سورة (MAKIYYAH)
Alaye awọn amin Ọlọhun ti o fi kun awọn ojisẹ lọwọ ati iparun awọn onirọ.
طسٓمٓ 1
(طسٓمٓ) (Tọ sin Mim) ọrọ ti gbawaju lori iru rẹ ni ibẹrẹ suuratu bakọrah.
تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ 2
Eleyi ni awọn aayah alukuraani ti o nsalaye ododo yatọ si ibajẹ.
لَعَلَّكَ بَٰخِعٞ نَّفۡسَكَ أَلَّا يَكُونُواْ مُؤۡمِنِينَ 3
O seese - irẹ ojisẹ - nitori oju kokoro rẹ si imọna wọn, ki iwọ pa ara rẹ niti ibanujẹ ati ise oju kokoro si imọna wọn.
إِن نَّشَأۡ نُنَزِّلۡ عَلَيۡهِم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ ءَايَةٗ فَظَلَّتۡ أَعۡنَٰقُهُمۡ لَهَا خَٰضِعِينَ 4
Ti a ba fẹ la ti sọ aayah kalẹ le wọn lori lati sanmọ, a o sọ ọ kalẹ le wọn lori, ti ọrun wọn yoo jẹ ohun ti yoo tẹriba ni ẹni yẹpẹrẹ sugbọn awa ko fẹ eleyi, ki o le jẹ adanwo fun wọn: boya wọn yoo nigbagbọ si kọkọ?
وَمَا يَأۡتِيهِم مِّن ذِكۡرٖ مِّنَ ٱلرَّحۡمَٰنِ مُحۡدَثٍ إِلَّا كَانُواْ عَنۡهُ مُعۡرِضِينَ 5
Nkankan ko waa ba awọn ẹlẹbọ wọnyi ninu iranti ti a sẹsẹ sọkalẹ lati ọdọ Ọba Ajọkẹ Aye pẹlu awọn ẹri Rẹ eyiti o ntọka si ijọkan soso Rẹ ati gbigba Anọbi Rẹ lododo ayaafi ki wọn gunri nipa titẹtigbọ Ọ ati gbigba A lododo.
فَقَدۡ كَذَّبُواْ فَسَيَأۡتِيهِمۡ أَنۢبَٰٓؤُاْ مَا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ 6
Paapa wọn ti pe ounti awọn ojisẹ wọn mu wa ba wọn nirọ, ododo iro nkan ti wọn fi se yẹyẹ yoo si pada waa ba wọn, bẹẹni yoo si sẹlẹ le wọn lori.
أَوَ لَمۡ يَرَوۡاْ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ كَمۡ أَنۢبَتۡنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوۡجٖ كَرِيمٍ 7
Se awọn olutako lori keferi yii yoo sẹku, bẹẹ ti wọn ko ni woye si ilẹ nipa awọn oniranran irugbin eyiti a mu jade nibẹ, ti o dara ni riri oju, ti o si pọ ni anfaani ni?!
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ 8
Dajudaju nibi mimu irugbin jade nilẹ ati oniranran irugbin naa jẹ itọka ti o fi oju han lori agbara ẹniti o mu jade lori jiji awọn oku, bẹẹ ni ọpọ wọn ko jẹ olugbagbọ ododo.
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ 9
Dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - ire ojise - Oun ni Ẹniti yoo bori ti ẹnikẹni ko le bori Rẹ, O si jẹ onikẹ si awọn ẹru Rẹ.
وَإِذۡ نَادَىٰ رَبُّكَ مُوسَىٰٓ أَنِ ٱئۡتِ ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ 10
Tun ranti - irẹ ojisẹ - nigbati Ọlọhun Ọba rẹ pe Musa, ni ẹniti O npa a lasẹ, ki o lọọ ba awọn ijọ alabosi nitori sise keferi wọn si Allah ati mimu ijọ Musa sin ni ẹru.
قَوۡمَ فِرۡعَوۡنَۚ أَلَا يَتَّقُونَ 11
Awọn ni ijọ Fir'aona, O npa wọn lasẹ pẹlu pẹlẹpẹlẹ ati irọrun pẹlu ipaya Allah ati titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijinna si awọn nakn ti wọn kọ.
