سورة (MADANIYYAH)
Ipepe lọsi ibi amumọra ati didaabo bo awọn dukia.
سُورَةٌ أَنزَلۡنَٰهَا وَفَرَضۡنَٰهَا وَأَنزَلۡنَا فِيهَآ ءَايَٰتِۢ بَيِّنَٰتٖ لَّعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ 1
Eleyi ni suura kan ti A sọkalẹ, a si se lilo awọn idajọ rẹ ni ọranyan, a si sọ awọn aayah ti o fi oju han kalẹ ninu rẹ, ni ireti ki ẹ le se iranti pẹlu ohun ti o nbẹ ninu rẹ ninu awọn idajọ, ki ẹ si lo o.
ٱلزَّانِيَةُ وَٱلزَّانِي فَٱجۡلِدُواْ كُلَّ وَٰحِدٖ مِّنۡهُمَا مِاْئَةَ جَلۡدَةٖۖ وَلَا تَأۡخُذۡكُم بِهِمَا رَأۡفَةٞ فِي دِينِ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ تُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۖ وَلۡيَشۡهَدۡ عَذَابَهُمَا طَآئِفَةٞ مِّنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 2
Alagbere lobinrin ati alagbere lọkunrin ti wọn jẹ opepe, ki ẹ yaa na ikọọkan wọn ni ẹgba ọgọrun, ki ẹ si ma mu ni rirọ tabi ikẹ fun wọn, ti ẹ ko wa nii le fi mu ofin sẹ le wọn lori, tabi fuyẹ rẹ fun wọn, ti ẹ ba jẹ olugbagbọ ninu Allah ati ọjọ ikẹyin, ki imu ofin sẹ le wọn lori jẹ ohun ti ọpọ awọn oolugbagbọ ododo yoo pe sẹ nibẹ, ni imọọmọ ifi awọn mejeeji han, ki o si le jẹ idẹrubani fun awọn mejeeji ati ẹniti o yatọ si wọn.
ٱلزَّانِي لَا يَنكِحُ إِلَّا زَانِيَةً أَوۡ مُشۡرِكَةٗ وَٱلزَّانِيَةُ لَا يَنكِحُهَآ إِلَّا زَانٍ أَوۡ مُشۡرِكٞۚ وَحُرِّمَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 3
Nitori biburu jan in agbere, Ọlọhun Allah sọ nipa ẹniti o kudun rẹ, ko gbọdọ se oju kokoro sibi igbeyawo ayaafi alagbere lobinrin gẹgẹ bii rẹ tabi ẹlẹbọ, ti ko le bọ nibi agbere pẹlu aitọ fifẹẹ, bẹẹni ẹniti o ba kundun agbere lobinrin ko gbọdọ se oju kokoro igbeyawo ayaafi si alagbere lọkunrin gẹgẹ bii rẹ tabi ẹlẹbọ, ti koo lee sọra nibẹ pẹlu jijẹ eewọ fifẹ ẹ, wọn se fifẹ alagbere lobinrin leewọ ati fifẹ alagbere lọkunrin fun awọn olugbagbọ ododo.
وَٱلَّذِينَ يَرۡمُونَ ٱلۡمُحۡصَنَٰتِ ثُمَّ لَمۡ يَأۡتُواْ بِأَرۡبَعَةِ شُهَدَآءَ فَٱجۡلِدُوهُمۡ ثَمَٰنِينَ جَلۡدَةٗ وَلَا تَقۡبَلُواْ لَهُمۡ شَهَٰدَةً أَبَدٗاۚ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ 4
Awọn ti wọn pa irọ ibajẹ mọ ninu awọn alamumọra obinrin (ati alamumọra ninu awọn ọkunrin gẹgẹ bii wọn), lẹyin naa ti wọn ko si mu ẹlẹri mẹrin wa lori irọ ibajẹ ti wọn pa, ki ẹ ya fun wọn lẹgba - ẹyin oludajọ - ni ẹgba ọgọrin, ki ẹ si mase gba ẹlẹri wọn kankan lailai, awọn alamumọra ti wọn pa irọ mọ yii ni awọn ti wọn jade kuro nibi itẹle ti Allah.
