سورة (MADANIYYAH)
sise afirinle wipe ẹsin Islam ni ododo, ni ifesi pada lori awọn iruju awọn ti a fun ni tira, ati ifirinle fun awon olugbagbo.
Ohun ni suurah ti o sọkalẹ ni Mẹdinah, wọn sọ ni Suuratu Al-Imran, nitori didarukọ awọn ara ile Imran nibẹ, ninu aayah ẹlẹẹkẹtalelọgbọn ninu suurah naa.
الٓمٓ 1
(الٓمٓ) (Alif, Lam, Mim) awọn alifabẹẹti ẹlẹyọ-ẹyọ yii, iru rẹ ti siwaju ninu suuratul- Bakọra, o si nbẹ nibẹ itọka si kikagara awọn larubawa nibi mimu iru Alukuraani yii wa, pẹlu wipe dajudaju ohun ti wọn kojọ ni lati ibi iru awọn alifabẹẹti yii, eyiti wọn fi bẹrẹ suurah naa ati eyiti wọn ma nko ọrọ wọn jọ lati ibẹ.
ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡحَيُّ ٱلۡقَيُّومُ 2
Allah ni Ẹniti ko si ọba kankan ti wọn yoo ma jọsin fun ni tootọ ayaafi Oun nikan soso, yatọ si ẹlomiran, Olusẹmi si ni, ni isẹmi ti o pe perepere, ti ko si iku nibẹ tabi adinku, Oluduro fun ara Rẹ ni, Ẹniti o da duro fun ara Rẹ, ni O fi rọrọ kuro ni ọdọ gbogbo ẹda Rẹ, ati wipe pẹlu Rẹ ni gbogbo awọn ẹda Rẹ se duro, ti wọn ko si le rọrọ kuro ni ọdọ Rẹ, nibi gbogbo isesi wọn.
نَزَّلَ عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَأَنزَلَ ٱلتَّوۡرَىٰةَ وَٱلۡإِنجِيلَ 3
o sọkalẹ fun ọ - irẹ Anọbi - Alukuraani pẹlu sisọ ododo nibi awọn ifunniniro ati sise deede nibi awọn idajọ, ti o se deede ohun ti o siwaju rẹ ninu awọn tira tii se ti Ọlọhun Ọba, ti ko si si itako laarin wọn, ati wipe O sọ Taoraata kalẹ fun Muusa, ati Injeela fun Isa (ki ọla maa jẹ ti wọn) siwaju ki O to sọ Alukuraani kalẹ fun ọ, ati wipe awọn tira Ọlọhun Ọba yii gbogbo rẹ, imọna ni ati ijuwe fun awọn eniyan lọsi ibi ohun ti daadaa ẹsin wọn ati aye wọn wa, ati wipe O sọ ohun ti o nse onpinya (Al-Furqọọn) , eyiti wọn yoo fi maa mọ ododo yatọ si ibajẹ, ati ọnaamọ yatọ si anu. Ati wipe awọn ti wọn se aigbagbọ si awọn aayah Ọlọhun Ọba Allah, eyiti ti o sọkalẹ fun ọ, o nbẹ fun iya ti o le koko. Ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Alagbara, ti nkankan ko le bori Rẹ, Ẹniti O ma ngbẹsan ni lara ẹniti o ba pe awọn ojisẹ Rẹ nirọ, ti o tun wa yapa asẹ Rẹ.
