سورة (MAKIYYAH)
Fifi jijẹ aaso Allah nibi pipe ati mimu lọkan ni ẹni ijọsin fun ati fifọ Ọ mọ kuro nibi ẹdinku rinlẹ.
قُلۡ هُوَ ٱللَّهُ أَحَدٌ 1
Sọ wipe - irẹ ojisẹ -: Oun ni Allah, aaso pẹlu mimu lọkan ẹni ijọsin fun, ko si ọba kan yatọ si I.
ٱللَّهُ ٱلصَّمَدُ 2
Oun ni asiwaju eyiti gbogbo iranlọwọ pari si ọdọ Rẹ nibi gbogbo iroyin pipe ati ẹwa, eyiti gbogbo ẹda dari ọkan si ọdọ Rẹ.
لَمۡ يَلِدۡ وَلَمۡ يُولَدۡ 3
Eyiti ko bi ẹnikankan, ti ẹnikankan ko si bi I, ko si ọmọ fun Un –mimọ Rẹ-, ko si si olubi.
وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ كُفُوًا أَحَدُۢ 4
Ko si si alapejuwe fun Un nibi isẹda Rẹ.
سورة (MAKIYYAH)
Wiwa aabo ati wiwa isọ pẹlu Allah kuro nibi awọn aburu ti o fi oju han.
قُلۡ أَعُوذُ بِرَبِّ ٱلۡفَلَقِ 1
Sọ wipe - irẹ ojisẹ -: mo fi Ọlọhun idaji wa isọ, mo si sa di I.
مِن شَرِّ مَا خَلَقَ 2
Kuro nibi aburu ti o le seni ni suta kuro lọdọ gbogbo ẹda.
وَمِن شَرِّ غَاسِقٍ إِذَا وَقَبَ 3
Mo si fi Allah wa isọ kuro nibi gbogbo aburu eyiti o ma nhan loru lọdọ gbogbo ẹranko awọn awọn ole.
وَمِن شَرِّ ٱلنَّفَّٰثَٰتِ فِي ٱلۡعُقَدِ 4
Mo si nfi wa isọ kuro nibi aburu awọn olupidan ti wọn ma nfẹ atẹgun si inu awọn agadagodo.
وَمِن شَرِّ حَاسِدٍ إِذَا حَسَدَ 5
Mo si wa isọ kuro nibi aburu onikeeta nigbati o ba se ohun ti keeta naa ti i si.
سورة (MAKIYYAH)
Wiwa isọ ati idaabobo pẹlu Allah nibi aburu esu ati royiroyi rẹ ati nibi awọn aburu ti o pamọ.
قُلۡ أَعُوذُ بِرَبِّ ٱلنَّاسِ 1
Sọ wipe - irẹ ojisẹ -: mo fi Ọlọhun awọn eniyan wa isọ, mo si sa di I.
مَلِكِ ٱلنَّاسِ 2
Ọba awọn eniyan ti O ma nse bi o se wu U nipa wọn, ko si Ọba miran fun wọn yatọ si I.
إِلَٰهِ ٱلنَّاسِ 3
Ẹni ijọsin fun wọn pẹlu ododo, ko si ẹni ijọsin fun pẹlu ododo fun wọn yatọ si I.
مِن شَرِّ ٱلۡوَسۡوَاسِ ٱلۡخَنَّاسِ 4
Kuro nibi aburu esu eyiti o nju royiroyi rẹ si ọmọniyan nigbati o ba fọnu kuro nibi iranti Allah, ti o si lọ kuro nibẹ nigbati o ba ranti Rẹ.
ٱلَّذِي يُوَسۡوِسُ فِي صُدُورِ ٱلنَّاسِ 5
O nju royiroyi rẹ si inu ọkan awọn eniyan.
مِنَ ٱلۡجِنَّةِ وَٱلنَّاسِ 6
O si nwa ninu eniyan gẹgẹ bi o se nwa ninu alujannu.
Fifi awọn iroyin pipe rinlẹ fun Allah ati lile awọn iroyin ẹdinku jinna kuro fun Un.
Ririnlẹ idan ati ojupọnna iwosan kuro nibẹ.
Iwosan royiroyi jẹ pẹlu riranti Allah ati wiwa isọ kuro ni ọdọ esu.