مَن جَآءَ بِٱلۡحَسَنَةِ فَلَهُۥ خَيۡرٞ مِّنۡهَا وَهُم مِّن فَزَعٖ يَوۡمَئِذٍ ءَامِنُونَ 89
Ẹniti o ba wa ni ọjọ igbende pẹlu igbagbọ ati isẹẹre alujannah nbẹ fun un, wọn jẹ ẹni ifọkan balẹ lati ibi ifọkan balẹ Allah fun wọn kuro nibi ipaya ọjọ igbende.
وَمَن جَآءَ بِٱلسَّيِّئَةِ فَكُبَّتۡ وُجُوهُهُمۡ فِي ٱلنَّارِ هَلۡ تُجۡزَوۡنَ إِلَّا مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 90
Ẹniti o ba si wa pẹlu keferi awọn ẹsẹ ina nbẹ fun un, wọn yoo ju wọn lati ibi oju wọn sibẹ, wọn yoo si maa sọ fun niti eebu ati iyẹpẹrẹ fun wọn: njẹ wọn san yin lẹsan nkankan ju ohun ti ẹ se ni ile aye ni keferi ati awọn ẹsẹ lọ bi?
إِنَّمَآ أُمِرۡتُ أَنۡ أَعۡبُدَ رَبَّ هَٰذِهِ ٱلۡبَلۡدَةِ ٱلَّذِي حَرَّمَهَا وَلَهُۥ كُلُّ شَيۡءٖۖ وَأُمِرۡتُ أَنۡ أَكُونَ مِنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ 91
Sọ fun wọn - irẹ ojisẹ - dajudaju wọn pa mi lasẹ ki nma sin Ọlọhun Ọba ti o ni Mẹkkah eyiti o se ni ọwọ, wọn ko gbọdọ ta ẹjẹ silẹ nibẹ, bẹẹni wọn ko gbọdọ se abosi si ẹnikankan, wọn si gbọdọ pa nkan idẹdẹ ibẹ, wọn ko gbọdọ ge igi ibẹ, Oun ti mimọ nbẹ fun ni o ni ọla gbogbo nkan, O si pami lasẹ ki nwa ninu awọn ti o jupa jusẹ si Allah, ti o si tẹriba fun itẹle asẹ Rẹ.
وَأَنۡ أَتۡلُوَاْ ٱلۡقُرۡءَانَۖ فَمَنِ ٱهۡتَدَىٰ فَإِنَّمَا يَهۡتَدِي لِنَفۡسِهِۦۖ وَمَن ضَلَّ فَقُلۡ إِنَّمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُنذِرِينَ 92
Wọn tun pami lasẹ ki nmaa ka Alukuraani fun awọn eniyan, ẹniti o ba mọna lati ibi itọsọna rẹ, ti o si se ohun ti o wa ninu rẹ, ti itọsọna rẹ si se lanfaani, sugbọn ẹniti o ba sọnu, ti o si yẹ kuro nibẹ, ti o wa tako o, ti ko se ohun ti o wa nibẹ: ki o sọpe dajudaju emi wa ninu awọn olukilọ, mo nse ikilọ fun yin kuro nibi iya Allah, bẹẹni imọna yin ko si ni ọwọ mi.
وَقُلِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ سَيُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ فَتَعۡرِفُونَهَاۚ وَمَا رَبُّكَ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ 93
Ki o si sọpe - irẹ ojisẹ -: ọpẹ ni fun Allah lori awọn idẹkun Rẹ eyiti ko see ka, Allah yoo fi awọn amin Rẹ han yin lara yin ati ni sanmọ ati ilẹ ati arisiki, ẹ yoo si pada mọ ọ ni mimọ ti yoo tọ yin si itẹriba fun ododo, Ọlọhun Ọba rẹ ki se ẹniti o fọnu nipa ohun ti ẹ nse, bikosepe O jẹ ẹniti O nri i, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ, yoo si san yin lẹsan le lori.
سورة (MAKIYYAH)
Isesi Ọlọhun nibi gbigba awọn olugbagbọ ododo ti wọnlẹ laaye ati pipa awọn olusegberaga run.
طسٓمٓ 1
(طسٓمٓ) (Tọ sin Mim) ọrọ ti gbawaju lori awọn iran rẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọrah.
تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ 2
Eleyi ni awọn aayah Alukuraani ti o fi oju han.
نَتۡلُواْ عَلَيۡكَ مِن نَّبَإِ مُوسَىٰ وَفِرۡعَوۡنَ بِٱلۡحَقِّ لِقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ 3
A nka fun ọ ninu iro Musa ati fir'aona pẹlu ododo eyiti ko si iyemeji nibẹ fun awọn ijọ ti o nigbagbọ; nitoripe dajudaju awọn ni wọn yoo se anfaani pẹlu ohun ti o wa nibẹ.
إِنَّ فِرۡعَوۡنَ عَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَجَعَلَ أَهۡلَهَا شِيَعٗا يَسۡتَضۡعِفُ طَآئِفَةٗ مِّنۡهُمۡ يُذَبِّحُ أَبۡنَآءَهُمۡ وَيَسۡتَحۡيِۦ نِسَآءَهُمۡۚ إِنَّهُۥ كَانَ مِنَ ٱلۡمُفۡسِدِينَ 4
Dajudaju fir'aona kọja ẹnu aala lori ilẹ Misira, o si jẹ gaba nibẹ, o si sọ awọn ara ibẹ di ipin ọtọọtọ, ti apakan wọn nyẹpẹrẹ apakan, awọn naa si ni arọmọdọmọ isirẹli pẹlu pipa awọn ọmọkunrin wọn ati siẹ awọn ọmọbirin wọn ku fun isisẹ sin niti imọọmọ yiyẹpẹrẹ wọn, dajudaju o wa ninu awọn olubilẹjẹ ni oriilẹ pẹlu sise abosi ati ikọja ẹnu aala ati isegberaga.
وَنُرِيدُ أَن نَّمُنَّ عَلَى ٱلَّذِينَ ٱسۡتُضۡعِفُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَنَجۡعَلَهُمۡ أَئِمَّةٗ وَنَجۡعَلَهُمُ ٱلۡوَٰرِثِينَ 5
A si ngbero lati sọla lori awọn ọmọ isirẹli, awọn ti fir'aona yẹpẹrẹ lori ilẹ misirọ pẹlu pipa ọta wọn run, ati mimu ijọlẹ kuro lara wọn, ati sisọ wọn di asiwaju ti awọn eniyan yoo maa kọse wọn nibi ododo, a o si tun se wọn ni ẹnti yoo jogun ilẹ onibukun Shaamu lẹyin iparun fir'aona gẹgẹ bi Allah ti O ga julọ se sọ: (وَأَوۡرَثۡنَا ٱلۡقَوۡمَ ٱلَّذِينَ كَانُواْ يُسۡتَضۡعَفُونَ مَشَٰرِقَ ٱلۡأَرۡضِ وَمَغَٰرِبَهَا ٱلَّتِي بَٰرَكۡنَا فِيهَاۖ) (a si sọ ijọ eyiti wọn sọ di ọlẹ ni ibuyọ oorun ilẹ ati ibuwọ rẹ eyiti a fi ibukun si di ẹniti yoo jogun).
Igbagbọ ati isẹ rere jẹ okunfa ọla kuro nibi ipaya ọjọ igbende.
Keferi ati ẹsẹ jẹ okunfa wiwọ ina.
Sise ipaniyan leewọ ati abosi ati didẹdẹ ni aaye ọwọ naa.
Aranse ati igbani laaye jẹ igbẹyin awọn olugbagbọ ododo.