سورة (MAKIYYAH)
Sise idẹkun lori Qurayshi ati ohun ti o jẹ dandan fun wọn ni ibamun si eleyi.
لِإِيلَٰفِ قُرَيۡشٍ 1
Nitori isesi Qurayshi ati ibarẹ wọn.
إِۦلَٰفِهِمۡ رِحۡلَةَ ٱلشِّتَآءِ وَٱلصَّيۡفِ 2
Irin ajo ọyẹ lọsi Yamani ati irin ooru lọsi Shaamu ni ẹni ifọkanbalẹ.
فَلۡيَعۡبُدُواْ رَبَّ هَٰذَا ٱلۡبَيۡتِ 3
Ki wọn ya maa sin Allah Ọba ti O ni ile ọwọ naa ni Oun nikan, Ẹniti o rọ irin ajo yii fun wọn, ki wọn si mase se ẹbọ kankan pẹlu Rẹ.
ٱلَّذِيٓ أَطۡعَمَهُم مِّن جُوعٖ وَءَامَنَهُم مِّنۡ خَوۡفِۢ 4
Ẹniti o fun wọn ni ounjẹ nibi ebi, O si fi wọn lọkan balẹ nibi ipaya; pẹlu gbigbe aaye ọwọ tobi ti O fi si inu ọkan awọn larubawa ati gbigbe awọn olugbeebẹ tobi.
سورة (MAKIYYAH)
Sise alaye awọn iwa olupe ẹsan ati ọrun nirọ niti sise ikilọ fun awọn olugbagbọ ododo ati mimu iburu ba awọn keferi.
أَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي يُكَذِّبُ بِٱلدِّينِ 1
Njẹ o mọ ẹniti o npe ẹsan ọjọ igbende nirọ bi?!
فَذَٰلِكَ ٱلَّذِي يَدُعُّ ٱلۡيَتِيمَ 2
Oun ni ẹniti o nti ọmọ orukan niti lile kuro nibi bukaata rẹ.
وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ 3
Kii si ta ẹmin rẹ ji tabi ẹlomiran lori fifun alaini lounjẹ.
فَوَيۡلٞ لِّلۡمُصَلِّينَ 4
Iparun ati iya ki o si maa ba awọn olukirun.
ٱلَّذِينَ هُمۡ عَن صَلَاتِهِمۡ سَاهُونَ 5
Awọn ti wọn ma ngbagbe nipa irun wọn, wọn kii bikita pẹlu rẹ titi asiko rẹ yoo fi lọ.
ٱلَّذِينَ هُمۡ يُرَآءُونَ 6
Awọn ti wọn nse karimi pẹlu irun wọn ati awọn isẹ wọn, wọn ki se afọmọ isẹ fun Allah.
وَيَمۡنَعُونَ ٱلۡمَاعُونَ 7
Wọn si ma nkọ riran ẹniti o yatọ si wọn lọwọ nibi ohun ti ko si inira nibi fifi ran ẹlomiran lọwọ.
سورة (MAKIYYAH)
Idẹkun Allah lori anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ati jija ọna awọn olukorira rẹ.
إِنَّآ أَعۡطَيۡنَٰكَ ٱلۡكَوۡثَرَ 1
Awa ni a mu rere ti o pọ wa ba ọ - irẹ ojisẹ - ninu si ni odo kaothar ninu ọgba idẹra naa.
فَصَلِّ لِرَبِّكَ وَٱنۡحَرۡ 2
Ki o ya pe idupẹ Allah lori idẹkun yi, ki o kirun fun Un ni Oun nikan, ki o si pa ẹran; niti yiyapa si ohun ti awọn ẹlẹbọ nse nipa fifi didu ẹran se isunmọ fun awọn oosa wọn.
إِنَّ شَانِئَكَ هُوَ ٱلۡأَبۡتَرُ 3
Dajudaju olukorira rẹ ni ẹniti o ti ja kuro nibi gbogbo rere, ẹni igbagbe eyiti wọn ba ranti rẹ, ti wọn yoo ranti rẹ pẹlu aburu.
Pataki ifọkanbọlẹ ninu ẹsin alaafia.
Sekarimọ jẹ ọkan ninu awọn aarẹ ọkan, o si ma nba isẹ jẹ.
Fifi ọpẹ didu koju idẹkun ma nse alekun rẹ.
Apọnle anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun lọdọ Ọlọhun rẹ ati idaabobo Rẹ fun un ati mimu iyi ba ni aye ati ọrun.