سورة (MAKIYYAH)
Sise adehun iya fun awọn ti nfi Quran se yẹyẹ, ati adehun ẹsan pẹlu sisọ rẹ ni sise atilẹyin fun anabi ati fifirinlẹ fun.
الٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ وَقُرۡءَانٖ مُّبِينٖ 1
(الٓر) (Alif Lam Rọọ) ọrọ ti gbawaju lori apejuwe iru rẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọra, awọn aayah yii jẹ ohun ti ipo rẹ ga, eyiti ntọka si sisọkalẹ rẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba, ohun naa ni awọn aayah Alukuraani ti nse alaye awọn ijọkansoso ati awọn ofin.
رُّبَمَا يَوَدُّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَوۡ كَانُواْ مُسۡلِمِينَ 2
Awọn keferi yoo maa rankan ni ọjọ igbende bii mi wọn jẹ Musulumi nigbati awọn alamọri ba han si wọn, ti aidara sise keferi wọn ni ile aye si fi oju han si wọn.
ذَرۡهُمۡ يَأۡكُلُواْ وَيَتَمَتَّعُواْ وَيُلۡهِهِمُ ٱلۡأَمَلُۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ 3
Fi silẹ - irẹ ojisẹ - awọn olupurọ ti wọn njẹun gẹgẹ bi awọn ẹranko se njẹun, ti wọn si ngbadun awọn adun ile aye eyiti yoo tan, tii gigun erongba si mu airoju ba wọn lati ma ni igbagbọ ati isẹ rere, wọn yoo pada mọ ofo eyiti wọn wa ninu rẹ nigbati wọn ba mu wọn wa si ọdọ Ọlọhun Ọba ni ọjọ igbende.
وَمَآ أَهۡلَكۡنَا مِن قَرۡيَةٍ إِلَّا وَلَهَا كِتَابٞ مَّعۡلُومٞ 4
A ko sọ iparun kalẹ lori abule kan ninu awọn abule alabosi ayaafi ki o ni asiko pato ninu imọ Ọlọhun Ọba Allah, ko le gba iwaju rẹ, bẹẹ ni ko lọra.
مَّا تَسۡبِقُ مِنۡ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسۡتَٔۡخِرُونَ 5
Iparun ijọ kan ninu awọn ijọ ko nii de siwaju asiko rẹ, bẹẹ ni iparun rẹ ko nii lọra nigbati asiko rẹ ba to, ki awọn alabosi mase gba itanjẹ pẹlu didẹ wọn lẹkẹ Ọlọhun Ọba Allah.
وَقَالُواْ يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِي نُزِّلَ عَلَيۡهِ ٱلذِّكۡرُ إِنَّكَ لَمَجۡنُونٞ 6
Awọn ara Mekkah sọ fun ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun: a pe iwọ ti a sọ iranti naa kalẹ fun - gẹgẹ bi o se npe apemọra rẹ - dajudaju, o jẹ ẹniti oriirẹ ti daru pẹlu ohun ti o npe apemọra rẹ yii, o nse isesi awọn were.
لَّوۡ مَا تَأۡتِينَا بِٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ 7
Se iwọ ko le mu awọn Malaika waa fun wa ti yoo jẹri gbe ọ, ti o ba jẹpe otitọ ni o nsọ wipe anabi ti wọn ran ni ẹ, ati wipe iya yoo sọ kalẹ ti wa.
مَا نُنَزِّلُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَمَا كَانُوٓاْ إِذٗا مُّنظَرِينَ 8
Ọlọhun Ọba Allah sọrọ ni ẹniti o nfesi lori imọran wiwa awọn Malaika: a ko le sọ awọn Malaika kalẹ ayaafi ni ibamun si ọgbọn ti o tọ nigbati asiko pipa yin run pẹlu iya ba to, wọn kii se ẹni ilọlara - nigbati a ba mu Malaika wa, ti wọn ko si nigbagbọ - bikose wipe wọn yoo kanju fi iya jẹ wọn.
