سورة (MAKIYYAH)
Sise alaye paapaa ere ati ofo ninu isẹmin ati titaniji lori pataki asiko eyiti ọmọniyan nlo.
وَٱلۡعَصۡرِ 1
Oun ti mimọ nbẹ fun bura pẹlu asiko irọlẹ.
إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَفِي خُسۡرٍ 2
Dajudaju ọmọniyan wa ninu ẹdinku ati iparun.
إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلۡحَقِّ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلصَّبۡرِ 3
Ayaafi awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah ati ojisẹ Rẹ, ti wọn si nse awọn isẹ rere, ti apakan wọn si nsọ asọtẹle fun apakan pẹlu ododo ati pẹlu suuru lori ododo; awọn ti a fi awọn iroyin yii royin ni wọn yoo la ninu isẹmin aye ati ọrun.
سورة (MAKIYYAH)
Adehun iya fun awọn onigberaga olufi ẹsin ati awọn ara ile rẹ se yẹyẹ.
وَيۡلٞ لِّكُلِّ هُمَزَةٖ لُّمَزَةٍ 1
Idaamun ati ilekoko iya nitori pipọ isọrọ eniyan lẹyin tabi fi ẹnu ẹgan kan wọn.
ٱلَّذِي جَمَعَ مَالٗا وَعَدَّدَهُۥ 2
Ẹniti ikolekan rẹ jẹ kiko owo jọ ati kika a, ko si ikolekan kankan fun un ju eleyi lọ.
يَحۡسَبُ أَنَّ مَالَهُۥٓ أَخۡلَدَهُۥ 3
O nlero wipe owo oun eyiti oun ko jọ yii, yoo la oun kuro nibi iku, ti yoo si maa sẹku gbere ninu isẹmin aye.
كَلَّاۖ لَيُنۢبَذَنَّ فِي ٱلۡحُطَمَةِ 4
Ọrọ ko ri bi alaimọkan yii se nya aworan rẹ, wọn yoo ju u si inu ina jahannamọ eyiti o ma nlọ, ti o si ma nkan gbogbo ohun ti wọn ba ju sibẹ nitori lile koko iya rẹ.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡحُطَمَةُ 5
Kinni yoo si fi mọ ọ - irẹ ojisẹ - kinni ina ti o ngbe gbogbo ohun ti wọn ba ju sinu rẹ min na?!
نَارُ ٱللَّهِ ٱلۡمُوقَدَةُ 6
Dajudaju ina Allah ti o njo geregere ni.
ٱلَّتِي تَطَّلِعُ عَلَى ٱلۡأَفِۡٔدَةِ 7
Eyiti yoo maa lu iho si ara wọn titi de ọkan wọn.
إِنَّهَا عَلَيۡهِم مُّؤۡصَدَةٞ 8
Dajudaju o wa ni titi pa fun awọn olujiya nibẹ.
فِي عَمَدٖ مُّمَدَّدَةِۢ 9
Pẹlu opo ti o na, ti o si gun, ti wọn ko fi le jade nibẹ.
سورة (MAKIYYAH)
Sise afihan agbara Allah lori idaabobo ile Rẹ ọwọ naa niti ikilọ ati sise idẹkun.
أَلَمۡ تَرَ كَيۡفَ فَعَلَ رَبُّكَ بِأَصۡحَٰبِ ٱلۡفِيلِ 1
Se o ko mọ ni - irẹ ojisẹ - bi Ọlọhun rẹ se se fun aburaha ati awọn ẹni rẹ elerin nigbati wọn gbero wiwo kahaba naa?!
أَلَمۡ يَجۡعَلۡ كَيۡدَهُمۡ فِي تَضۡلِيلٖ 2
Paapaa Allah ti sọ ete wọn alaburu lati wo o di irare, wọn ko ri ohun ti wọn nlero gbamun nipa yiyi awọn eniyan kuro nibi kahaba naa, wọn ko si ri nkankan nibẹ.
وَأَرۡسَلَ عَلَيۡهِمۡ طَيۡرًا أَبَابِيلَ 3
O si gbe ẹyẹ kan dide si wọn, ti o nwa ba wọn ni ijọ ijọ.
تَرۡمِيهِم بِحِجَارَةٖ مِّن سِجِّيلٖ 4
Ti o nju okuta kan lati inu amọ ti o le.
فَجَعَلَهُمۡ كَعَصۡفٖ مَّأۡكُولِۢ 5
Allah si sọ wọn da gẹgẹ bi ewe ọgbin ti awọn ẹran ti jẹ, ti wọn si tẹ mọlẹ.
Ofo ẹniti ko ba gba iroyin pẹlu igbagbọ ati sise awọn isẹ rere ati sisọ asọtẹlẹ ododo ati sisọ asọtẹlẹ suuru.
Jijẹ eewọ bibuni loju ati bibuni lẹyin laarin awọn eniyan.
Idaabobo Allah fun ile Rẹ ọlọwọ eleyi si wa ninu ifọkanbalẹ ti Allah kọ silẹ fun un.