سورة (MADANIYYAH)
Mimu sise adari ori ilẹ sẹ pẹlu gbigbe ẹsin Islam duro ati jijupa jusẹ silẹ fun Ọlọhun, ati sisọra nibi isesi awọn ọmọ Isrẹli.
Wọn npe Suratul Baqọrah ni orukọ yii nitori itan Maalu awọn bani Isiraiila ti o waye ninu rẹ, o si nbẹ ninu rẹ, itọkasi jijẹ dandan mima sare tete lọsi ibi mimu ofin Ọlọhun Allah wa si imusẹ, ati mima fa si ẹyin nibẹ gẹgẹ bi o se sẹlẹ lati ọdọ awọn Yahuudi.
الٓمٓ 1
(الٓمٓ) awọn ọrọ ẹlẹyọẹọyọ yii eyiti wọn fi bẹrẹ apakan awọn suurah Alukuraani, ohun ni awọn ‘aarafi’ ipilẹ ede larubawa, ti ko si itumọ fun un ni igba ti o ba dawa ni ẹyọ-ẹyọ gẹgẹ bii (Alif, baa, taa......) . o si nbẹ fun awọn idi ati erongba kan nitori wipe ko si nkankan kan ninu Alukuraani ti ko ni idi tabi erongba ti o fi waye, ninu awọn idi pataki fun wiwa awọn aarafi yii, ohun ni itọkasi lọsi ibi pipe wọn nija Alukuraani, eyiti o ko jọ lati inu awọn ‘aarafi’ eyiti wọn mọ, ti wọn si tun fi nsọ ọrọ; latari eyi, o ma nwa lẹyin rẹ ni ọpọlọpọ igba isọrọ nipa Alukuraani Alapọnle naa gẹgẹ bi o ti wa ninu Suurah yii.
ذَٰلِكَ ٱلۡكِتَٰبُ لَا رَيۡبَۛ فِيهِۛ هُدٗى لِّلۡمُتَّقِينَ 2
Alukuraani ti o tobi yii, ko si iyemeji nibẹ, nibi isọkalẹ rẹ ni ati nibi awọn gbolohun rẹ ati iyumọ rẹ, o si jẹ ọrọ Ọlọhun Allah ti o ma nfi awọn olupaya Ọlọhun Allah mọ ọna lọ si oju ọna ti yoo mu wọn de ọdọ Rẹ.
ٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡغَيۡبِ وَيُقِيمُونَ ٱلصَّلَوٰةَ وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ 3
Awọn ti wọn jẹ wipe wọn ni igbagbọ ninu kọkọ, ohun ni gbogbo nkan ti ako le ni ifura mọ, ti so pamọ fun wa, ninu awọn nkan ti Ọlọhun Allah iro wa nipa rẹ tabi lati ọdọ Ojisẹ Rẹ, gẹgẹ bi Ọjọ ikẹyin. Awọn wọnyi si ma ngbe irun wọn duro pẹlu mima mu wa ni ibamu si ofin Ọlọhun Allah ninu awọ majẹmu rẹ, awọn origun rẹ, awọn ọranyan rẹ, ati awọn asegbọrẹẹ bẹ.awọn wọnyi si ma nna ninu ohun ti Ọlọhun Allah ba se ni ọrọ fun wọn nipa mimu ọranyan jade gẹgẹ bii ‘Saka’ yiyọ, tabi ohun ti kii se ọranyan gẹgẹ bii asegbọrẹ; ni ẹni ti nrankan ẹsan Ọlọhun Alla; awọn wọnyi si ma nni igbagbọ si isẹ iransẹ eyi ti Ọlọhun Alla sọkalẹ fun wọn – Irẹ Anọbi ati eyi ti a sọkalẹ fun awọn Anọbi yoku (ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn) siwaju rẹ laini si onpiya, awọn wọnyi si ma nni igbagbọ ti o fẹsẹ mulẹ nipa ọjọ ikẹyin ati awọn nkan ti nbẹ nibẹ nipa ẹsan tabi iya.
وَٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ وَمَآ أُنزِلَ مِن قَبۡلِكَ وَبِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ يُوقِنُونَ 4
Awọn ti wọn jẹ wipe wọn ni igbagbọ ninu kọkọ, ohun ni gbogbo nkan ti ako le ni ifura mọ, ti so pamọ fun wa, ninu awọn nkan ti Ọlọhun Allah iro wa nipa rẹ tabi lati ọdọ Ojisẹ Rẹ, gẹgẹ bi Ọjọ ikẹyin. Awọn wọnyi si ma ngbe irun wọn duro pẹlu mima mu wa ni ibamu si ofin Ọlọhun Allah ninu awọ majẹmu rẹ, awọn origun rẹ, awọn ọranyan rẹ, ati awọn asegbọrẹẹ bẹ.awọn wọnyi si ma nna ninu ohun ti Ọlọhun Allah ba se ni ọrọ fun wọn nipa mimu ọranyan jade gẹgẹ bii ‘Saka’ yiyọ, tabi ohun ti kii se ọranyan gẹgẹ bii asegbọrẹ; ni ẹni ti nrankan ẹsan Ọlọhun Alla; awọn wọnyi si ma nni igbagbọ si isẹ iransẹ eyi ti Ọlọhun Alla sọkalẹ fun wọn – Irẹ Anọbi ati eyi ti a sọkalẹ fun awọn Anọbi yoku (ki ọla Ọlọhun o maa ba wọn) siwaju rẹ laini si onpiya, awọn wọnyi si ma nni igbagbọ ti o fẹsẹ mulẹ nipa ọjọ ikẹyin ati awọn nkan ti nbẹ nibẹ nipa ẹsan tabi iya.
أُوْلَٰٓئِكَ عَلَىٰ هُدٗى مِّن رَّبِّهِمۡۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ 5
Awọn ti a fi iroyin yii royin, wọn wa ni pipe ni oju ọna imọna, awọn ẹniti yoo jere ni aye ati ọjọ ikẹyin pẹlu pe ki ọwọ wọn tẹ ohun ti wọn nse irankan rẹ, ati lila kuro nibi ohun ti wọn npaya.
Ifọkantan pọnbele nibi kikọ iyemeji, itọka ni o jẹ lori wipe Alukuraani jẹ ohun ti o wa lati ọdọ Ọlọhun Allah, nigbati o jẹ wipe ko rọrun fun ẹda kan ko pe Alukuraani ni ọrọ tirẹ.
Ko le se anfaani pẹlu ohun ti nbẹ ninu Alukuraani Alapọnle ninu imọna ti o tobi ayaafi olupaya Ọlọhun Allah (ti Ọla Rẹ ga) , ti wọn si ngbe Ọlọhun Allah ni titobi.
Ninu awọn eyi ti o tobi nibi ipilẹ igbagbọ, ni nini igbagbọ si ikọkọ, nitori wipe o ko sinu ijuwọjusẹ silẹ fun Ọlọhun Allah (ti Ọla Rẹ ga) nibi gbogbo nkan ti Oun nikan ni imọ nipa rẹ ninu imọ ikọkọ, ati fun Ojisẹ Rẹ nipa ohun ti O sọ nipa rẹ.
Ni ọpọlọpọ igba, Ọlọhun Allah ma nso Saka yiyọ papọ mọ Irun kiki; nitori wipe Irun kiki ni sise afọmọ ẹni ti a nsin; ti Saka yiyọ si jẹ sise daradara si ẹrusin, nkan mejeeji yii ni akọle oriire ati iyege.
Nini igbagbọ pẹlu Ọlọhun Allah (ti Ọla Rẹ ga) ati mima se isẹ oloore, nkan mejeeji yii ma njogun imọna ati kongẹ sise ni ile aye ati ere jijẹ pẹlu lila ni ọjọ ikẹyin.