إِنَّا نَحۡنُ نَزَّلۡنَا ٱلذِّكۡرَ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَٰفِظُونَ 9
Awa ni ẹniti o sọ Alukuraani kalẹ si ọkan Muhammad ẹniti ọla nbẹ fun ni iranti fun awọn ẹniyan, bẹẹ ni awa ni olusọ Alukuraani nibi alekun ati ẹdinku ati ipaarọ ati ipalofo.
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ فِي شِيَعِ ٱلۡأَوَّلِينَ 10
Paapaa, a ti dide siwaju tirẹ -ire ojise- awọn ojisẹ ninu awọn keferi ti o ti siwaju, sugbọn wọn pe wọn nirọ, iwọ kii se ipilẹ ninu awọn ojisẹ nibi ki awọn ijọ rẹ pe ọ nirọ.
وَمَا يَأۡتِيهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ 11
Ojisẹ kan ko nii wa ba awọn ijọ keferi ti o ti siwaju ayaafi ki wọn pe e nirọ, ki wọn si fi se yẹyẹ.
كَذَٰلِكَ نَسۡلُكُهُۥ فِي قُلُوبِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ 12
Gẹgẹ bi A se fi ipeninirọ si inu ọkan awọn ijọ naa, gẹgẹ bẹẹ naa ni A fi si ọkan awọn ẹlẹbọ Mẹka nitori igunri wọn ati isorikunkun wọn.
لَا يُؤۡمِنُونَ بِهِۦ وَقَدۡ خَلَتۡ سُنَّةُ ٱلۡأَوَّلِينَ 13
Wọn ko niini igbagbọ si Muhammad ẹniti ikẹ ati ọla nbẹ fun, paapaa isesi Ọlọhun Ọba ti re kọja nibi mimu iparun ba awọn ti wọn npe ohun ti awọn ojisẹ wọn mu wa nirọ, ki awọn ti wọn npe ọ nirọ yaa ri ariwoye nibẹ.
وَلَوۡ فَتَحۡنَا عَلَيۡهِم بَابٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ فَظَلُّواْ فِيهِ يَعۡرُجُونَ 14
Awọn opurọ yii tun jẹ olori kunkun koda bi ododo pẹlu ẹri ti o fi oju han ba hande si wọn, koda bi A si ilẹkun sanmọ fun wọn, wọn yoo wa ni ẹniti yoo maa gun oke lọ.
لَقَالُوٓاْ إِنَّمَا سُكِّرَتۡ أَبۡصَٰرُنَا بَلۡ نَحۡنُ قَوۡمٞ مَّسۡحُورُونَ 15
Ti wọn ba sọ ootọ, wọn ko ba tun sọ wipe: wọn di wa loju ni lati riran koda a ko rii wipe o jẹ oripa idan tori wipe a ti di ẹniti idan ti mu.
Alukuraani Alapọnle jẹ ohun ti o ko iroyin pipe nibi gbogbo nkan sinu ati fifi oju han pẹlu alaye.
Awọn keferi ni ọpọ igbọ ma nka awọn nkan ti o se fi oju ri kun, ni iwọ yoo fi ri wọn ni ẹniti yoo ti tẹri si awọn adun ati ifẹ inu, ti wọn yoo si tun gba itanjẹ pẹlu awọn erongba ti yoo pada tan, ti wọn yoo si ko iroju pẹlu aye kuro nibi ọrun.
Iparun awọn ijọ jẹ ohun ti a ti pebubu pẹlu asiko pato, ati ohun ti a ti seto si asiko ti a ti fi aala si, ko si ilọlara nibẹ tabi gbigba iwaju, bẹẹ ni Allah kii kanju nitori ikanju ẹnikan.
Ọlọhun Ọba Allah ti o ga julọ la isọ Alukuraani Alapọnle bọ ọrun kuro nibi iyipada ati ipaarọ ati alekun ati ẹdinku titi di ọjọ igbende.