سورة (MAKIYYAH)
Sise ifirinlẹ isẹ ati alaye ijọkan soso erongba awọn anabi ati ini akolekan Ọlọhun Ọba siwọn
ٱقۡتَرَبَ لِلنَّاسِ حِسَابُهُمۡ وَهُمۡ فِي غَفۡلَةٖ مُّعۡرِضُونَ 1
Isiro isẹ awọn ẹniyan ni ọjọ igbende ti sun mọ, wọn si wa ninu ifọnu ni ẹniti o ngunri kuro nibi ọjọ ikẹyin; nitori kiko airoju pẹlu aye kuro nibẹ.
مَا يَأۡتِيهِم مِّن ذِكۡرٖ مِّن رَّبِّهِم مُّحۡدَثٍ إِلَّا ٱسۡتَمَعُوهُ وَهُمۡ يَلۡعَبُونَ 2
Nkankan ko ni waa ba won ninu Alukuraani lati ọdọ Ọlọhun Ọba wọn ninu ọrọ ti o sọkalẹ ayaafi ki wọn gbọ ni gbigbọ ti ko le se anfaani, bikosepe gbigbọ ere ni ẹniti ko nii ka a kun.
لَاهِيَةٗ قُلُوبُهُمۡۗ وَأَسَرُّواْ ٱلنَّجۡوَى ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ هَلۡ هَٰذَآ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُكُمۡۖ أَفَتَأۡتُونَ ٱلسِّحۡرَ وَأَنتُمۡ تُبۡصِرُونَ 3
Wọn gbọ ọ, ọkan wọn si fọnu kuro nibẹ, awọn alabosi ti se afipamọ ọrọ keferi eyiti wọn nsọ kẹlẹ kẹlẹ ni ẹniti o nsọ bayi wipe: se eleyi ni o npe ara rẹ ni ojisẹ, bikosepe abara bii ti yin ni, ko si asayan fun un ju yin lọ?! Ohun ti o si mu wa jẹ idan, se ẹyin yoo tẹle bi nigbati ẹ ti mọ wipe abara bi ti yin ni, ati wipe dajudaju ohun ti o mu wa jẹ idan?!
قَالَ رَبِّي يَعۡلَمُ ٱلۡقَوۡلَ فِي ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ 4
Ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun sọpe: Ọlọhun mi mọ ohun ti ẹ fi pamọ ninu ọrọ, Oun si mọ gbogbo gbolohun eyiti o ba jade lati ọdọ olusọ ọ ni sanmọ ni tabi ilẹ, Oun si jẹ olugbọ gbogbo ọrọ ẹru Rẹ, onimimọ si gbogbo isẹ wọn, yoo si san wọn lẹsan le lori.
بَلۡ قَالُوٓاْ أَضۡغَٰثُ أَحۡلَٰمِۢ بَلِ ٱفۡتَرَىٰهُ بَلۡ هُوَ شَاعِرٞ فَلۡيَأۡتِنَا بَِٔايَةٖ كَمَآ أُرۡسِلَ ٱلۡأَوَّلُونَ 5
Bikosepe wọn npaara nipa isesi ohun ti Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun mu wa, ni asiko miran wọn sọ wipe: ala ti o lu mọ ara wọn ni, ti ko ni alaye, wọn si tun wi ni asiko miran: rara bikosepe wọn hun ni, ni eyiti ko ni ipilẹ, wọn si tun sọ ni igba miran: oun jẹ kọrin kọrin, koda bi o jẹ olododo nibi ohun ti o npe apemọra rẹ, ki o ya mu isẹ iyanu wa gẹgẹ bi ti awọn ẹni akọkọ ninu awọn ojisẹ naa, paapa wọn ti mu awọn isẹ iyanu wa gẹgẹ bi ọpa Musa ati rakunmi Sọlihu.
مَآ ءَامَنَتۡ قَبۡلَهُم مِّن قَرۡيَةٍ أَهۡلَكۡنَٰهَآۖ أَفَهُمۡ يُؤۡمِنُونَ 6
Abule kan ko gbagbọ siwaju awọn oluda adapa irọ, wọn mu ọrọ sisọ kalẹ awọn aayah wa, bẹẹni wọn fun wọn gẹgẹ bi wọn se wi i, bikosepe wọn pe e nirọ Awa naa si pa wọn run, se awọn wọnyi yoo nigbagbọ bi?!
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا قَبۡلَكَ إِلَّا رِجَالٗا نُّوحِيٓ إِلَيۡهِمۡۖ فَسَۡٔلُوٓاْ أَهۡلَ ٱلذِّكۡرِ إِن كُنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ 7
A ko gbe dide siwaju rẹ - irẹ ojisẹ - ayaafi awọn okunrin ninu abara ti A nransẹ imisi si, a ko gbe wọn dide ni Malaika, ki ẹ yaa bi awọn ti a fun ni tira siwaju yin ti ẹyin ko ba mọ eleyi.
وَمَا جَعَلۡنَٰهُمۡ جَسَدٗا لَّا يَأۡكُلُونَ ٱلطَّعَامَ وَمَا كَانُواْ خَٰلِدِينَ 8
Awa ko se awọn ojisẹ ti a ran nisẹ ni abara ti ko lee jẹun bikosepe wọn njẹ gẹgẹ bi awọn ti o yatọ si wọn naa se njẹ, kii sii sepe wọn jẹ ẹniti yoo sẹku laye ti wọn ko nii ku.
ثُمَّ صَدَقۡنَٰهُمُ ٱلۡوَعۡدَ فَأَنجَيۡنَٰهُمۡ وَمَن نَّشَآءُ وَأَهۡلَكۡنَا ٱلۡمُسۡرِفِينَ 9
Lẹyin naa a sọ erongba awọn ojisẹ wa di ododo lori ohun ti a se ni adehun fun wọn nitori wipe a la wọn, a si la awọn ti o wu Wa ninu awọn olugbagbọ ododo kuro nibi iparun, a si tun la awọn olukọja ẹnu aala nibi sise keferi wọn si Allah, ati gigunle ẹsẹ wọn.
لَقَدۡ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكُمۡ كِتَٰبٗا فِيهِ ذِكۡرُكُمۡۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ 10
Paapa ati sọ Alukuraani kalẹ fun yin, ti iyi yin ati iyanran yin wa nibẹ ti ẹ ba sọ ododo pẹlu rẹ, ti ẹ si nse ohun ti o wa ninu rẹ se ẹ ko se laakaye eleyi ni, ki ẹ ya yara lọsi ibi nini igbagbọ si I ati lilo ohun ti ko sinu?!
Sisunmọ ọjọ igbende jẹ ohun ti imura silẹ fun un jẹ dandan.
Kiko airoju ọkan pẹlu ere ma ngbe kuro nibi ododo.
Rirọkirika imọ Allah wa pẹlu gbolohun tabi isẹ ti njade ni ọdọ awọn ẹru Rẹ.
Iyapa awọn ẹlẹbọ nibi ibuduro wọn si Anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun tọka si itẹsẹ bọsẹ wọn ati idaru dapọ wọn.
Dajudaju Allah wa pẹlu awọn ojisẹ Rẹ ati awọn olugbagbọ ododo niti ikunlọwọ ati aanu lori awọn ọta.
Alukuraani jẹ iyi ati ogo fun ẹniti o ba gba a gbọ ti o si nlo.