سورة (MADANIYYAH)
Dida ọrọ pada si enu awọn ti wọn ko imisi ati ije anọbi pelu sise alaye awọn afihan agbara Ọlọhun Ọba.
الٓمٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِۗ وَٱلَّذِيٓ أُنزِلَ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَ ٱلۡحَقُّ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يُؤۡمِنُونَ 1
(الٓمٓ)رۚ (Alif, Lam, Mim, Rọọ) ọrọ ti siwaju lori iru rẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọrah, eleyi ni awọn aayah ti o ga ninu ọgba ọrọ naa, ati alukuraani eyiti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ fun ọ - irẹ ojisẹ - ohun ni ododo eyiti ko si iyemeji nibẹ, ko si si iyemeji nibi wipe ọdọ Ọlọhun Ọba ni o ti wa sugbọn ọpọ ninu awọn eniyan ko nigbagbọ si i niti isori kunkun ati igberaga.
ٱللَّهُ ٱلَّذِي رَفَعَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ بِغَيۡرِ عَمَدٖ تَرَوۡنَهَاۖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ وَسَخَّرَ ٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ كُلّٞ يَجۡرِي لِأَجَلٖ مُّسَمّٗىۚ يُدَبِّرُ ٱلۡأَمۡرَ يُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّكُم بِلِقَآءِ رَبِّكُمۡ تُوقِنُونَ 2
Ọlọhun Allah ni O da gbogbo sanmọ ni ohun ti o ga ti ko si awọn opo kankan ti ẹyin na nri, lẹyin igba naa o ga, o si leke ikẹ Rẹ niti giga ti o tọ si I mimọ Rẹ laisọ bi o se ri ati apejuwe Rẹ, O si rọ oorun ati osupa fun anfaani ẹda Rẹ, oorun tabi osupa nlọ fun igba ti o ni aala ninu imọ Ọlọhun Allah, Ọba ti mimọ nbẹ fun ndari asẹ Rẹ ni gbogbo sanmọ ati ilẹ pẹlu bi o se wu U, O nsalaye awọn amin ti o ntọka si agbara Rẹ ni ireti ki ẹ le ba mọ amọdaju pipade Ọlọhun Ọba yin ni ọjọ igbende ki ẹ le ba fi isẹ rere mura silẹ fun un.
وَهُوَ ٱلَّذِي مَدَّ ٱلۡأَرۡضَ وَجَعَلَ فِيهَا رَوَٰسِيَ وَأَنۡهَٰرٗاۖ وَمِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِ جَعَلَ فِيهَا زَوۡجَيۡنِ ٱثۡنَيۡنِۖ يُغۡشِي ٱلَّيۡلَ ٱلنَّهَارَۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ 3
Oun ti mimọ nbẹ fun ni ẹniti o tẹ ilẹ, O si da oke si i ni ifirinlẹ rẹ ti ko fi nii maa min mọ awọn eniyan, O si fi awọn ibudo sibẹ ki awọn eniyan le ma mu, awọn ẹranko ati awọn oun ọgbin, ati awọn oniranran awọn eso, O fi iran meji si i gẹgẹ bi akọ ati abo ninu awọn ẹranko, O fi oru bo ọsan ti yoo di okunkun lẹyin igbati o ti tan imọlẹ, dajudaju nibi eleyi ti a sọ yii ẹri ni o jẹ ati awọn awijare fun ijọ ti o nronu si isẹ Ọlọhun Allah, ti o si nronu jinlẹ nipa rẹ, awọn ni ẹniti yoo se anfaani pẹlu awọn ẹri ati awọn awijare.
وَفِي ٱلۡأَرۡضِ قِطَعٞ مُّتَجَٰوِرَٰتٞ وَجَنَّٰتٞ مِّنۡ أَعۡنَٰبٖ وَزَرۡعٞ وَنَخِيلٞ صِنۡوَانٞ وَغَيۡرُ صِنۡوَانٖ يُسۡقَىٰ بِمَآءٖ وَٰحِدٖ وَنُفَضِّلُ بَعۡضَهَا عَلَىٰ بَعۡضٖ فِي ٱلۡأُكُلِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ 4
O si wa ni ori ilẹ awọn aaye ti o sun mọ ara wọn, bẹẹ ni o wa nibẹ awọn oko eso inabi ati awọn nkan ọgbin ati awọn ọpẹ ti o parapọ ni ipilẹ ẹyọkan soso ati awọn ọpẹ ti wọn da wa ni ipilẹ wọn, wọn nfun awọn oko yii ati awọn ọgbin naa ni omin kan soso mu, a si gbọla fun apakan rẹ lori apakan nibi itọwo awọn nkan ti o yatọ si ninu awọn anfaani laigboju wo sisun mọ wọn ati fifun lomin kan soso, dajudaju nibi eleyi ti a sọ yii jẹ awọn ẹri ati awọn awijare fun ijọ ti o ni laakaye; toripe awọn ni yoo woye si i.
۞وَإِن تَعۡجَبۡ فَعَجَبٞ قَوۡلُهُمۡ أَءِذَا كُنَّا تُرَٰبًا أَءِنَّا لَفِي خَلۡقٖ جَدِيدٍۗ أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِرَبِّهِمۡۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ ٱلۡأَغۡلَٰلُ فِيٓ أَعۡنَاقِهِمۡۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ 5
Ti o ba seemọ - irẹ ojisẹ - nibi nkan ohun ti o tọ ki o se eemọ rẹ ju ni irọ ti wọn npe ọjọ igbende ati gbolohun wọn lati fi se ẹri titako o: se ti a ba ku ti a si di yeepẹ ati egungun ti o ti kẹfun, se wọn yoo gbe wa dide, ti wọn yoo si tun da wa pada si aaye bi?! Awọn wọnyi ni wọn ntako igbende lẹyin iku, awọn ti wọn se keferi si Ọlọhun Ọba wọn, wọn si tako agbara Rẹ lori gbigbe oku dide, awọn ni wọn yoo fi sẹkẹ sẹkẹ ina si wọn lọrun ni ọjọ igbende, awọn ni ẹni ina, wọn yoo si maa gbebẹ lọ gbere, titan ko nii de ba wọn, iya ko si ni tan fun wọn.
Fifi agbara Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun rinlẹ ati sise eemọ nibi dida ti o da sanmọ laisi opo kankan ti o gbe dani, eleyi pẹlu titobi idẹda Rẹ ati fifẹ Rẹ.
Fifi rinlẹ agbara Ọlọhun Ọba ati pipe isetọju Rẹ pẹlu awijare idẹda nigbati O mu eso ti o tobi jade, O si nmu jade lati ibi irugbin ti o kere, lẹyin igba naa o si nfun ni omin kan soso mu pẹlu eleyi odiwọn ara rẹ yatọ ati awọn awọ eso rẹ ati itọwo rẹ.
Dajudaju mimu ti Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga mu awọn igi ti o tobi jade lati ibi awọn irugbin kekere lẹyin igbati o ti jẹ ohun ti ko si tẹlẹ, ẹri wa nibẹ lati da ọrọ pada si awọn ẹlẹbọ lọdọ nibi titako igbende; nitori wipe dida ọpọ ẹka ẹka awọn eso ọtọọtọ ati awọn nkan ẹtọ lori ilẹ pada ati gbigbe dide ni titun lẹyin igbati o ti nbẹ tẹlẹ eyi wa ni ipo ti o rọrun ju mimu jade nibi aisi lati ibi irugbin.