سورة (MAKIYYAH)
Alaye awọn isesi awọn eniyan pelu awọn idẹra, ati isesi Ọlọhun Ọba nipa yiyi awọn isesi naa pada.
ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَهُ ٱلۡحَمۡدُ فِي ٱلۡأٓخِرَةِۚ وَهُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡخَبِيرُ 1
Ọpẹ fun Allah eyiti O ni gbogbo ohun ti nbẹ ni sanmọ ati gbogbo ohun ti nbẹ ni ilẹ niti sisẹda ati ninikapa ati didari, Ounn nikan ti mimọ nbẹ fun ni O ni ẹyin ni ọrun, Oun si ni ọjọgbọn nibi isẹda ati idari eto Rẹ, olufunni niro nipa isesi awọn ẹru Rẹ, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ.
يَعۡلَمُ مَا يَلِجُ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا يَخۡرُجُ مِنۡهَا وَمَا يَنزِلُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ وَمَا يَعۡرُجُ فِيهَاۚ وَهُوَ ٱلرَّحِيمُ ٱلۡغَفُورُ 2
O mọ ohun ti o nwọ inu ilẹ ninu omin ati awọn irugbin, O si mọ ohun ti o njade nibẹ gẹgẹ bi awọn irugbin ati nkan miran, O si mọ ohun ti nsọkalẹ lati sanmọ gẹgẹ bi ojo, awọn Malaika ati arisiki, O si mọ ohun ti ngoke sanmọ gẹgẹ bi awọn Malaika ati awọn isẹ awọn ẹru Rẹ ati awọn ẹmin wọn, Oun si ni olukẹ fun awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ododo, oluforijin ẹsẹ ẹniti o ba sẹri lọ si ọdọ Rẹ.
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَا تَأۡتِينَا ٱلسَّاعَةُۖ قُلۡ بَلَىٰ وَرَبِّي لَتَأۡتِيَنَّكُمۡ عَٰلِمِ ٱلۡغَيۡبِۖ لَا يَعۡزُبُ عَنۡهُ مِثۡقَالُ ذَرَّةٖ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَآ أَصۡغَرُ مِن ذَٰلِكَ وَلَآ أَكۡبَرُ إِلَّا فِي كِتَٰبٖ مُّبِينٖ 3
Awọn ti o se keferi si Allah sọpe: asiko ikẹyin ko le waa ba wa lailai, sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: ko ri bẹẹ, mo fi Allah bura, paapaa asiko ikẹyin eyiti ẹ npe nirọ yoo wa ba yin, sugbọn ẹnikankan ko mọ asiko yii ayaafi Allah, Oun ti mimọ nbẹ fun ni onimimọ nipa ohun ti o pamọ nibi asiko ikẹyin ati nkan miran, osunwọn ti o kere ninu inọ ori ko pamọ fun mimọ Rẹ ninu sanmọ tabi ninu ilẹ koda ohun ti o kere ju eleyi lọ ti a darukọ tabi tobi ju u lọ ko pamọ fun Un ayaafi ki o jẹ ohun ti a ti kọ silẹ sinu iwe ti o fi oju han, ohun si ni ọpọn ti a daabobo eyiti wọn kọ gbogbo nkan si inu rẹ, yoo si maa wa titi di ọjọ igbende.
لِّيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِۚ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَرِزۡقٞ كَرِيمٞ 4
Allah nfi rinlẹ eyiti o ba fẹ fi rinlẹ ninu ọpọn ti a daabobo naa, ki O le sẹsan fun awọn ti o nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si nse ọpọ isẹẹre, awọn ti a fi iroyin yii royin aforijin nbẹ fun ẹsẹ wọn ni ọdọ Ọlọhun Ọba wọn, ko ni tibẹ gba wọn mu, arisiki alapọnle naa si wa fun wọn; ohun si ni ọgba idẹra ni ọjọ igbende.
وَٱلَّذِينَ سَعَوۡ فِيٓ ءَايَٰتِنَا مُعَٰجِزِينَ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٞ مِّن رِّجۡزٍ أَلِيمٞ 5
Awọn ti wọn nsisẹ niti gbigbiyanju lati ba ohun ti Allah sọkalẹ jẹ ninu awọn amin, ti wọn wa nsọ nipa rẹ wipe: idan ni, wọn si tun nsọ nipa ojisẹ Wa wipe: alagbegba ni, onidan ni, kọrin kọrin ni, awọn ni ẹniti awọn iroyin yii royin, iya ti o buru ju, ti o si le koko nbẹ fun wọn ni ọjọ igbende.
وَيَرَى ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ ٱلَّذِيٓ أُنزِلَ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَ هُوَ ٱلۡحَقَّ وَيَهۡدِيٓ إِلَىٰ صِرَٰطِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَمِيدِ 6
Awọn onimimọ ninu ọmọ lẹyin ojisẹ si jẹri ati awọn ti o nigbagbọ ninu awọn onimimọ awọn ti a fun ni tira wipe ohun ti Allah sọkalẹ fun ọ ninu imisi jẹ ododo, ti ko si iyemeji nibẹ, o si ntọni si oju ọna iyi ti ẹnikankan ko le bori rẹ, ti ẹyin nbẹ nibẹ ni aye ati lọrun.
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ هَلۡ نَدُلُّكُمۡ عَلَىٰ رَجُلٖ يُنَبِّئُكُمۡ إِذَا مُزِّقۡتُمۡ كُلَّ مُمَزَّقٍ إِنَّكُمۡ لَفِي خَلۡقٖ جَدِيدٍ 7
Awọn ti o se keferi si Allah sọ fun apakan wọn; niti ijọni loju ati iseyẹyẹ nipa ohun ti ojisẹ naa ti ikẹ ati nbẹ fun muwa: se ka tọka fun yin ọkunrin kan ti yoo fun yin niro nipa igbati ẹ ba ku, ti wọn si ge yin ni keekeeke wipe wọn yoo gbeyin dide lẹyin iku yin ni alaaye?!
Gbigbaaye imọ Allah ti mimọ nbẹ fun ti o rọkirika gbogbo nkan.
Ọla awọn onimimọ.
Atako awọn ẹlẹbọ si igbedide abara jẹ nkan atako fun agbara Allah eyiti o da wọn.