سورة (MAKIYYAH)
Fifi mimu Ọlọhun lọkan nibi ijọsin ati bibọpa bọsẹ kuro nibi ẹbọ rinlẹ ati sise adayanri ti o pe laarin ẹsin alaafia ati ẹbọ.
قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡكَٰفِرُونَ 1
Sọ - irẹ ojisẹ -: mo pe ẹyin oluse keferi si Allah.
لَآ أَعۡبُدُ مَا تَعۡبُدُونَ 2
Nko nii sin ni asiko tabi ni igbati o ba ya ohun ti ẹ nsin ninu awọn ẹbọ.
وَلَآ أَنتُمۡ عَٰبِدُونَ مَآ أَعۡبُدُ 3
Ẹyin naa ko si nii jẹ olujọsin fun ohun ti emi nsin; Oun sini Allah nikan soso.
وَلَآ أَنَا۠ عَابِدٞ مَّا عَبَدتُّمۡ 4
Emi ko si nii jẹ olujọsin fun ohun ti ẹ nsin ninu awọn oosa.
وَلَآ أَنتُمۡ عَٰبِدُونَ مَآ أَعۡبُدُ 5
Ẹyin naa ko si nii jẹ olujọsin fun ohun ti emi nsin; Oun sini Allah nikan soso.
لَكُمۡ دِينُكُمۡ وَلِيَ دِينِ 6
Ẹsin ti yin eyiti ẹ da adadaalẹ rẹ fun ara yin ki o jẹ ti yin, ẹsin temi eyiti Allah sọkalẹ fun mi, ki o jẹ temi.
سورة (MADANIYYAH)
Sise alaye igbẹyin ẹsin alaafia pẹlu aranse ati isipaya ati ohun ti wọn yoo se lofin nigbati eleyi ba sẹlẹ gẹgẹ bi o tun se ntọka si iku anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun.
إِذَا جَآءَ نَصۡرُ ٱللَّهِ وَٱلۡفَتۡحُ 1
Nigbati aranse Allah ba de fun ẹsin rẹ - irẹ ojisẹ - ati fi fun un lagbara ati ti isina isẹgun ilu Mẹkkah ba sẹlẹ.
وَرَأَيۡتَ ٱلنَّاسَ يَدۡخُلُونَ فِي دِينِ ٱللَّهِ أَفۡوَاجٗا 2
Ti o si ri awọn eniyan ti wọn nwọ inu ẹsin alaafia ni ijọ kan lẹyin ijọ.
فَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ وَٱسۡتَغۡفِرۡهُۚ إِنَّهُۥ كَانَ تَوَّابَۢا 3
Ki o si mọ wipe eleyi jẹ amin lori sisunmọ titan pataki ohun ti wọn tori rẹ gbe ọ dide, ki o si se afọmọ pẹlu didupẹ fun Ọlọhun rẹ; niti didupẹ fun Un lori idẹkun aranse ati isina isẹgun naa, ki o si wa aforijin lọdọ Rẹ, dajudaju O jẹ olugba iforu piwada ti O ma ngba ironu piwada awọn ẹru Rẹ, O si nfi ori jin wọn.
سورة (MAKIYYAH)
Adehun iya fun awọn ti o ntako isẹ ipepe pẹlu iyẹpẹrẹ ati ijiya ni aye ati ọjọ ikẹhin, wọn se adayanri Abu Lahab ati iyawo rẹ; nitori bi iba anọbi ẹniti ikẹ ati ọla nbẹ fun se ọta wọn se to.
تَبَّتۡ يَدَآ أَبِي لَهَبٖ وَتَبَّ 1
Ọwọ ẹgbọn baba anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun tii se Abi Lahabi ọmọ Abdul Mutọlib ti sofo pẹlu sise ofo isẹ rẹ; nigbati o fi suta se anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, igbesẹ rẹ naa si sofo.
مَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُ مَالُهُۥ وَمَا كَسَبَ 2
Ewo ninu owo rẹ ati ọmọ rẹ ni o le rọ ọ lọrọ kuro nibẹ? Mejeei ko le la a kuro nibi iya, wọn ko si le mu ika wa ba a.
سَيَصۡلَىٰ نَارٗا ذَاتَ لَهَبٖ 3
Yoo pada wọn ina elejo bele ni ọjọ igbende, ti yoo fi ara kin igbona rẹ.
وَٱمۡرَأَتُهُۥ حَمَّالَةَ ٱلۡحَطَبِ 4
Iyawo rẹ naa tii se Umu Jamiil eyiti o nfi suta se anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun pẹlu jiju ẹgun si oju ọna rẹ, yoo si pada wọ ọ.
فِي جِيدِهَا حَبۡلٞ مِّن مَّسَدِۢ 5
Okun ti a ti dajọ pipani le lori yoo wa ni ọrun rẹ, ti wọn yoo fi wọ lọ si inu ina.
Pipinya pẹlu awọn keferi.
Fifi idupẹ koju idẹkun.
Ọgba ọrọ Masad wa ninu awọn itọka jijẹ anọbi; nitoripe o dajọ iku lori Abi lahabi ti o jẹ keferi, o si ku lẹyin ọdun mẹwa lori eleyi.
Lilaalafia fifẹ iyawo awọn keferi.