọ Mi, bẹẹni ododo ni Mo nsọ, nko ni sọ nkan miran.
لَأَمۡلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنكَ وَمِمَّن تَبِعَكَ مِنۡهُمۡ أَجۡمَعِينَ 85
Emi yoo fi iwọ ati ẹniti o ba tẹle ọ ninu keferi rẹ ninu awọn ọmọ Adamọ lapapọ kun ina jahannamọ ni ọjọ igbende.
قُلۡ مَآ أَسَۡٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٖ وَمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُتَكَلِّفِينَ 86
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ wọnyi: nko bi yin leere ẹsan kankan lori nkan ti mo fi nto yin leti ninu isiti, nko si jẹ olulabọrun lati mu alekun wa lori ohun ti wọn pa mi lasẹ rẹ.
إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرٞ لِّلۡعَٰلَمِينَ 87
Alukuraani ko jẹ nkankan ayaafi iranileti fun ẹniti a la nkan bọ lọrun ninu eniyan ati alujannu.
وَلَتَعۡلَمُنَّ نَبَأَهُۥ بَعۡدَ حِينِۢ 88
Ẹ o si pa da mọ iro Alukuraani naa ati wipe dajudaju o jẹ sootọ sootọ lẹyin asiko ti o sun mọ nigbati ẹ ba ku.
سورة (MAKIYYAH)
Ipepe sibi ọkan soso ati afọmọ, gbigbe ẹbọ ju silẹ.
تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ 1
Sisọ Alukuraani lati ọdọ Allah abiyi eyiti ẹnikankan ko le bori rẹ, ọjọgbọn nibi isẹda RẸ ati idari eto Rẹ ati ofin Rẹ, ko si olusọ ọ kalẹ yatọ si I ti mimọ nbẹ fun.
إِنَّآ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ فَٱعۡبُدِ ٱللَّهَ مُخۡلِصٗا لَّهُ ٱلدِّينَ 2
Paapaa Awa ni a sọ ọ kalẹ - irẹ ojisẹ - Alukuraani ti o kun fun ododo, gbogbo awọn iro ibẹ jẹ ododo, awọn idajọ rẹ patapata jẹ deedee, ki o sin Allah niti mimu lohun nikan niti sise afọmọ ijọkan soso kuro nibi ẹbọ.
أَلَا لِلَّهِ ٱلدِّينُ ٱلۡخَالِصُۚ وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَ مَا نَعۡبُدُهُمۡ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَآ إِلَى ٱللَّهِ زُلۡفَىٰٓ إِنَّ ٱللَّهَ يَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡ فِي مَا هُمۡ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَنۡ هُوَ كَٰذِبٞ كَفَّارٞ 3
Tẹti gbọ, Allah ni O ni ẹsin ti o pa lofo kuro nibi ẹbọ, awọn ti wọn mu alaayo ninu awọn oosa ati awọn ẹlẹsẹ yatọ si Allah, ti wọn sin wọn dipo Allah jẹ ẹniti o nwa awijare nibi ijọsin wọn pẹlu gbolohun wọn wipe: a ko sin awọn wọnyi ayaafi ki wọn le mu wa sun mọ Allah ni ipo, ki wọn si le gbe awọn nkan ti a nfẹ lọ si ọdọ Rẹ, ki wọn si tun sipẹ fun wa lọdọ Rẹ; dajudaju Allah yoo idajọ laarin awọn olugbagbọ ododo olumu U lọkan soso ati laarin awọn keferi ẹlẹbọ ni ọjọ igbende nibi ohun ti wọn nse iyapa rẹ ninu imu u lọkan soso, dajudaju Allah ko nii fi ẹniti o jẹ oluparọ mọ Ọ, ti o si nfi akẹgbẹ ti si lọdọ se kongẹ imọna lọsi ibi ododo, ti o si tun jẹ alarinọ si ikẹ Allah le lori.
لَّوۡ أَرَادَ ٱللَّهُ أَن يَتَّخِذَ وَلَدٗا لَّٱصۡطَفَىٰ مِمَّا يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ سُبۡحَٰنَهُۥۖ هُوَ ٱللَّهُ ٱلۡوَٰحِدُ ٱلۡقَهَّارُ 4
Ti Allah ba gbero lati yan ọmọ ki ba sẹsa ẹniti o wu U ninu awọn ẹda Rẹ, ki ba si gbe si ipo ọmọ, fifọmọ ati mimọ kanga Rẹ kuro nibi ohun ti awọn ẹlẹbọ yii nsọ, Oun ni ọkan nibi bibẹ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn isẹ Rẹ, ko si orogun fun Un nibẹ, Olubori gbogbo ẹda Rẹ.
خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۖ يُكَوِّرُ ٱلَّيۡلَ عَلَى ٱلنَّهَارِ وَيُكَوِّرُ ٱلنَّهَارَ عَلَى ٱلَّيۡلِۖ وَسَخَّرَ ٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ كُلّٞ يَجۡرِي لِأَجَلٖ مُّسَمًّىۗ أَلَا هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡغَفَّٰرُ 5
O da gbogbo sanmọ ati ilẹ nitori ọgbọn kan ti o ga, kii se fun ere gẹgẹ bi awọn alabosi se nsọ, O nmu oru wọ inu ọsan, o si nmu ọsan wọ inu oru, ti ikan ba de ninu wọn omiran yoo pamọ, O tun rọ oorun, O si rọ osupa, gbogbo wọn nlọ ni asiko ti a pebubu, O nni titan isẹmin aye yii, tiẹti gbọ, Oun ti mimọ nbẹ fun ni abiyi ti yoo gbẹsan lara awọn ọta Rẹ, ẹnikankan ko si le bori Rẹ, Alaforijin ẹsẹ ẹniti o ba sẹri ninu awọn ẹru Rẹ.
Olupepe si ọdọ Allah yoo maa rankan ẹsan lọdọ Rẹ, ko nii gbero ẹsan lori ohun ti o npe wọn si ni ododo lọdọ eniyan.
Ijẹra ẹni nipa ko si ninu ẹsin.
Sise atẹgun si ọdọ Allah ma njẹ pẹlu awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati igbagbọ, ati sise isẹẹre ti ko si omiran.