مِن قَبۡلُ هُدٗى لِّلنَّاسِ وَأَنزَلَ ٱلۡفُرۡقَانَۗ إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدٞۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٞ ذُو ٱنتِقَامٍ 4
o sọkalẹ fun ọ - irẹ Anọbi - Alukuraani pẹlu sisọ ododo nibi awọn ifunniniro ati sise deede nibi awọn idajọ, ti o se deede ohun ti o siwaju rẹ ninu awọn tira tii se ti Ọlọhun Ọba, ti ko si si itako laarin wọn, ati wipe O sọ Taoraata kalẹ fun Muusa, ati Injeela fun Isa (ki ọla maa jẹ ti wọn) siwaju ki O to sọ Alukuraani kalẹ fun ọ, ati wipe awọn tira Ọlọhun Ọba yii gbogbo rẹ, imọna ni ati ijuwe fun awọn eniyan lọsi ibi ohun ti daadaa ẹsin wọn ati aye wọn wa, ati wipe O sọ ohun ti o nse onpinya (Al-Furqọọn) , eyiti wọn yoo fi maa mọ ododo yatọ si ibajẹ, ati ọnaamọ yatọ si anu. Ati wipe awọn ti wọn se aigbagbọ si awọn aayah Ọlọhun Ọba Allah, eyiti ti o sọkalẹ fun ọ, o nbẹ fun iya ti o le koko. Ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Alagbara, ti nkankan ko le bori Rẹ, Ẹniti O ma ngbẹsan ni lara ẹniti o ba pe awọn ojisẹ Rẹ nirọ, ti o tun wa yapa asẹ Rẹ.
إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَخۡفَىٰ عَلَيۡهِ شَيۡءٞ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِي ٱلسَّمَآءِ 5
Dajudaju Ọlọhun Ọba Allah nkankan ko nii pamọ fun Un, ninu ilẹ tabi ninu sanmọ, paapaa imọ Rẹ si rọkirika gbogbo nkan, eyiti o han ni ati eyiti o pamọ.
هُوَ ٱلَّذِي يُصَوِّرُكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡحَامِ كَيۡفَ يَشَآءُۚ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 6
Oun ni Ẹniti O nda yin ni aworan orisirisi, si awọn inu awọn iya yin, bi O se fẹ lọkunrin tabi lobinrin, ati rirẹwa tabi biburẹwa, ati ni funfun tabi ni dudu, ko si ẹniti ijọsin tọsi ni tootọ yatọ si Oun, Alagbara ti wọn ko lee bori ni, Ọjọgbọn si ni nibi idẹda ati idari Rẹ, ati sise ofin Rẹ.
هُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ مِنۡهُ ءَايَٰتٞ مُّحۡكَمَٰتٌ هُنَّ أُمُّ ٱلۡكِتَٰبِ وَأُخَرُ مُتَشَٰبِهَٰتٞۖ فَأَمَّا ٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمۡ زَيۡغٞ فَيَتَّبِعُونَ مَا تَشَٰبَهَ مِنۡهُ ٱبۡتِغَآءَ ٱلۡفِتۡنَةِ وَٱبۡتِغَآءَ تَأۡوِيلِهِۦۖ وَمَا يَعۡلَمُ تَأۡوِيلَهُۥٓ إِلَّا ٱللَّهُۗ وَٱلرَّٰسِخُونَ فِي ٱلۡعِلۡمِ يَقُولُونَ ءَامَنَّا بِهِۦ كُلّٞ مِّنۡ عِندِ رَبِّنَاۗ وَمَا يَذَّكَّرُ إِلَّآ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ 7
Oun ni Ẹniti O sọkalẹ fun ọ - irẹ Anọbi - Alukuraani, o nbẹ nibẹ awọn aayah ti o han ni itọkasi, ti ko si iruju nibẹ, awọn naa ni ipilẹ tira ati ọpọlọpọ rẹ, ati wipe ohun ni ibusẹri si nigbati iyapa ẹni ba sẹlẹ, o si nbẹ nibẹ awọn aayah miran, ti o gbe awọn itumọ ti o pọ dani, ti itumọ rẹ si ma nru ọpọlọpọ eniyan loju, ẹ ko wa ri awọn ti o nbẹ ninu ọkan wọn, yiyẹ kuro nibi ododo, wọn yoo fi eyiti o duro deede silẹ, ati wipe wọn yoo gba eyiti o ruju mu, ti o si mu royiroyi dani, wọn yoo maa wa pẹlu nkan naa, titan ina dida awuyewuye iruju silẹ ati sisọ awọn eniyan nu, ati wipe wọn yoo maa wa pẹlu nkan naa, yiyii pẹlu awọn ifẹ inu wọn lori ohun ti yoo se deede awọn ilana wọn, eyiti o ko dara, ati wipe ko le mọ paapa awọn itumọ awọn aayah yii, ati igbẹyin rẹ, eyiti wọn yoo maa yi si ayaafi Ọlọhun Ọba Allah. Ati wipe awọn ti wọn jido ninu imọ, ti wọn si dantọ ninu rẹ, wọn yoo maa sọ wipe a ni igbagbọ pẹlu Alukuraani patapata; toripe dajudaju gbogbo rẹ wa lati ọdọ Ọlọhun Ọba wa, ati wipe wọn yoo ma se alaye eyiti o ruju pẹlu eyiti duro tọ nibẹ, ati wipe ko nii ranti, ko si gba isiti ayaafi awọn ti wọn ni laakaye ti o ni alaafia.
