إِنَّ ٱلَّذِي فَرَضَ عَلَيۡكَ ٱلۡقُرۡءَانَ لَرَآدُّكَ إِلَىٰ مَعَادٖۚ قُل رَّبِّيٓ أَعۡلَمُ مَن جَآءَ بِٱلۡهُدَىٰ وَمَنۡ هُوَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ 85
Dajudaju ẹniti o sọ Alukuraani kalẹ fun ọ, ti O si imude ogongo rẹ lọranyan le ọ lori ati sisisẹ pẹlu ohun ti nbẹ ninu rẹ, Oun ni ẹniti yoo sẹri rẹ pada niti olusi mọka, sọ fun - irẹ ojisẹ - awọn ẹlẹbọ: Ọlọhun mi nimọ nipa ẹniti o wa pẹlu ododo ati ẹniti o wa ni ọna anu ti o fi oju han kuro nibi ọnaamọ ati ododo.
وَمَا كُنتَ تَرۡجُوٓاْ أَن يُلۡقَىٰٓ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبُ إِلَّا رَحۡمَةٗ مِّن رَّبِّكَۖ فَلَا تَكُونَنَّ ظَهِيرٗا لِّلۡكَٰفِرِينَ 86
Iwọ kii se - irẹ ojisẹ - ẹniti o nronu - siwaju igbende - nipa fifi Alukuraani ransẹ si ọ lati ọdọ Allah, sugbọn o jẹ ikẹ lati ọdọ Rẹ ti mimọ nbẹ fun, O si seto sisọ ọ kalẹ le ọ lori, mase jẹ oluranlọwọ fun awọn keferi lori ọna anu ti wọn wa.
وَلَا يَصُدُّنَّكَ عَنۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ بَعۡدَ إِذۡ أُنزِلَتۡ إِلَيۡكَۖ وَٱدۡعُ إِلَىٰ رَبِّكَۖ وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ 87
Mase jẹ ki awọn ẹlẹbọ yii le ọ kuro nibi awọn amin Allah lẹyin igbati O ti sọ ọ kalẹ fun ọ, ti iwọ yoo wa fi lọ gbe kike e ati mimu u de ogongo ju silẹ, ki o si maa pe awọn eniyan lọ si ibi igbagbọ ninu Allah ati ọkan soso Rẹ ati sise ofin Rẹ, masi se wa ninu awọn ẹlẹbọ ti o nse nkan miran mọ Allah bikosepe ki o wa ninu awọn olumu U lọkan, awọn ti ko sin nkankan ju Allah nikan soso lọ.
وَلَا تَدۡعُ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَۘ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۚ كُلُّ شَيۡءٍ هَالِكٌ إِلَّا وَجۡهَهُۥۚ لَهُ ٱلۡحُكۡمُ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ 88
Mase sin olujọsin fun miran mọ Allah, ko si ẹni ijọsin fun ododo yatọ si I, gbogbo nkan ni yoo parun ayaafi adaojukọ Rẹ ti mimọ nbẹ fun, Oun nikan ni O ni idajọ, yoo se idajọ pẹlu ohun ti o ba wu U, ọdọ Rẹ nikan ni ẹ o si sẹri si ni ọjọ igbende fun isiro ati ẹsan.
سورة (MAKIYYAH)
O duro lori ọrọ iduro sinsins ati suuru ni igba adanwo ati idaamun ati igbẹyin rẹ.
الٓمٓ 1
(الٓمٓ) (Alif Lam Mim) ọrọ ti gbawaju nipa irurẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọrah.
أَحَسِبَ ٱلنَّاسُ أَن يُتۡرَكُوٓاْ أَن يَقُولُوٓاْ ءَامَنَّا وَهُمۡ لَا يُفۡتَنُونَ 2
Se awọn eniyan lero ni wipe lori gbolohun wọn ti wọn nsọ: a nigbagbọ ninu Allah, wọn yoo waa fi wọn silẹ laidan wọn wo ki o le se alaye paapaa ohun ti wọn sọ: se olugbagbọ ododo tootọ ni wọn bi?! ọrọ ko ri bi wọn se lero.
وَلَقَدۡ فَتَنَّا ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۖ فَلَيَعۡلَمَنَّ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ صَدَقُواْ وَلَيَعۡلَمَنَّ ٱلۡكَٰذِبِينَ 3
paapaa a ti dan awọn ti o siwaju wọn wo, Ọlọhun Allah fẹẹ fi imọ gbangba han, O si fẹ si gaga ododo awọn sootọ sootọ fun yin nibi igbagbọ wọn ati irọ parọ parọ nibẹ.
أَمۡ حَسِبَ ٱلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلسَّئَِّاتِ أَن يَسۡبِقُونَاۚ سَآءَ مَا يَحۡكُمُونَ 4
Tabi awọn ti o nse ẹsẹ ẹbọ lero ati ohun ti o yatọ si i nlero lati kagaara ba wa ati lila kuro nibi iya Wa? Idajọ wọn yii buru eyiti wọn nda yii, wọn ko le ko agara ba Allah, bẹẹni wọn ko le la kuro nibi iya Rẹ ti wọn ba ku lori keferi wọn.
مَن كَانَ يَرۡجُواْ لِقَآءَ ٱللَّهِ فَإِنَّ أَجَلَ ٱللَّهِ لَأٓتٖۚ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ 5
Ẹniti o ba nrankan pipade Allah ni ọjọ igbende ki wọn le sẹ lẹsan, dajudaju igbati Ọlọhun Ọba Allah ti fi lelẹ fun eleyi nbọ laipẹ, Oun si ni olugbọ ọrọ awọn ẹru Rẹ, Onimimọ nipa awọn isẹ wọn, nkankan ko le fo O ru nibẹ, Yoo si san wọn lẹsan le lori.
وَمَن جَٰهَدَ فَإِنَّمَا يُجَٰهِدُ لِنَفۡسِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَغَنِيٌّ عَنِ ٱلۡعَٰلَمِينَ 6
Ẹniti o ba ja ẹmin rẹ logun pẹlu gbigbe lori itẹle asẹ ati jijinna si ẹsẹ, ti o si gbiyanju si oju ọna Allah, dajudaju ẹmin rẹ ni o nja logun; nitoripe anfaani eleyi yoo sẹri waa ba, bẹẹ ni Allah si rọrọ kuro ni ọdọ awọn ẹda lapapọ, itẹle asẹ wọn ko le lekun fun Un, bẹẹni ẹsẹ wọn ko le din ku.
Kikọfunni kuro nibi mimọ kun awọn ẹni anu lọwọ.
Pipani lasẹ gbigba mimu ọkan soso Ọlọhun Ọba dani ati jijinna si sise ẹbọ pẹlu Rẹ.
Adanwo awọn olugbagbọ ododo ati yiyẹwọn wo jẹ isesi Allah.
Rirọrọ Allah kuro nibi titẹle asẹ ẹru Rẹ.