سورة (MADANIYYAH)
Alaye akolekan Allah si anọbi rẹ - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun - ati idaabobo awọn alabagbe rẹ ati ara ile rẹ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ ٱتَّقِ ٱللَّهَ وَلَا تُطِعِ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَٱلۡمُنَٰفِقِينَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا 1
Irẹ anọbi duro sinsin ati ẹniti o nbẹ pẹlu rẹ lori ipaya Allah pẹlu mima tẹle awọn asẹ Rẹ ati jijnna si awọn nkan ti o kọ, ki o si bẹru Rẹ ni Oun nikan soso, mase tẹle awọn keferi ati awọn sọbẹ selu nibi ifẹ inu wọn, dajudaju Allah jẹ onimimọ nipa ete ti awọn keferi ati awọn sọbẹ selu nda, o si jẹ ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati idari eto Rẹ.
وَٱتَّبِعۡ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٗا 2
Ki o si maa tẹle ohun ti Ọlọhun Ọba rẹ sọkalẹ fun nibi imisi, dajudaju Allah jẹ olufonu niro nkan ti ẹ nse, nkankan ko bọ mọ lọwọ nibẹ, yoo si san yin lẹsan lori awọn isẹ yin.
وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلٗا 3
Ki o si gbarale Allah nikan soso nibi alamọri rẹ lapapọ, Allah ti mimọ nbẹ fun si to ni oludaabobo fun ẹniti o ba gbarale ninu awọn ẹru Rẹ.
مَّا جَعَلَ ٱللَّهُ لِرَجُلٖ مِّن قَلۡبَيۡنِ فِي جَوۡفِهِۦۚ وَمَا جَعَلَ أَزۡوَٰجَكُمُ ٱلَّٰٓـِٔي تُظَٰهِرُونَ مِنۡهُنَّ أُمَّهَٰتِكُمۡۚ وَمَا جَعَلَ أَدۡعِيَآءَكُمۡ أَبۡنَآءَكُمۡۚ ذَٰلِكُمۡ قَوۡلُكُم بِأَفۡوَٰهِكُمۡۖ وَٱللَّهُ يَقُولُ ٱلۡحَقَّ وَهُوَ يَهۡدِي ٱلسَّبِيلَ 4
Allah ko fi ọkan meji si inu igbaaya ọkunrin kan soso, bẹẹ naa ni ko fi awọn iyawo si ipo awọn iya nibi ise ni eewọ, bẹẹni ko se awọn ọmọ ti wọn nfi orukọ wọn pe ẹni ni ẹniti o wa ni ipo ọmọ atarabi, dajudaju ifi iyawo ẹni we ẹyin mama ẹni - oun ni ki ọkunrin se iyawo rẹ leewọ fun ara rẹ gẹgẹ bii iya rẹ ati ẹgbọn rẹ lobirin - gẹgẹ bẹẹ naa ni ọmọ afipeni: ninu awọn isesi asiko aimọkanmọkan eyiti Islam ko fi ọwọ si, eyi tii se ifẹyin iyawo ẹni we ti iya ẹni ati ọmọ apemọni, gbolohun eyiti ẹ npaara rẹ ni ẹnu yin, ti ko si ifidimulẹ fun un, iyawo kii se iya, bẹẹni ọmọ apemọni kii se ọmọ fun ẹniti wọn pe e mọ, Allah ti mimọ nbẹ fun sọ ọrọ ododo ki awọn ẹru Rẹ le maa mu sẹ, O si nfi ni mọ ọna ododo.
ٱدۡعُوهُمۡ لِأٓبَآئِهِمۡ هُوَ أَقۡسَطُ عِندَ ٱللَّهِۚ فَإِن لَّمۡ تَعۡلَمُوٓاْ ءَابَآءَهُمۡ فَإِخۡوَٰنُكُمۡ فِي ٱلدِّينِ وَمَوَٰلِيكُمۡۚ وَلَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٞ فِيمَآ أَخۡطَأۡتُم بِهِۦ وَلَٰكِن مَّا تَعَمَّدَتۡ قُلُوبُكُمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمًا 5
Ẹ se afiti awọn ọmọ ti ẹ npe si ọdọ awọn baba wọn ti o jẹ tootọ, fifi wọn ti si ọdọ wọn ni deede ni ọdọ Allah, ti ẹ ko ba mọ awọn baba ti ẹ le se afiti wọn si ọdọ wọn, ọmọ iya yin ninu ẹsin ni wọn jẹ, wọn si jẹ ẹni ibọkun ẹru kuro lọrun rẹ yin ni wọn jẹ, ki ẹ ya maa pe ikọọkan wọn ni irẹ ọmọ iya ati irẹ ọmọ ẹgbọn baba mi, ko si ẹsẹ fun yin nigbati ẹ ba se asise nibi fifi ọmọ apemọni pe ẹniti wọn ba fi npe e, sugbọn ẹ maa da ẹsẹ ti ẹ ba mọọmọ pe eleyi, Allah si jẹ oluforijinni fun ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, Onikẹ si wọn nitori aiko gba wọn mu nitori asise.
ٱلنَّبِيُّ أَوۡلَىٰ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ مِنۡ أَنفُسِهِمۡۖ وَأَزۡوَٰجُهُۥٓ أُمَّهَٰتُهُمۡۗ وَأُوْلُواْ ٱلۡأَرۡحَامِ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلَىٰ بِبَعۡضٖ فِي كِتَٰبِ ٱللَّهِ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُهَٰجِرِينَ إِلَّآ أَن تَفۡعَلُوٓاْ إِلَىٰٓ أَوۡلِيَآئِكُم مَّعۡرُوفٗاۚ كَانَ ذَٰلِكَ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مَسۡطُورٗا 6
Anọbi tii se Muhammad ẹniti ikẹ ati ọla nbẹ fun ni ẹniti awọn olugbagbọ ododo lẹtọ si ju ẹmi ara wọn lọ nibi gbogbo ohun ti o ba pe wọn sibẹ, koda bi ẹmin wọn ba fi si ibi ẹlomiran, bẹẹni awọn iyawo rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun wa ni ipo awọn iya fun awọn olugbagbọ ododo, o wa jẹ eewọ fun eyikeyi olugbagbọ ododo ki o fẹ ikan ninu wọn lẹyin iku rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, bẹẹni awọn alasunmọ lẹtọ si apakan wọn ju apakan wọn lọ nibi ijogun ninu idajọ Allah ninu awọn olugbagbọ ati oluse irin ajo si oju ọna Allah, awọn ti wọn ma njogun ara wọn ni ibẹrẹ pẹpẹ Islam, lẹyin naa ni wọn paarọ jijogun ara wọn lẹyin eleyi ayaafi ti ẹ ba se daadaa –ẹyin olugbagbọ ododo- si awọn eniyan yin ti kii se ẹniti yoo jẹ ogun gẹgẹ bi mimu daadaa de ọdọ wọn ati sise daadaa fun wọn, idajọ yii jẹ ohun ti o ti wa ninu ọpọn ti a daabobo, ti a kọ nkan si, ti o si jẹ dandan sisisẹ tọ ọ.
Ko si ẹnikankan ti o dagba ju ki wọn pa lasẹ daadaa lọ, ki wọn si kọ fun kuro nibi ibajẹ.
Mimu igbamun lori asise kuro fun awọn ijọ yii.
Jijẹ dandan titi erongba anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun siwaju erongba ara ẹni.
Sise alaye giga awọn iyawo anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ati jijẹ eewọ fifẹ wọn lẹyin rẹ; nitoripe wọn jẹ iya fun awọn olugbagbọ ododo.