رَبَّنَا لَا تُزِغۡ قُلُوبَنَا بَعۡدَ إِذۡ هَدَيۡتَنَا وَهَبۡ لَنَا مِن لَّدُنكَ رَحۡمَةًۚ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡوَهَّابُ 8
Awọn ti wọn jidu ninu imọ yii, wọn yoo maa sọ wipe, irẹ Ọlọhun Ọba wa, mase tẹ awọn ọkan wa kuro nibi ododo lẹyin igbati O ti fi wa mọ ọna lọ si ibẹ, ati wipe ko lawa kuro nibi ohun ti o fi ọwọ ba awọn ti wọn ti gbunri, ti wọn si ti yẹsẹ kuro nibi ododo, ki o si ta wa lọrẹ ikẹ ti o gbaaye lati ọdọ Rẹ, ti Iwọ yoo si fi ọkan wa mọ ọna pẹlu rẹ, ati wipe ti Iwọ yoo si sọ wa pẹlu rẹ kuro nibi anu, dajudaju Iwọ - Irẹ Ọlọhun Ọba wa - ni Olutani-lọrẹ ti O pọ ni ọrẹ tita.
رَبَّنَآ إِنَّكَ جَامِعُ ٱلنَّاسِ لِيَوۡمٖ لَّا رَيۡبَ فِيهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُخۡلِفُ ٱلۡمِيعَادَ 9
Irẹ Ọlọhun Ọba wa dajudaju Iwọ Yoo pada ko awọn eniyan jọ lapapọ si ọdọ Rẹ lati ba se isiro wọn, ni Ọjọ kan ti ko si iyemeji nibẹ, o nbọ ti ko si si ibuyẹ nibẹ, dajudaju Iwọ - Irẹ Ọlọhun Ọba wa - o kii yapa adehun.
Ọlọhun Ọba Allah gbe awijare duro, O si ge gbogbo awijare kuro fun ẹda pẹlu riran awọn ojisẹ ati sisọ awọn tira kalẹ eyiti o nse imọna lọsi ibi ododo, ati eyiti o nkilọ nibi ibajẹ.
Pipe imọ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) , ati rirọkirikaa Rẹ pẹlu awọn ẹda Rẹ, ko si nkankan ti yoo pamọ fun Un ninu ilẹ ati ninu sanmọ, yala o jẹ ohun ti o han ni tabi ti o pamọ.
Ninu ipilẹ awọn oni igbagbọ ododo, ti wọn jinlẹ ninu imọ, ni wọn maa tumọ ohun ti o ba ruju ninu awọn aayah naa pẹlu ohun ti o tọ ninu rẹ.
Sise ni pipe Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) ni ofin, ati mima beere ni ọwọ Rẹ idurisinsin lori ododo ati itọsọna ninu alamọri, paapaa julọ nigba awọn adanwo ati awọn ibẹru.