سورة (MAKIYYAH)
Sise alaye ihan gbangba ikẹ Allah si awọn ẹnii Rẹ gẹgẹ bi itanilọrẹ ọmọ rere, ati mimọ kanga Rẹ kuro nibi ọmọ ati oluranlọwọ, ni ida ọrọ pada si awọn opurọ.
كٓهيعٓصٓ 1
(كٓهيعٓصٓ) (Kaf Ha Ya ‘Aen Sọd), ọrọ ti gbawaju lori iru rẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọrah.
ذِكۡرُ رَحۡمَتِ رَبِّكَ عَبۡدَهُۥ زَكَرِيَّآ 2
Eleyi ni iranileti Ọlọhun Ọba rẹ lori ẹru Rẹ Sakariyah ti ọla nbẹ fun, a sọ fun ọ ki o le woye pẹlu rẹ.
إِذۡ نَادَىٰ رَبَّهُۥ نِدَآءً خَفِيّٗا 3
Nigbati o pe Ọlọhun Ọba rẹ ti mimọ nbẹ fun ni pipe jẹẹjẹẹ ki o le ba sun mọ gbigba.
قَالَ رَبِّ إِنِّي وَهَنَ ٱلۡعَظۡمُ مِنِّي وَٱشۡتَعَلَ ٱلرَّأۡسُ شَيۡبٗا وَلَمۡ أَكُنۢ بِدُعَآئِكَ رَبِّ شَقِيّٗا 4
O sọ wipe: irẹ Ọlọhun mi, eegun mi ti lẹ, irun funfun ori mi si ti pọ, emi ko si jẹ ẹniti o padanu nibi adua mi si ọ bikosepe gbogbo igba ti mo ba npe ọ ni o ma njẹ Mi.
وَإِنِّي خِفۡتُ ٱلۡمَوَٰلِيَ مِن وَرَآءِي وَكَانَتِ ٱمۡرَأَتِي عَاقِرٗا فَهَبۡ لِي مِن لَّدُنكَ وَلِيّٗا 5
Bẹẹni dajudaju emi npaya isunmọ mi si ọ, ki wọn ma dide lẹyin iku mi pẹlu ododo ẹsin nitori kiko airoju pẹlu aye wọn, iyawo mi si jẹ agan ti ko bi mọ fun mi lati ọdọ Rẹ ti yoo jẹ oluranlọwọ.
يَرِثُنِي وَيَرِثُ مِنۡ ءَالِ يَعۡقُوبَۖ وَٱجۡعَلۡهُ رَبِّ رَضِيّٗا 6
Ti yoo jẹ ogun ijẹ Anọbi lọwọ mi, ti yoo jogun rẹ lati ọdọ ara ile ya'quuba ẹniti ọla nbẹ fun, ki o si sọ ọ di - irẹ Ọlọhun mi - ẹni iyọnu nibẹ ẹsin, ẹda rẹ ati imọ rẹ.
يَٰزَكَرِيَّآ إِنَّا نُبَشِّرُكَ بِغُلَٰمٍ ٱسۡمُهُۥ يَحۡيَىٰ لَمۡ نَجۡعَل لَّهُۥ مِن قَبۡلُ سَمِيّٗا 7
Ọlọhun Ọba Allah si jẹpe adua rẹ, O wa pe e: irẹ Sakariya, Awa yoo fun ọ ohun ti yoo dun ọ ninu, paapaa a ti jẹpe adua rẹ, a si fun ọ ni ọmọkunrin ti orukọ rẹ njẹ yahya, a ko fun ẹlomiran siwaju rẹ ni orukọ yii.
قَالَ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَٰمٞ وَكَانَتِ ٱمۡرَأَتِي عَاقِرٗا وَقَدۡ بَلَغۡتُ مِنَ ٱلۡكِبَرِ عِتِيّٗا 8
Zakariya sọ niti sise eemọ nipa agbara Allah: bawo wọn se le bimọ fun mi, ti iyawo mi si jẹ agan ti ko le bimọ, paapaa mo ti de opin ọjọ ori agba, bẹẹni eegun si ti di ọlẹ?!
قَالَ كَذَٰلِكَ قَالَ رَبُّكَ هُوَ عَلَيَّ هَيِّنٞ وَقَدۡ خَلَقۡتُكَ مِن قَبۡلُ وَلَمۡ تَكُ شَيۡٔٗا 9
Malaika sọpe: bọrọ se ri bi o se sọ wipe obinrin rẹ ko le bimọ ati wipe dajudaju o ti de opin nibi ọjọ ori agba, bẹẹni eegun si ti di ọlẹ, sugbọn Ọlọhun Ọba rẹ sọpe: dida Ọlọhun Ọba rẹ fun yahya lati iya agọn ati lati ara baba ti ọjọ ori rẹ ti dopin rọrun, paapaa Mo si ti da ọ - irẹ Zakariya - siwaju eleyi, ti o ko jẹ nkankan ti a le sọ; nitoripe o wa ni aisi.
قَالَ رَبِّ ٱجۡعَل لِّيٓ ءَايَةٗۖ قَالَ ءَايَتُكَ أَلَّا تُكَلِّمَ ٱلنَّاسَ ثَلَٰثَ لَيَالٖ سَوِيّٗا 10
Zakariya ẹniti ọla nbẹ fun sọpe: irẹ Ọlọhun mi, se amin kan fun mi, ti ọkan mi yoo fi balẹ, ti yoo tọka si titẹlọwọ ohun ti awọn Malaika fun mi ni iro idunnu rẹ, o sọ wipe: amin rẹ lori titẹlọwọ ohun ti wọn fun ọ ni iro idunnu rẹ ni ki o ma le ba awọn eniyan sọrọ ni oru mẹta laisi idi bikosepe iwọ jẹ ẹniti o ni alaafia ti ko ni arun lara.
فَخَرَجَ عَلَىٰ قَوۡمِهِۦ مِنَ ٱلۡمِحۡرَابِ فَأَوۡحَىٰٓ إِلَيۡهِمۡ أَن سَبِّحُواْ بُكۡرَةٗ وَعَشِيّٗا 11
Zakariya jade si awọn ijọ rẹ lati ibi aaye ijọsin rẹ, o si tọka fun wọn laisi ọrọ nibẹ: wipe ki ẹ se afọmọ Allah ti mimọ nbẹ fun ni ọsan ati ni igbẹyin rẹ.
Lilẹ ati kikagara wa ninu ọna ti Allah nifẹ si lati se itẹgun si ọdọ Rẹ; nitoripe o tọka si mimọ kanga kuro nibi ete ati agbara ati siso ọkan mọ ete Ọlọhun Ọba ati agbara Rẹ.
Wọn fẹ fun ọmọniyan ko o ranti idẹkun Allah ti o ga le lori nibi adua rẹ, ati itẹriba ti o tọ.
Sise oju kokoro si anfaani ẹsin ati titi i siwaju ekikeyi awọn anfaani miran lọ.
Wọn fẹ awọn orukọ ti o nitumọ ti o dara.