إِلَّا ٱلَّذِينَ تَابُواْ مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ وَأَصۡلَحُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 5
Ayaafi awọn ti wọn ba ronu piwada lọsi ọdọ Allah lẹyin eyi ti wọn ti gbawaju sibẹ ninu eleyi, ti wọn si se atunse isẹ wọn, dajudaju Allah yoo gba ironu piwada wọn ati ijẹri wọn, dajudaju Allah jẹ alaforijin fun ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, O si tun jẹ Onikẹ si wọn.
وَٱلَّذِينَ يَرۡمُونَ أَزۡوَٰجَهُمۡ وَلَمۡ يَكُن لَّهُمۡ شُهَدَآءُ إِلَّآ أَنفُسُهُمۡ فَشَهَٰدَةُ أَحَدِهِمۡ أَرۡبَعُ شَهَٰدَٰتِۢ بِٱللَّهِ إِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ 6
Awọn ọkunrin ti wọn parọ ibajẹ mọ iyawo wọn, ti ko si si awọn ẹlẹri fun wọn ju ara wọn lọ, ti yoo jẹri lori lilaafia irọ ti wọn pa mọ wọn; ẹnikan yoo jẹri ninu wọn ni ijẹri mẹrin pẹlu Allah: dajudaju olododo ni oun nibi ohun ti o parọ rẹ mọ iyawo rẹ ni agbere.
وَٱلۡخَٰمِسَةُ أَنَّ لَعۡنَتَ ٱللَّهِ عَلَيۡهِ إِن كَانَ مِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ 7
Lẹyin naa nibi ijẹri rẹ karun, yoo se alekun epe le ara rẹ lori pẹlu lilẹtọ si ijinna si ikẹ Allah ti o ba jẹ opurọ nibi ohun ti o fi kan iyawo rẹ.
وَيَدۡرَؤُاْ عَنۡهَا ٱلۡعَذَابَ أَن تَشۡهَدَ أَرۡبَعَ شَهَٰدَٰتِۢ بِٱللَّهِ إِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ 8
Bayi ni obinrin naa yoo lẹtọ si ifiyajẹni lori agbere sise, ohun ti yoo mu eleyi kuro fun un niki o jẹri ni ijẹri mẹrin pẹlu Allah: dajudaju oun jẹ opurọ nibi ohun ti o sọ si i.
وَٱلۡخَٰمِسَةَ أَنَّ غَضَبَ ٱللَّهِ عَلَيۡهَآ إِن كَانَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ 9
Lẹyin naa nibi ijẹri rẹ ẹlẹkaarun, yoo se alekun epe le ara rẹ lori pẹlu ibinu Allah le lori ti o ba jẹ sootọ sootọ nibi ohun ti o sọ si i.
وَلَوۡلَا فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَرَحۡمَتُهُۥ وَأَنَّ ٱللَّهَ تَوَّابٌ حَكِيمٌ 10
Ti kii ba se isọla Allah le yin lori - ẹyin eniyan - ati ikẹ Rẹ fun yin ati wipe dajudaju Oun jẹ olugba ironu piwada lọwọ ẹniti o ba sẹri pada waa ba ninu ẹru Rẹ, Ọjọgbọ ni O si jẹ nibi idari eto Rẹ ati ofin Rẹ, ko ba ti kanju fi iya jẹ yin lori awọn ẹsẹ yin, ki ba si doju ti yin pẹlu rẹ.
Bibẹrẹ ọrọ lori awọn alamọri ti o tobi wa ninu ohun ti o mu ni mọ titobi Rẹ.
Alagbere lọkunrin padanu apọnle ati ikẹ ni awujọ Musulumi.
Ifunlẹmọni awujọ lori awọn alagbere jẹ ọna idaabobo fun awujọ kuro ni ọdọ wọn, ati ojupọnna idẹruba kuro nibi agbere.
Sise oniranran iya fun ẹniti o parọ agbere mọ eniyan debi ijiya ifuramọ (haddu) ati aifojuri (dida ijẹri rẹ pada ati sise idajọ poki le lori) jẹ itọka lori ewu isẹ yii.
Agbere ko fi ẹsẹ rinlẹ ayaafi pẹlu aridaju, pipe apemọra rẹ laisi i jẹ iparọmọni.