سورة (MAKIYYAH)
Sise alaye paapaa sisẹda ati awọn isesi ọmọniyan laye ati ni ọjọ ikẹhin.
الٓمٓ 1
(الٓمٓ) (Alif Lam Mim) ọrọ ti gbawaju lori iran rẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọrah.
تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ لَا رَيۡبَ فِيهِ مِن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 2
Alukuraani yii ti Muhammad - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun - mu wa jẹ ounti a sọkalẹ fun un lati ọdọ olutọju agbanla aye, ti ko si iyemeji nibẹ.
أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۚ بَلۡ هُوَ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ لِتُنذِرَ قَوۡمٗا مَّآ أَتَىٰهُم مِّن نَّذِيرٖ مِّن قَبۡلِكَ لَعَلَّهُمۡ يَهۡتَدُونَ 3
Dajudaju awọn keferi naa nsọpe: dajudaju Muhammad hun fun Ọlọhun Ọba rẹ ni, ọrọ ko ri bi wọn ti sọ, bikosepe ohun ni ododo ti ko iyemeji nibẹ eyiti o sọkalẹ ni ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ - irẹ ojisẹ - fun ọ ki o le maa fi dẹruba awọn ijọ kan, ti ojisẹ ko waa ba wọn, ti o fi ndẹru ba wọn nibi iya Allah, boya wọn yoo mọ ọna lọsi ibi ododo, ki wọn le tẹle e, ki wọn si sisẹ pẹlu rẹ.
ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَا فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ مَا لَكُم مِّن دُونِهِۦ مِن وَلِيّٖ وَلَا شَفِيعٍۚ أَفَلَا تَتَذَكَّرُونَ 4
Allah ni Ẹniti O da sanmọ, ti O si da ilẹ, O tun da ohun ti o wa laarin mejeeji ni ọjọ mẹfa, O ni agbara lati le da a ni ohun ti o kere si sisẹ oju, lẹyin naa O ga, O si gunwa si ori itẹ naa niti giga ti o tọ si gbigbọngbọn Rẹ, ko si fun yin -ẹyin eniyan- alatilẹyin ti o yatọ si I, ti yoo la ọrọ yin bọrun tabi olusipẹ ti yoo sipẹ yin ni ọdọ Ọlọhun Ọba yin, se ẹ ko ronu ni ki ẹ si sin Allah Eyiti o da yin, ki ẹ mase sin nkankan miran pẹlu Rẹ?!
يُدَبِّرُ ٱلۡأَمۡرَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ ثُمَّ يَعۡرُجُ إِلَيۡهِ فِي يَوۡمٖ كَانَ مِقۡدَارُهُۥٓ أَلۡفَ سَنَةٖ مِّمَّا تَعُدُّونَ 5
Allah ti mimọ nbẹ fun ndari ọrọ gbogbo awọn ẹda ni sanmọ ati ilẹ lẹyin naa ọrọ naa yoo gunke lọ si ọdọ Rẹ ni ọjọ kan ti odiwọn rẹ jẹ ẹgbẹrun ọdun ninu eyiti ẹyin nka - ẹyin eniyan - ni ile aye.
ذَٰلِكَ عَٰلِمُ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ 6
Ẹniti o ndari gbogbo eleyi lapapọ, Oun ni ẹniti o nimọ nipa nkan ti ko si ati ohun ti nbẹ, nkankan ko pamọ fun Un ninu mejeeji, alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, ti O ma ngbẹsan ni ọdọ awọn ọta Rẹ, O jẹ onikẹ si awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ododo.
ٱلَّذِيٓ أَحۡسَنَ كُلَّ شَيۡءٍ خَلَقَهُۥۖ وَبَدَأَ خَلۡقَ ٱلۡإِنسَٰنِ مِن طِينٖ 7
Ẹniti o da gbogbo nkan ni adape, O si bẹrẹ isẹda Adamọ lati ibi amọ laisi apejuwe siwaju.
ثُمَّ جَعَلَ نَسۡلَهُۥ مِن سُلَٰلَةٖ مِّن مَّآءٖ مَّهِينٖ 8
Lẹyin naa O se awọn arọmọdọmọ rẹ lẹyin rẹ lati inu omin eyiti o nsan, ti o si jade nibẹ (atọ).
ثُمَّ سَوَّىٰهُ وَنَفَخَ فِيهِ مِن رُّوحِهِۦۖ وَجَعَلَ لَكُمُ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡأَبۡصَٰرَ وَٱلۡأَفِۡٔدَةَۚ قَلِيلٗا مَّا تَشۡكُرُونَ 9
Lẹyin naa o pari ẹda ọmọniyan ni dọgbandọgba, O si fẹmi si i ninu ẹmin Rẹ pẹlu asẹ Malaika ti A la ifẹmi si bọ lọrun, o si se fun yin -ẹyin eniyan- awọn etigbọ ki ẹ le maa gbọ ọrọ pẹlu rẹ ati awọn iriran ki ẹ le maa riran pẹlu rẹ ati awọn ọkan ki ẹ le maa se laakaye pẹlu rẹ, o kere nigbati ẹ ndupẹ awọn idẹkun yii fun Allah eyiti O se le yin lori.
وَقَالُوٓاْ أَءِذَا ضَلَلۡنَا فِي ٱلۡأَرۡضِ أَءِنَّا لَفِي خَلۡقٖ جَدِيدِۢۚ بَلۡ هُم بِلِقَآءِ رَبِّهِمۡ كَٰفِرُونَ 10
Awọn ẹlẹbọ opurọ nipa igbende sọpe: ti a ba ku, ti a si ti se afẹku ni inu ilẹ, ti abara wa si ti di yerupẹ, se wọn yoo gbe wa dide ni alaaye ni titun ni?! Eleyi ko ba laakaye mu sugbọn wọn jẹ ẹniti o wa nibi ọrọ wọn yii ni olutako igbende ti wọn ko nigbagbọ nipa rẹ.
۞قُلۡ يَتَوَفَّىٰكُم مَّلَكُ ٱلۡمَوۡتِ ٱلَّذِي وُكِّلَ بِكُمۡ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمۡ تُرۡجَعُونَ 11
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ olupe igbende nirọ yii: malaika iku ti a fi ọrọ igbẹmin bọ lọrun ni yoo pa yin, lẹyin naa ọdọ Wa nikan ni ẹ o sẹri si fun isiro ati ẹsan ni ọjọ igbende.
ọgbọn ti nbẹ ninu gbigbe awọn ojisẹ dide ni ki wọn fi awọn ijọ wọn mọ ọna ti o duro tọ.
Fifi rinlẹ iroyin igunwa Allah laisi afiwe tabi afijọ.
Jijinna tefe ati ẹlẹbọ si igbende pẹlu hihan awọn ẹri le lori.