قَالَ رَبِّ إِنِّيٓ أَخَافُ أَن يُكَذِّبُونِ 12
Musa ẹniti ọla nbẹ fun sọpe: dajudaju emi npaya nibi ki wọn ma pe mi nirọ nipa ohun ti mo mu wa ba wọn nipa Irẹ.
وَيَضِيقُ صَدۡرِي وَلَا يَنطَلِقُ لِسَانِي فَأَرۡسِلۡ إِلَىٰ هَٰرُونَ 13
Ọkan mi si fun pinpin lori pipe mi nirọ, bẹẹni ahọn mi naa ha nibi ọrọ, ki o ya ran Jibril ẹniti ọla nbẹ fun si ọmọ iya mi Haruuna ki o le jẹ oluranlọwọ fun mi.
وَلَهُمۡ عَلَيَّ ذَنۢبٞ فَأَخَافُ أَن يَقۡتُلُونِ 14
Mo si sẹ wọn nitori pipa ti mo pa kibiti, mo wa npaya ki wọn o ma baa pa mi.
قَالَ كَلَّاۖ فَٱذۡهَبَا بَِٔايَٰتِنَآۖ إِنَّا مَعَكُم مُّسۡتَمِعُونَ 15
Ọlọhun Allah sọ fun Musa ẹniti ọla nbẹ fun: ko ri bẹẹ, wọn ko le pa ọ, ki o yaa maa lọ iwọ ati ọmọ iya rẹ Haruna pẹlu awọn amin Wa eyiti o ntọka si ijẹ ododo ẹyin mejeeji, dajudaju Awa yoo bẹ pẹlu yin niti aranse ati ikunlọwọ ni ẹniti yoo maa tẹti gbọ ohun ti ẹ ba nsọ ati ohun ti wọn ba sọ fun yin, nkankan ko ni bọ mọ Wa lọwọ nibẹ.
فَأۡتِيَا فِرۡعَوۡنَ فَقُولَآ إِنَّا رَسُولُ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 16
Ki ẹ ya lọ ba Fir'aona, ki ẹ si sọ fun: awa jẹ ojisẹ meji si ọdọ rẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba ti O da gbogbo ẹda patapata.
أَنۡ أَرۡسِلۡ مَعَنَا بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ 17
Ki o gbe awọn ọmọ bani isirẹli dide pẹlu wa.
قَالَ أَلَمۡ نُرَبِّكَ فِينَا وَلِيدٗا وَلَبِثۡتَ فِينَا مِنۡ عُمُرِكَ سِنِينَ 18
Fir'aona sọ fun Musa ẹniti ọla nbẹ fun: se a ko tọu rẹ ni igba kekere ni, ni ọdọ wa, o si lo ọpọlọpọ ọdun ninu ọjọ ori rẹ ni ọdọ Wa, ewo lo waa pe ọ lọ si ibi ki o pe ara rẹ ni anọbi?
وَفَعَلۡتَ فَعۡلَتَكَ ٱلَّتِي فَعَلۡتَ وَأَنتَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ 19
O si tun alamọri ti o tobi nigbati o pa kibiti lati fi se aranse fun arakunrin kan ninu ijọ rẹ, o si jẹ ọkan ninu ẹniti o nja idẹkun mi ti o wa lori rẹ niyan.
Oju kokoro ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun si imọna awọn eniyan.
Fifi iroyin iyi ati ikẹ rinlẹ fun Allah.
Pipataki gbigbaaye igbaaya ati idantọ fun olupepe.
Adua awọn anọbi Ọlọhun jẹ itunisilẹ nibi ijẹru si ohun ti o yatọ si Allah.
Fir'aona fi pipaayan ti o sẹlẹ ni ọdọ Musa se ẹri lori isẹ ti a ran Musa, bẹẹni Musa si fi isẹ naa rinlẹ ni eyiti o fi mọ wa wipe kii se ẹri fun fir'aona lati pe e nirọ.